Lẹ́yìn Ìpọ́njú Náà – fíìmù lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pẹlu Yorùbá àkọlékè
Watch Video
October 9, 2015
VIDEO
"Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan;
bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú
ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;
ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́
náà." - Esekiẹli :
Ní aarọ kutu ọjọ Iṣẹgun yii, ti i ṣe ọjọ Kọkanla, ọdun 2001.
- Al, owurọ yii mà dara o, abi bẹẹ kọ? Owurọ ìgbà ẹ̀rùn tó wuni ni.
Ni ọjọ Kọkanla osù Kẹsan an ọdun 2001, ayé yípadà.
Tí "ilẹ awọn olómìnira naa" sì di
ilẹ́ awọn ẹni-ìgbèkùn. Awọn ará
Ilẹ̀ Amẹrika wa tí ó ti fi ìgbà kan ilẹ jẹ ológo ti ta ominira wọn
nitori idaabobo. Sugbọn se gbogbo awọn nnkan yii sàdéédé
sẹlẹ ni bí? "Ọjọ Keje oṣu Kejila, ọdun , jẹ́ ọjọ kan tí
a ó máa ranti fún àìnítìjú. Wọn fínnú-fíndọ̀ kọlu Ilẹ Amerika lójijì."
Ọpọlọpọ ibeere ni n sọ kúlúkúlú lọ́kàn eniyan lori isẹlẹ ọjọ
naa - ànì ọjọ àìnítìjú naa. Sugbọn ohun kan
ni a mọ̀ daju; ìkọlù tì ò yanilẹnu naa tó wáyé ní
ní Pearl Harbour ṣe okunfa fún awọn isẹlẹ kan
tí yoo kúkú sọ gbogbo ayé di oníjọba ayédọ̀kan.
"Orilẹ-ede Japan fi ìwà-ọ̀dàlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ogun yii.
Isẹgun ni àwa yóò fi rẹ́yiǹ rẹ̀."
Ní igbẹyin ogun Agbaye Keji, a dá
Àjọ Àpapọ̀ awọn Orilẹ-ede silẹ, eyi tí ó mú ki
gbigbé ìgbésẹ̀ sí sáà ijọba ayédọ̀kan gbéra-sọ ní kiakia.
Ogun kọọkan tí a jà n fi igbesẹ kan sún wa mọ ohun ti Bibeli
pè ní "opin ayé." Awọn agbófinró
gbe igi dánà nibi gbogbo; tí awọn ọlọpaa
sì mú ètò-ààbò le koko lara awọn eniyan
Ilẹ Amẹrika, sugbọn fun awọn tí wọn ní òye
asọtẹlẹ Bibeli, ohun tí yoo sẹlẹ lẹyin eyi kò ní í
jẹ́ iyalẹnu.
Ní awọn asiko kan ní ọjọ iwaju, ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu
sọ pe gbogbo eniyan ní orilẹ-ayé ni wọn
máa se é ni dandan funni lati gba àmì kan kí wọn tó lè tà
tabi ra ohunkohun. Bí ọrọ-aje wa sì se n dẹnu kọlẹ,
tí imọ ẹrọ sì ti n gbilẹ̀ sí, owó níná n lọ sí
opin igbagbe. Òkodoro pé awujọ kò
ní í maa lo owó fun títà ati rírà kò pẹ mọ́ rárá.
Àní ó tilẹ ti bẹrẹ bayii. Bí ó tilẹ jẹ pé ọpọ awọn
olórí ẹlẹ́sìn kan kò gbà bẹẹ, awọn ẹni-ibi kan n sisẹ
lọ́sàn-án-lóru lati mú Isejọba Ayé-dọ̀tun sẹ. Àwa pẹlu
rí pé igbẹyin ayé ti sunmọ, tí gbogbo
ètò sì n kórí jọ fun ifarahan asòdìsí-Krisiti.
Etí wa n gbọ ohùn awọn tí n dojú ofin wa kodò
ni Ilẹ Amẹrika, tí wọn sì n se agbatẹru agbekalẹ
agbaye yii. "...ìsejọba ayé-dọ̀tun..."
Ati pẹlu bí gbogbo eyi ti sunmọ etile,
fọ́nrán-aworan yii se koko ni akoko yii ju ti tẹlẹ lọ. Satani
n sísẹ labẹnu lati se ìfilọ́lẹ̀
ijọba ayé-dọ̀kan ati ẹ̀sìn ayé-dọ̀kan
ní igbaradi fun asòdìsí-kristi. Ó tilẹ tún
ti tan awọn Kristiani ajíyìnrere igbalode jẹ
lati gbagbọ pé a ó gbà wọn kuro
lorilẹ aye siwaju ki Ipọnju Nla Náà tó
sẹlẹ. Ẹkọ yii , ti a mọ̀ sí ̂igbasoke siwájú
ipọnju naa,” n kọ wa pe Kristi le pada wa ní
igbakugba, ati pe ko ní í sí ami
ipadabọ rẹ̀. Nitori itanjẹ yii,
ni ọpọ Kristiẹni fi wa ni aimurasilẹ patapata
fun awọn ohun ti Bibeli n kilọ fun wa pe yoo sẹlẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe iwe-mimọ sọ kedere ninu Matteu
, ati nibomiran pe, igbasoke yoo waye
LẸYIN IPỌNJU NAA ni, awọn oniwaasu olorukọ,
awọn ile-ẹkọ Bibeli, ati awọn fiimu tó gbajumọ bi i
"Awọn tó Kù Lẹyin" ti kọ ogunlọgọ pe ki wọn
reti pe igbasoke le ṣẹlẹ nigbakugba.
Ati pe ọpọ Kristiẹni ni kò tí ì ka
Bibeli parí tan lodindi funrawọn, diẹ ló mọ̀
pe ẹkọ igbasoke siwaju ipọnju naa jẹ itannijẹ tí kò sí
ninu iwe-mimọ. Sugbọn tí igbasoke siwájú ipọnju naa
kò bá sí ninu iwe-mimọ, nibo ni ó ti
wá?
Oluṣọ-agutan Anderson: Orukọ mi ni Steven Anderson,
mo sì jẹ́ oluṣọ-agutan ní Ijọ Faithful Word Baptist
ni ilu Tempe, Arizona, mo sí n ṣiṣẹ iranṣẹ
lati kọ awọn eniyan nipa pé igbasoke siwájú
ipọnju naa nitori ó jẹ́ ipo-ironu tí ó dá lori
aimọkan,mo sí gbagbọ pe bí
awọn eniyan bá le ri iwe-mimọ, tí wọn sì rí
okodoro naa, ko ní í nira fun wọn lati wa
aridaju pe laisi aniani, igbasoke yoo ṣẹlẹ
LẸYIN IPỌNJU NAA ni
Oluṣọ-agutan Jimenez: Orukọ mi ni Roger Jimenez.
emi sì ni oluṣọ-agutan fun Ijọ Verity Baptist ní
ilu Sacramento, California. Idile Kristiẹni ni mo dàgbà
sí, wọn sì fi kọ mi ni gbogbo aye mi pe igbasoke n
siwaju ipọnju naa ni, ti emi kò sì idi kan lati
sọ pé bẹẹ kọ ni. Awọn oniwaasu sọ bẹẹ fun wa,
emi naa kuku gba a bi wọn ṣe sọ ọ, sugbọn
nigba ti oju mi ṣí sí ẹkọ naa, mo bẹrẹ
sí rí i bí eyi kò ṣe bá iwe-mimọ mu tó,
mo sì rí pe a ni lati kọ́
Bibeli kí a sì mú otitọ ibẹ jade.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹkọ lori igbasoke siwájú
ipọnju jẹ́ ohun tí kò sí tẹlẹ. Kò sí ẹri
pe ẹnikan n kọni bẹẹ siwaju ọdun .
Oluṣọ-agutan Jimenez: A ni lati jẹ́ kí ó yé wa pe
ọdun ti pẹ ninu it̀àn. Fun ẹgbẹgbẹrun
ọdun lati sáà ti Kristi, a la awọn atunto kan
kọja, a gba abẹ́ ẹkọ awọn onimọ-ijinlẹ ninu
Bibeli kan kọja – ohun yoowu ti o ba ṣe tabi
tí o kò faramọ pẹlu awọn bí i Martin Luther, tabi
John Calvin, tabi ẹnikẹni wọn, òkodoro ibẹ ni pe
ẹgbẹgbẹrun awọn iwe, ẹgbẹgbẹrun awọn akọsilẹ, ẹgbẹrun awọn
arokọ, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn iwaasu ló tí
jade kí ó tó di ọdun ,
Oluṣọ-agutan Anderson: Mo sì tún n sọ pe kò
sí ẹri oniwaasu kankan lati inu ijọ yoowu,
tabi iru ẹsin Kristiẹni yoowu, tí n kọni
ẹkọ yii.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Tí ẹ bá wo inu iwe,
itan, ẹ maa fẹ lati bi ara yin ni ibeere kan,
"Kin gan an ni orírun ẹkọ igbasoke siwájú
ipọnju naa?"
Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Ọkan lara awọn abẹnugan
ẹkọ igbasoke siwáju ipọnju naa yii ni ọkunrin kan tí orukọ rẹ̀ n jẹ
John Nelson Darby. Ni awọn ọdun inu , ó bẹrẹ
kikọ ẹkọ naa ti ó pe ni "igbasoke
ìdákọ́-ń-kọ́." Lẹyin naa ni ó tún gbé ẹ̀dà Bibeli
ti ararẹ̀ jade, ninu eyi ti ó
fa awọn ẹsẹ kan yọ lodindi-lodindi, tí ó sì pòrúurù awọn
kókó ẹkọ Bibeli kan, tí ó sì tún yí awọn ibi kika
pataki kan tí n sọ nipa ipadabọ Kristi lẹẹkeji sódì
John Nelson Darby, tí a mọ̀ sí “Baba ninu awọn
tí n kọni lẹkọọ Ọmọ-tí-ayé-bí-layé-ńpọ̀n”, ṣe agbatẹru
èrò-dìmọ̀ rẹ̀ lori igbasoke n siwájú ipọnju naa ní
gbogbo akoko ọ̀rùndún kọkandinlogun. Lẹyin
naa sì ni igbasoke n siwájú ipọnju naa di kari-aye
ninu ijọ Onitẹbọmi nigba ti Ile-itẹwe Oxford University
ṣagbejade Atọka Bibeli Scofield, tí ó ní arokọ-aarin
tí n ṣe agbatẹru fun ojuwoye igbasoke ìdákọ́-ń-kọ́ tí
tí Darby fi n kọni. Awọn àkọsílẹ̀ yii ti mú kí ọpọ
Kristiẹni tẹwọgba ẹkọ yii bi i pe
Ọlọrun funraRẹ ló sọ bẹẹ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Eṣu ti lo Atọka inu Bibeli
Scofield gẹgẹ bí irinṣẹ rẹ̀ ju
Ohunkohun miran lọ lati ṣe agbatẹru ẹkọ
igbasoke n siwaju ipọnju naa. O maa fẹ mọ̀
ibi tí ó ti wa? Bí ó ṣe wọ inu ijọ niyi.
ibi yii sì ni awọn oluṣọ-agutan ti maa
n rì i. Kì í ṣe lati inu Bibeli ni ó ti wá. Ó sì daju
pẹlu pe kì í ṣe lati ẹnu Jesu ni ó ti jade!
Sugbọn lati ẹnu Scofield ló ti jade wa. Awọn akọsilẹ
Scofield ló n tọka sí igbasoke siwájú ipọnju naa,
eyi ti n mú kí ẹni ti n kà wọn gbagbọ pe
lati inu iwe-mimọ lo ti wa, tí eyi kò sì jẹ bẹẹ
rara. Tí ó jẹ pe nitori ẹ̀dà Bibeli Scofield tí
wọn pin kaakiri awọn ile-ẹkọ Bibeli
tí ọpọ awọn oniwaasu kekeeke n kà ẹ̀dà
Atọka Bibeli Scofield naa, wọn bẹrẹ sí ní
tẹwọgba ẹkọ igbasoke siwájú ipọnju naa gẹgẹ
ododo, tí wọn sì bẹrẹ sí ní waasu rẹ̀.
Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Awọn àròsọ
nipa igbasoke ti n bọ lọna yii tún dé ìran ti n bẹ laye ni
bí ogoji ọdun sẹyin nipasẹ fiimu Don Thompson.
Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Awọn itan aláwògbádùn tí
Thompson ṣe naa tún kó ipa tó ní apẹrẹ ninu kíkọ́
awọn iran ọ̀dọ́ iwoyi ní ẹkọ yii. Lati igba tí ó ti kọkọ jade,
ó lé ni eniyan ọgbọn miliọnu tí ó ti wo "Bì Olè
L’Óru." Ní ọdun , Ile-itẹwe Tim Dalehouse
tẹ iwe Tim LaHaye ati Jerry Jenkins tó dá lori
ẹkọ nipa igba ikẹyin "Awọn tó Kù Lẹyin."
Oluṣọ-agutan Anderson: Eyi jẹ itan àròsọ tí
n sọ nipa awọn ti n poora, tí kò sì sí
ẹni tí ó mọ ibi tí wọn lọ. Awọn ọkọ n kọlu
arawọn; awọn baalu n ja lulẹ nitori
awakọ-ofurufu ti parẹ, ere itage nipa
igbasoke siwájú ipọnju naa ti di
ọkan lara awọn iṣẹdalẹ Ilẹ Amẹrika, ti awọn eniyan
sì gba a bẹẹ bí otitọ, tí ó sì jẹ́ pé … o jẹ́
fiimu tí kò mọgbọn dání.
Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Fiimu Awọn tó Kù Lẹyin yoo tẹ
siwaju lati ma tà lọ tó miliọnu mẹtalelọgọta kaakiri agbaye, tí
iwe mẹrindinlogun keekeeke ti arawọn jade, pẹlu awọn fiimu
àgbélẹ̀rọ mẹta kan titi di oni. Sugbọn “Awọn tó Kù Lẹyin” jẹ́
àròsọ lasan. Lati kọ otitọ nipa
igbasoke naa, a ni lati bojuwo awọn oju-ewe
Bibeli funrarẹ̀.
Iran Kẹta – Tẹsalonika Kinni ori Kẹrin ati Mateu ori Kẹrinlelogun
Oluṣọ-agutan Anderson: Tẹsalonika Kinni ori Kẹrin
jẹ́ ibi-kika pataki julọ nipa igbasoke.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ninu Tẹsalonika Kinni ori Kẹrin, ni a ti
fẹ̀rẹ́ rí ẹsẹ tí ó gbajumọ julọ tí a ba n sọ nipa
igbasoke naa.
Oluṣọ-agutan Anderson: Enikẹni yoo gba pe ibi-kika
yii n sọ gẹlẹ nipa igbasoke ni. Eyi jẹ́
ibi ẹkọ tó mọ́ gaara julọ ninu Bibeli nipa
bíbọ̀ Jesu ni awọ sanma, ati bí a sì ti maa gbe wa
pade rẹ̀ papọ loke. Bibeli sọ ninu ẹsẹ :
( Tẹsalonika :) "Ẹyin ara, awa kò fẹ́
ki ẹ mà nì òye nipa awọn ti
wọn ti sùn, kí ẹ má ba à banujẹ bi
awọn ti kò ní ìrètí."
( Tẹsalonika :) "Nitori tí a bá gbagbọ pe
Jesu kú, ó sì jinde, bẹẹ gan an ni
Ọlọrun yoo mú awọn ti wọn ti kú ninu Jesu wà pẹlu rẹ̀."
Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, ohun ti ó n sọ nibi
ni pe oun kò fẹ kí wọn jẹ aláìlóye
nipa awọn Kristiẹni, awọn ẹni-igbagbọ ti wọn ti kú,
awọn ti wọn sùn ninu Jesu, awọn ti wọn ti
lọ wà pẹlu Oluwa. Ó sọ pe,
Emi kò fẹ kí ẹ má ni òye awọn ará-ninu-Oluwa yii
nitori pe emi kò fẹ kí ẹ ṣọ̀fọ̀ bí awọn
ti kò ni ìrètí. Mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe
ẹ maa rí awọn ayanfẹ yin pada, ti wọn jẹ́
ẹni-irapada. Ẹ maa tún wọn rí
lẹẹkan sí i nitori Bibeli sọ pe nigbati
Jesu Kristi ba pada dé, ó maa ko wọn
pada pẹlu rẹ̀. Awọn oku ninu Kristi kọkọ maa jinde,
:
( Tẹsalonika :) Ẹ maa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu
ara yín ninu .
Oluṣọ-agutan Anderson: Idi ni yii tí eyi fi jẹ
iwaasu tí ó gbajumọ julọ ti a n gbọ nibi isinku.
Ọpọlọpọ isinku ni mo ti lọ nibi ti awọn eniyan n
fi awọn ọrọ yii tu arawọn ninu. Tori naa, kiyesi
ninu ẹsẹ kọọkan, tó n jẹyọ ni o n mu kí otitọ
naa jade pe a maa rí awọn eniyan yii pada,
àní awọn ti wọn ti lọ.
( Tẹsalonika :) Nitori a n ṣọ ọrọ yii
fun yin gẹgẹ bi ọrọ Oluwa, pe awa ti a
bá wà laaye. tí a bá kù lẹyin nigba ti Oluwa ba farahan, kò ní siwájú
awọn ti wọn ti kú.
( Tẹsalonika :) Nitori nigba ti ohùn
àṣẹ bá dún, olórí awọn angẹli yoo fọhun,
fere Ọlọrun yoo dún Oluwa funrarẹ̀ yoo sọkalẹ
lati ọ̀run. Awọn oku ninu Jesuni yoo
kọ́kọ́ jinde.
( Tẹsalonika :) A óo wá gbé awa ti ó ti kú lẹyin,
tí a wà laaye, lọ pẹlu wọn ninu awọsanma,
lati lọ pade Oluwa ní ofuurufu,
a òo sì maa wà lọdọ Oluwa laelae.
( Tẹsalonika :) Ẹ maa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu
ara yín ninu.
Oluṣọ-agutan Anderson: Tori naa, tí òye ọrọ naa bá ye ọ,
itunu naa ni pe o maa rí awọn ayanfẹ rẹ
lẹẹkan sí i. Ó sọ pe o maa pada rí wọn
nitori pe tí o bá gbagbọ pe Jesu kú, tí
ó sì jinde pada, bẹẹ gelẹ (ní ọna kan naa), awọn
oku ninu Jesu ni Ọlọrun yoo mú pada wá
pẹlu rẹ̀. A ó ji wọn dide. Awọn
oku ninu Kristi maa kọkọ jinde. Ó sọ pe
Ẹ maa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu. Kò sí ibikan kan
tí a ti sọ ọrọ itunu tí n sọ pe
o kò ní í la ìnilára kọja. Pé wọn kò ní í ni ọ lara.
Pé o kò ní í la
ipọnju kọja. Pé o kò ní í la ailera kọja. Pé o
kò ní jìyà rara. Ṣé
ibi-kíkà yii tilẹ mẹnu ba ipọnju bí? N jẹ ó tilẹ
sọ nnkankan nipa ipọnju bí?
Rara o. Kò ṣọ pe, Ẹ tu ara yin ninu kí ẹ má
ba à la ipọnju kọja.Ẹ tu ara yin ninu
Pé kí ẹ tu ara yin ninu kí wọn má ba à ni yin lara.
Pé kí ẹ tu ara yin ninu kí ẹ má ba à la igbasoke
siwáju ipọnju kọja. Kì í ṣe ohun tí ó n sọ niyẹn o!
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ní bayii, ti a ba yẹ ibi-kika yii wò,
awọn àrímọ́ kan nbẹ tí a lè
rí nipa igbasoke tí ó lè ran wa lọwọ lati dá
igbasoke mọ̀ ni awọn ibi-kika miran. Mo maa fẹ
ki ẹ lóye ohun tí ó rọ̀mọ́ igbasoke
naa. Ti ẹ ba wo ẹsẹ nibẹ,
ó sọ pé, "Oluwa funrarẹ oo sọkalẹ lati ọrun..."
Tori naa, ohun akọkọ tí a nilo
lati lóye igbasoke naa ni pe
Oluwa n sọkalẹ bọ lati ọ̀run pẹlu ariwo
ati pẹlu ohùn angẹli nla naa, ti mo
sì fẹ́ kí ẹ ṣakiyesi eleyii, "fèrè
Ọlọrun yoo sì dún." Eyi ni àrímọ̀ keji tí mo
fẹ́ kí ẹ rí nipa igbasoke naa.
Oluwa yoo sọkalẹ wa, fèrè Ọlọrun yoo dún
lẹyin naa sì ni Bibeli sọ pe, "Awọn oku
ninu Kristi yoo kọkọ jinde. Lẹyin naa ni awa
ti a wà laaye, ni a màa..." Kiyesi
awọn ọrọ yii, " lọ pẹlu wọn
ní awọsanma..." Tori naa, nigba ti igbasoke naa ba sẹlẹ,
gẹgẹ bi Tẹsalonika orí ti sọ, awọn
àrímọ̀ igbasoke naa ni:
. Oluwa Sọkalẹ . Fere Dún . Lọ pẹlu wọn
ní Awọsanma
Oluṣọ-agutan Jimenez: Awa yoo lọ
pẹlu rẹ̀ ní awọsanma.
Oluṣọ-agutan Anderson: Pada sí Mateu kí o sì
rí hóró-ìtumọ̀ gẹlẹ ní Mateu :-.
Iwọ wo Mateu :, "Lẹsẹkẹsẹ lẹyin
ipọnju ọjọ wọ̀n-ọn-nì, nigba miran ẹ̀wẹ̀,
mo maa n fẹ bi awọn eniyan leere pe, "Apá ibo
LẸYIN NAA ni kò ye yin gan an ná?"
Sugbọn ó sọ pe:
(Matthew :) "Lẹsẹkẹsẹ lẹyin ipọnju ọjọ
wọ̀n-ọn-nì, òòrùn oo sokunkun,
oṣupa kò ní tan imọlẹ rẹ̀, awọn irawọ yoo jábọ́ lati ọ̀run.
Gbogbo awọn agbára
tí ó wà ní ọ̀run ni a ó mì jìgìjìgì:
(Mateu :) Àmì ọmọ eniyan yoo
wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo awọn
ẹ̀yà áye yoo figbe ta, wọn yoo rí ọmọ eniyan
["Ọmọ eniyan"
jẹ́ ohun kan tí Jesu maa n pe ara rẹ̀
nigba ti ó n bẹ lórílẹ̀ ayé] n bọ̀
lori ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbara ati ogo nla.
(Mateu :) Yoo wa rán awọn angẹli rẹ̀
pẹlu fere nla, wọn yoo
kó awọn ayanfẹ jọ lati igun mẹrẹẹẹrin
ayé; ànì lati ìkangun kan dé ìkangun keji.
Oluṣọ-agutan Anderson: Gbogbo awọn hóró-ìtumọ̀ kan naa!
Jesu n bọ̀ ní àwọ̀sánmà. Fere kan dún.
Ó rán awọn angẹli rẹ̀ lati kó awọn ayanfẹ jọ
Oluṣọ-agutan Jimenez: Idi ti mo fi fi eyi hàn yin
ni pé mo fẹ kí ẹ ni òye pe ninu
Mateu :-, a rí igbasoke naa, a sì fi ṣe àkàwé
pẹlu Tẹsalonika :-,
wọn ṣe deedee pẹlu arawọn.
Oluṣọ-agutan Anderson: Fi ìka rẹ há ibẹ yẹn, kí o sì lọ
sí Maaku . Bayii, Maaku naa pẹlu kúkú n sọ
ohun kan naa tí Mateu n sọ ni. Eyi ni
a n pe ni "ibi-kíkà afẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́". Iwọ
yoo rí iwaasu kan naa, ikọ́ni kan naa,
ní awọn ibi-kika mejeeji naa. O le fi wọn
ṣí ẹ̀gbẹ́ arawọn. Ohun kan ni wọn n sọ. Jẹ́ kí
n fi hàn ọ nibi ibi-kika yẹn. Ó sọ ní
ẹsẹ :
(Maaku :) Sugbọn ní ọjọ wọnyii, lẹyin
ipọnju naa, òòrùn yoo sóòkùn,
oṣupa kì yoo si fi imọlẹ rẹ̀ hàn,
(Maaku :) Awọn irawọ oju ọrun yoo ja
silẹ, ati agbara ti n bẹ ni ọrun ni a ó
sì mì tìtì.
(Maaku :) Nigba naa ni wọn ó sì rí Ọmọ-eniyan
ti yoo maa ti ọ̀run bọ̀. oun pẹlu agbara
ati ògo,
(Maaku :) Nigba naa ni yoo sì ran awọn angẹli rẹ̀,
yoo sì kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati
origun mẹrẹẹrin ayé jọ, lati ìkángun ayé títí dé ìkángun ọ̀run.
Oluṣọ-agutan Anderson: Níbi tí a dé bayii, a le
gbadura kí a sì maa lọ sílé. A kàn le
pa Bibeli wa dé, kí a sì sọ pé, "Ṣebí ẹ ti rí i
bó ṣe rí, ẹyin ará. LẸYIN IPỌNJU NAA ni o," kí
ẹ sì pa Bibeli yin dé, ki ẹ maa lọ sílé. Sugbọn
rara o, a kò ní pa Bibeli wa dé, kí
a kọri sílé nitori mo maa fi idi rẹ̀ mulẹ,
mo sì maa fihan yin pe igbasoke naa ni
eyi n tọka sí, pé LẸYIN IPỌNJU NAA ló maa ṣẹlẹ.
Ìran - Kì í ṣe awọn "Júù" ni Mateu
n sọrọ bá
Oluṣọ-agutan Anderson: Ọpọlọpọ ni yoo tako
orí yii ti wọn a sọ pé "O kò lè rí ẹkọ yii kọ
lati Mateu nitori "awọn Júù" nìkan ni Mateu
n sọrọ bá. Wọn maa
maa da ibi-kika yii nù ni,won maa sọ pe, Oh,
awọn Juu nìkan ni ó wà fún, Awọn onimọ-ijinlẹ Bibeli
kan nibi kan pinnu pe awọṅ ẹya Júù nikan ni iwe Mateu
wà fún, tí iwe Maaku wà fún awọn ara
Romu, iwe Luku wà fún Gíríkì,
tí iwe Johanu sì wà fún gbogbo ayé, Oh.
o ṣeun o, Oluwa, pe o fi ọ̀kan lara awọn iwe iyinrere
fún awa naa! Sugbọn ta ló gbé irú
àfinúrò yii jade? Pe boya iwe nitori awọn Júù ni a ṣe kọ
iwe Mateu. Tabi nitori awọn Gíríkì ni a ṣe kọ iwe Luuku.
Tabi boya awọn ara Efesu ni episteli Pọọlu sí
awọn ara Efesu wà fún. Kinni iwọ èrò tìrẹ?
Pe boya awọn Heberu ni episteli Pọọlu sí awọn
Heberu wà fún. Boya awọn ara
Boya awọn ara Tẹsalonika ni episteli Pọọlu sí awọn ara
Tẹsalonika wà fún, ni temi o, emi ni gbogbo awọn ileri
inu iwe naa wà fun! Ori kọọkan, ẹsẹ kọọkan, ìlà kọọkan!
Iwe Titọọsi kí ì kúkú ṣe fun Titọọsi nikan!
Iwe kekere kan niyẹn! Gbogbo awọn
oluṣọ-agutan ni a kọ ọ fún. Gbogbo
onigbagbọ ní kí ó kà á. Majẹmu tuntun niyẹn!
Oluṣọ-agutan Anderson: Sugbọn ohun tí wọn yoo sọ niyi,
"Bí ó ṣe rí kọ́ niyẹn, Oluṣọ-agutan Anderson, kò ye yin ni.
Gbogbo iwaasu yii nipa awọn Júù ni, sí awọn Júù,
ati fún awọn Júù. Jesu Krisiti
waasu fun awọn Júù ninu Àròyé lori Oke Olifẹti
(eyi ni orukọ inagijẹ tí wọn fun
ibi-kika naa). Oluṣọ-agutan Anderson, awọn Júù
ló n bá sọrọ! Ṣé o kò ri bẹẹ ni! Nigba ti ó sọ
ninu Maaku :, Lẹyin ipọnju naa, lẹyin naa ni
ó sọ nipa Jesu n bọ̀ láwọ̀sánmà
ni ẹsẹ , ati kíkó awọn ayanfẹ jọ ni ẹsẹ
, lati opin ayé,
títí dé opin ọ̀run, eyi ni ohun tí awọn kan n pè ní
"awọn Júù nikan ni ó n bá sọrọ." Ó dara, ẹyin ẹ wo
ẹsẹ tó kẹyin ni Maaku : Ohun ti mo n wí fun yin yii,
awọn Júù nikan ni mo n wí i fún: ẹ maa ṣe jẹ́ kí
oniwaasu kankan sọ fún yin pé eyi wà fún
gbogbo awọn onigbagbọ o. Awọn Júù nikan ló wà fún. Njẹ
ohun ti Bibeli sọ ní Maaku : niyi bí? Rara o.
Ó sọ pe
(Maaku :) "Ohun ti mo n wí fun yin ni
mo n wí fún gbogbo eniyan: ẹ maa sọ́nà.".
Oluṣọ-agutan Anderson: Gbolohun tó gbẹyin ní orí naa niyi.
(Mark :) "Ohun ti mo n wí fun yin ni
mo n wí fún gbogbo eniyan: ẹ maa sọ́nà."
Oluṣọ-agutan Anderson: Sibẹ awọn eniyan
sì tun n sọ pe, "Orí yii kò
bá gbogbo eniyan wí. "Awọn Júù nikan
ni ó n báwí." Àfi bí i pé ó ti mọ̀ pé
awọn eniyan maa sọ bẹẹ ni, ni ó fi sọ ọ́ ní igbẹyin
ibi-kika yii. Gbogbo
eniyan ni mo n bá sọrọ nigba ti mo sọ pé Ẹ maa sọ́nà.
Gbogbo eniyan ni eyi wà fún. Lati sọ pe awọn Júù nikan
ibi-kika yii nbáwí panilẹrin. Nigba ti ó sọ ọ gbagada pé
(Mark :) Ohun ti mo n wí fun yin ni
mo n wí fún gbogbo eniyan: ẹ maa sọ́nà.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ní ọpọ igba, awọn eniyan yoo wo
Mateu :-, wọn yoo sì sọ pe, "Kò buru,
bi o tilẹ jẹ pe ó jọ igbasoke naa, bi o sì
tún jẹ́ pe ó n fọhùn bí igbasoke naa, kì í
ṣe igbasoke naa," idi tíwọn sì fi
maa sọ pe kì í ṣe igbasoke naa nìyí
tí ẹ bá wo ẹsẹ , ó sọ pe, "Yoo sì
rań awọn angẹli rẹ̀ pẹlu ohùn ìpè nla,
wọn o sì kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati orígun
mẹrẹẹrin ayé jọ, …" awọn eniyan yoo sì wo
ọrọ naa, wọn sì maa sọ pe, "Ṣe ẹ ri bẹẹ, ọrọ naa
'ayanfẹ' kì í ṣe fun awa Kristiẹni o." Wọn a sọ pe,
"Awọn ọmọ Israẹli ni 'ayanfẹ' Tori idi eyi, Mateu
kọ ni igbasoke naa. Kì í ṣe fún
awa Kristiẹni. Awọn Júù ni gbogbo ori naa wà fún
nitori tí ó n ṣọ nipa awọn ayanfẹ"
Kókó ọrọ ibi ni pe: kí a gba Bibeli laaye kí ó tumọ ararẹ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Mo ní iye ìgbà tí
Bibeli ko ọrọ naa "ayanfẹ" A kò ní wulẹ̀
ni lati ka gbogbo rẹ̀ nitori kò sí àkókò, sugbọn
mo le sọ gbogbo awọn igba tí a lo "ayanfẹ"
mo sì tun le fihan yin pe nígbà kọọkan ti ó wáyé,
awọn tí a gbala ni ó n tọka sí.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Idi naa tí awọn eniyan fi rò pe
awọn Júù ni ọrọ naa "ayanfẹ" n tọka sí, tabi awọn
"awọn ọmọ Israeli," ní n sọ ni pe, eyiti wọn fi maa
ṣe àṣàrò lori Bibeli wọn, eyití wọn maa ka Bibeli wọn
awọn àlàyè inu Bibeli ni won n kà, wọn sì ti tun
maa n ka awọn iwe tí ti ọwọ awọn eniyan kọ,
tí awọn eniyan yii sì ti sọ ohun tí "ayanfẹ"
jẹ fun wọn. Atọka Bibeli Scofield
ní arokọ kan lori Mateu tí ó sọ pe ọro naa
"ayanfẹ" n tọka sí "Israẹli." Sugbọn
Bibeli fúnrarẹ̀ sọ tumọ ararẹ̀, tí Bibeli sì fun wa
ní idahun sí awọn ibeere lori awọn ẹkọ naa
tí a ní, ti ẹ bá ṣe àsàrò nipa rẹ̀ ninu Bibeli,
ọrọ naa "ayanfẹ" kò tọka si awọn Júù nikan
Oluṣọ-agutan Anderson: Lati tanná sí ọrọ naa ní kíá fun yin,
ní Awọn ara Tẹsalonika :, ó sọ pe:
( Thessalonians :) Nitori pé awa mọ yíàn yin, ará, olufẹ ti Ọlọrun;
Oluṣọ-agutan Anderson: ...ó n bá Awọn ara Tẹsalonika sọrọ
tí wọn jẹ awọn Keferi. A rí i ninu iwe Awọn ara Romu
:
(Awọn ara Romu :) Tani yoo ha ka ohunkohun
sí ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ọlọrun ní n dáre.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ninu ibi mẹrindinlogun ti Bibeli
ti lo ọrọ naa "ayanfẹ", mẹwaa ninu wọn ni n sọ
nipa awọn onigbagbọ lapapọ, meji ninu wọn n tọka si
awọn onigbagbọ tí wọn jẹ́ Keferi ní pàtó,
ọkan ninu wọn n tọka si awọn onigbagbọ tó jẹ́ Júù
meji n tọka si Jesu Kristi funrarẹ̀,
ọ̀kan n tọka si Jakọbu, gẹgẹ bí ẹnikan,
tí Ọlọrun yàn. Mo maa fun yin ní ẹsẹ
kan tí ó sọ ọ́ kedere pé ayanfẹ kì í kàn ṣe
fun "Israẹli" nitori awọn eniyan sọ pe,
"Awọn ayanfẹ naa? Awọn ọmọ Israẹli ni. Awọn Júù ni."
(Romans :) Ki ha ni? Ohun tí Israẹli n wá kiri, oun
naa ni kò rí; sugbọn awọn ẹni-ìyànfẹ́
ti rí i, a sì ṣé àyà awọn yooku le.
Oluṣọ-agutan Anderson: Tori eyi, Bibeli sọ pe, Israẹli kò rí;
awọn ẹni-ìyànfẹ́ ti rí i. Bí ó bá jẹ́ bẹẹ, bí Israẹli
bá jẹ́ ẹni-ìyànfẹ́, eyi kò mú ọgbọn kankan lọ́wọ́.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ó hàn kedere kaakiri inu
iwe-mimọ, tí ẹ bá gba Bibeli laaye kí ó ṣàlàyé
ararẹ̀, pé kì í ṣe awọn Júù ni "ayanfẹ" naa,
pé kì í ṣe orilẹ-ede Israẹli ní "ayanfẹ",
awọn tí-a-gbàlà ní ayanfẹ. Wọn le wa lati ilẹ Asia;
wọn le jẹ́ ẹ̀yà Gírìkì, wọn le jẹ́
kògbédè, wọn le jẹ́ ẹ̀yà yoowu. Tí o bá ti gbé
Kristi wọ̀, tí o bá ti gbé ẹni tuntun
wọ̀, ayanfẹ ni o jẹ́. Torí naa, nigba ti a bá pada wo
Mateu , ó sì sọ pé,
"Yoo wa rán awọn angẹli rẹ̀ pẹlu fere nla,
wọn yoo
kó awọn ayanfẹ jọ," eyi ṣe deedee pẹlu ibi-kika yii,
tí a bá ní kí a sọ ododo nipa pé
igbasoke awọn tí-a-gbàlà.
Oluṣọ-agutan Anderson: Kò ní nnkan kan ṣe pẹlu
pe boya wọn jẹ́ Júù tabi Keferi kan, dudu ni
tabi funfun. Awọn ayanfẹ naa ni awọn tí a ti gbala,
Yoo kó wọn jọ papọ nínú ìkùukùu
pẹlu rẹ̀. Njẹ eyi kì í ṣe deedee pẹlu
ohun tí Tẹsalonika ori
sọ bí? Nigba ti ó sọ pe ìpè yoo dún,
ati pe awọn tì a gbala ni yoo kó
kó jọ pẹlu Kristi. Nigba ti ò ṣe diẹ ní orí naa,
ó sọ pé, "Sugbọn ní ti
ọjọ ati wakati naa. kó sí ẹnikan tí ó mọ́ ọ́..." tori bẹẹ,
kò sí ẹni ti ó mọ̀ ọjọ tabi wakati naa tí eyi yoo ṣẹlẹ.
Emi kò le sọ fun ọ, "Yoo ṣẹlẹ ninu oṣu Kẹwaa, ní
ọjọ bayii-bayii, ní ọdun yii " Lẹyin naa, ó tún sọ ní:
(Matthew :) Nigba naa ni ẹni meji yoo wà ni oko;
a o mu ọ̀kan, a o si fi ekeji silẹ.
(Mateu :) Awọn obinrin meji yoo jumọ maa
lọ ọlọ pọ̀; a o mu ọ̀kan, a o sì fi
ekeji silẹ.
(Mateu :) Nitori naa ẹ maa ṣọ́nà: nitori ẹyin
kò mọ̀ wakati tí Oluwa yin yoo dé.
Oluṣọ-agutan Anderson: Tori bẹẹ ni Ọlọrun
fi n sọ fun wa pe a kò mọ igba ti yoo jẹ́.
Ohun kan tí a gbọdọ maa sọ́nà fún ni. A kò mọ
ọjọ tabi wakati naa, sugbọn o sọ fun wa pe LẸYIN
IPỌNJU NAA ni, nitori ó sọ pe LẸYIN IPỌNJU NAA
ni òòrùn ati oṣupa yoo ṣókùnkùn,
nigba ti Jesu Kristi bá dé lawọsanma. Nigba
yii ni fere máa dún. Nigba naa ni
a o gba awọn onigbagbọ soke. Titori pe a kò
kàn mọ ọjọ tabi wakati naa, kọ́ ni yoo
duro fún pe kí a wá sọ pe o le ṣẹlẹ nigbakuugba.
Ọpọlọpọ eniyan yoo wo pe,
"kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọjọ tabi wakati naa,"
ti wọn yoo sì sọ pe "o le ṣẹlẹ nigbakuugba"
Ó dara, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pe LẸYIN IPỌNJU NAA ni.
Eyi ni a maa rí nínú iwe
Mateu, Maaku, and Luuku. Mateu sọ nipa rẹ̀ ni ori ,
Maaku sọ tirẹ̀ ni ori ,
Luuku sọ tirẹ̀ naa ni ori ati ori ,
Lẹyin naa sì ni Johanu sọ tirẹ̀ ninu iwe Ifihan.
Awọn mẹrẹẹrin ni wọn sọ nipa rẹ̀. Akọkọ ni ipọnju naa,
lẹyin eyi ni òòrùn ati oṣupa yoo ṣókùnkùn,
lẹyin naa ni Jesu yoo wá ninu
ìkùukùu ni àkókò igbasoke naa.
Ìran - "Ipọnju" kò tumọ sí "ìbínú"
Oluṣọ-agutan Anderson: Idi tí awọn eniyan fi n rò pé
igbasoke siwaju ipọnju naa ni
pe wọn n rò ó pé ipọnju naa tumọ sí ibinu Ọlọrun.
Ọna kan lati fidi eyi mulẹ pe ibinu Ọlọrun
ati ipọnju naa yatọ si ara wọn patapata
n bẹ ninu Mateu :, tí ó sọ pe,
Lojukan naa lẹyin ipọnju ọjọ wọnyii ni
òòrùn yoo sokunkun, oṣupa
kì ì yoo sì fi imọlẹ rẹ̀ hàn." Tori naa, Bibeli
hàn kedere ní Mateu pe òòrùn ati
oṣupa yoo ṣokunkun LẸYIN IPỌNJU NAA. Ó dara,
bí o ba lọ sí iwe Ifihan ori nibi ti o ti maa kà
nipa àkókò naa ti òòrùn ati oṣupa tí ṣokunkun (nigba ti
èdìdí kẹfa ṣí), ó sọ pe," ...
òòrùn sì dudu bi aṣọ onirun, oṣupa
sì dabi ẹ̀jẹ̀; ọ̀kan naa gẹ́lẹ́ pẹlu
bí ó ti sọ ọ́ ni Mateu .
(Ìfihàn :) Awọn ìràwọ̀ oju ọ̀run sì ṣubu silẹ gẹgẹ bi ọ̀pọ̀tọ́ ti ṣe
n rẹ̀ àìgbó èṣo rẹ̀ dànù nigba tí ẹfuufu nla bá mì ín.
(Ìfihàn :) A sì ká ọ̀run kuro bí iwe ti a ká; ati
olukuluku oke ati erékùṣù ni a sì ṣí kuro ni ipo wọn.
(Ìfihàn :) Awọn ọba ayé ati awọn ọlọ́lá ati awọṅ olórí ológun,
ati awọn ọlọ́rọ́, ati awọn alagbara, ati olúkúlukú
ominira si fi ara wọn pamọ́
ninu iho-ilẹ, ati ninu apata ori oke.
(Ìfihàn :) Wọn sì n wí fún awọṅ oke ati awọn apata
naa pe, "Ẹ wólù wá, kí ẹ sì fi wa pamọ kuro
kuro loju ẹni ti ó jokoo lori ìtẹ́, ati kuro
ninu ibinu Ọdọ-agutan naa:
(Ìfihàn :) Nitori ọjọ nla ibinu wọn dé;
tani sì le duro?!
Oluṣọ-agutan Anderson: Tori naa, gẹgẹ bi eyi,
nigba wo ni ibinu Ọlọrun nbẹ̀rẹ̀? Nigba ti
òòrùn ati oṣupa bá ṣókùnkùn ni ìgbà ti wọn
sọ pe, "Ọjọ nla ibinu rẹ̀ ti dé."
Ọrọ-iṣe naa, TI dé, tumọ si pe ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ni.
Tori naa, bí Mateu ba sọ pe òòrùn ati
oṣupa bá ṣókùnkùn LẸYIN IPỌNJU NAA,
ati tí ibinu Ọlọrun kò bá bẹrẹ títí di ẹ̀yìn
ìgbà tí òòrùn ati oṣupa bá ṣókùnkùn, bawo ni wọn
ṣe le jẹ nnkankan naa? Tori naa ibinu naa kò le bẹ̀rẹ̀
títí di ẹ̀yìn ìgbà tí òòrùn ati oṣupa bá ṣókùnkùn.
Ní ọpọ igba, ti ẹ bá beere pe ki awọn eniyan
fi iwe-mimọ tí n sọ nipa igbasoke siwaju ipọnju hàn yin,
wọn kò ní í rí ẹsẹ kankan fihàn yin. Mo maa pe
ẹnikẹni níjà pe kí ó fi ẹsẹ kan tó lo ọrọ
naa "ipọnju" lati gbe
igbasoke siwaju ipọnju lẹ́sẹ̀. Wọn kò le ṣe é.
Wọn maa ni lati fi awọn ẹsẹ tó lo
ọrọ bí i "ibinu" ni wọn maa fihàn yin. Wọn rí awọn
ẹsẹ tí n ṣafihan pe awa Kristiẹni kò sí labẹ
ibinu Ọlọrun, wọn sì maa fi awọn ẹsẹ
tí n sọ pe a kò kọ ibinu Ọlọrun mọ́ wa, ati pe,
a ti gba wá là lọwọ ibinu. Wọn sì sọ pe,
"Wò ó, níbẹ̀, Bibeli sọ pe awa kò ní la
ipọnju kankan kọja. Sugbọn ẹ tilẹ duro ná:
ipọnju ati ibinu kì í ṣe ọ̀kan naa rara!
Kò sí ẹsẹ kan nipa igbasoke n siwaju ipọnju tí o lo
ọrọ naa "ipọnju" tí iru awọn onigbagbọ yii le fihàn yin
lati fi idi ẹkọ yii mulẹ. Awọn ẹsẹ kan ti n sọ
nipa ibinu Ọlọrun ni wọn maa mu yin lọ.
Ibinu Ọlọrun ati ipọnju naa jẹ ohun meji tó yatọ
patapata sí ara wọn. Ọpọ Kristiẹni ni wọn ti kọ́
wọn ninu ijọ wọn ati nipasẹ iwe tí wọn ti kà
pé awọn ohun mejeeji yii jẹ́ ọ̀kan naa.
Ti o bá sì gbiyanju lati sọ fun wọn, "Gbọ́ mi! A
maa wà nibi nígbà ipọnju naa! Igbasoke naa
kò ní í ṣẹlẹ titi di LẸYIN IPỌNJU NAA." Ohun ti
wọn maa da ọ lóhùn niyi: "Rara o, Ọlọrun
kò ní í da ibinu rẹ̀ sori awọn eniyan rẹ̀ o. A kò
kọ ibinu mọ́ wa. A maa
gbà wá lọwọ ibinu rẹ̀ ni. "Àní ẹ duro nà sẹ́:
ṣe ọ̀kan naa ni ibinu ati ipọnju Ọlọrun ni?
Rara o. Tori naa, tí a bá lè fi òye ohun ti ọrọ naa,
"ipọnju" tumọ sí yé awọn eniyan, wọn yoo
lóye pé LẸYIN IPỌNJU NAA naa yoo ṣẹlẹ siwaju
igbasoke naa. Ó kàn jẹ́ pé awọn eniyan kò
lóye ọrọ naa, "ipọnju" tori pe wọn ní èrò
kan ninu ori wọn pe ipọnju naa
jẹ́ àkókò ọlọ́dún meje kan nigba ti Ọlọrun yoo
tú ibinu rẹ̀ síta, tí ó sì n da ina
ati òkúta-iná, tí ó n sọ omi di ẹ̀jẹ̀, tí ó sì
n fi àkeekè dá awọn eniyan lóró, atí awọn
aburú loriṣiriṣị. Awọn yii kọ ni ipọnju naa o.
Eyi kọ ni Bibeli kọni.
Ìran - Májẹ̀mu Tuntun Kọọkan Mẹ́nuba
Ọrọ naa, "Ìpọ́njú"
Oluṣọ-agutan Anderson: Gbogbo awọn tí wọn gbagbọ
ninu "igbasoke siwájú ipọnju naa" yii tabi igbasoke
tí yoo ṣẹlẹ siwaju ipọnju naa, tí ó le ṣẹlẹ
nigbakuugba: ẹ jẹ́ kì a tu ìpèdè naa palẹ̀
"igbasoke siwájú ipọnju naa." Ó ní hóró mẹta ninu.
"Siwájú" tumọ si kinni? "Kí ó tó sẹlẹ̀." Kinni
"ipọnju" dúró fún? "ìpọ́nnilójú." Lẹin naa ni a rí
"igbasoke." Ọrọ naa "igbasoke" kò sí ninu
Bibeli. Àfijọ igbasoke n bẹ ninu Bibeli nitori pe
a rí Jesu tí n bọ̀ wá
ní awọsanma, a sì gba awọn eniyan soke lati
pade rẹ̀ lófurufú, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Torinaa, àfijọ
igbasoke wa nibẹ, sugbọn ọrọ naa gan an, "igbasoke"
ní a kò lò nibẹ. Njẹ́ ọrọ naa, igbasoke n bẹ ninu
Bibeli bí? Tí ẹ ba wo ẹsẹ kọọkan tí a ti lo
ọrọ naa, "igbasoke," ó hàn ni ẹẹmejilelogun
ninu Majẹmu Tuntun. Tori naa, tí Majẹmu Tuntun
ba lo ọrọ naa ni ẹẹmejilelogun,
tí gbogbo eniyan sì tun lọ kiri pẹlu ẹkọ naa tí
wọn n pe ní ̂igbasoke siwájú ipọnju naa," ṣé kò
yẹ kí ọ̀kan lara awọn ẹsẹ mejilelogun yii, tabi ibi-kika
mejeejilelogun naa kọ wa ní ohun kan nipa igbasoke
kan ti yoo wáyé siwaju ipọnju naa bí? Ko si
eyikeyi ninu ẹsẹ wọnyi tí ó sọ nipa igbasoke kan
tí yoo wáyé siwaju ipọnju naa tabi iru nnkan bẹẹ,
tori naa, awọn eniyan oni-igbasoke siwaju ipọnju
naa ni lati gbáralé ọpọlọpọ àlàyé, wọn sì ní lati
ṣàlàyé rẹ̀ fun yin, ó sì maa n saaba
ṣòro gan an. Mo ti ṣakiyesi ohun kan nipa Bibeli:
Ọlọrun fẹ́ kí òye Bibeli yé wa
Kì í gbiyanju lati ṣe àrekérekè fun wa, kí ó da nnkan
rú mọ́ wa loju tabi kí ó mú nnkan ṣòro fun wa.
Ó fẹ́ kí a mọ ododo. Ó nífẹ̀ẹ́ wa. Mo ti
ṣakiyesi pe ni ọpọ igba, nigba akọkọ tí
Bibeli bá dá ọrọ kan silẹ, o maa n ṣe
àlàyé rẹ̀ fun wa, ó sì maa n jẹ́ kí ó yé wa.
Ní ọna yii, tí a ba tun rí i ní ẹẹkeji, a maa mọ̀
ohun tí ó n sọrọ nipa rẹ̀. Bibeli
kà ní Mateu :
(Mateu :) Sugbọn kò ní gbongbo ninu ara rẹ̀, ó sì
pẹ́ diẹ ni akoko kan; nigba ti wahala
tabi inúnibíni sì dide nitori ọrọ naa,
lojukan naa oo sì kọsẹ̀.
Oluṣọ-agutan Anderson: Bawo ni ẹ ṣe ri
àlàyé "ipọnjụ" sí. Inúnibíni ni. Ó sọ pe
"ipọnju" tabi "inúnibini"tí ó wáyé nitori
ọrọ naa. Ṣe tori pe awọn eniyan yii búru gan an
ni wọn fi ń la ipọnju naa kọja ni bí? Bẹẹ kọ o, wọn ń la
ipọnju kọja nitori wọn n duro deedee
ninu ọrọ Ọlọrun ni. Ati nitori pe wọn ti
mú iduro wọn ninu ọrọ Ọlọrun ṣinṣịn,
nitori ti wọn ti fi ayọ gba ọrọ Ọlọrun,
wọn yoo la inubini tabi
tabi ipọnju kọja. Tí a bà duro ṣinṣin tí a sì gbilẹ̀
ninu ohun tí a gbagbọ, nigba ti inunibini
bá dé, a maa faradà á. Igba akọkọ naa tí ẹ
rí i tí wọn lo ọrọ yii "ipọnju" ninu Bibeli,
wọn lò ó ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu "inunibini" ni. Eyi ni
igba akọkọ naa ti wọn lo ipọnju ninu
ninu Majẹmu Tuntun, ti ẹ ba sì n fi ọkàn bá
igba kọọkan kaakiri inu Majẹmu Tuntun tí
wọn lo ọrọ naa "ipọnju" lọ, igba mẹsan an ninu mẹwaa
ní n tọka sí pe awọn onigbagbọ n la ipọnju
kọja - ànì ìrírí naa tí awọn ẹni-igbala là kọja.
Awọn igba meji yooku ti wọn tun lò ó nibi tí
wọn kò ti lò ó nipa awọn ẹni-igbala, kò ní í
nnkankan ṣe pẹlu asọtẹlẹ nipa igba ikẹyin. Ó kàn
n sọrọ nipa awọn eniyan ti wọn n la ipọnju
kọja lapapọ ni. Kaakiri itan ayé ni awọn Kristiẹni
ti la ipọnju kọja, tí kò sì ní í yatọ ní
ìran tiwa yii pẹlu. Boya eyi naa maa
ṣẹlẹ ni igba ayé tiwa, boya bẹẹ kọ, sugbọn tí ó
bá ṣẹlẹ ni igba ayé tiwa, a maa là á
kọja bí onigbagbọ ni. Ninu kí wọn ṣe iku
pa wá nitori ọrọ Kristi, tabi ó ṣeéṣe kí
a là á igba yii kọja títí tí igbasoke naa yoo ṣẹlẹ.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ìgbà ẹkarun un tí ọrọ naa
"ipọnju" tún jẹyọ ninu Majẹmu Tuntun ní a rí ní
in Johanu :.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ó n bá awọn onigbagbọ sọrọ.
Awọn ọmọ-lẹyin rẹ̀ ni ó n ba sọrọ. Ó sọ pe
(Johanu :) Mo ti sọ nnkan wọnyii fun yin
kí ẹ le ní alaafia nipa wíwà ninu mi. Ẹ óo
ní ipọnju ninu ayé, sugbọn ẹ ṣe ara gírí,
mo ti ṣẹgun ayé!
Oluṣọ-agutan Anderson: Njẹ ó sọ pe iwọ
yoo wà láìní ipọnju bi? Njẹ ó sọ
pe iwọ kò ní í la ipọnju kọja bi? Njẹ ó sọ pe,
"Emi kò ní í jẹ kí awọn eniyan mi la ipọnju kọja!
Mo nifẹẹ wọn pupọ!" Rara o! Kinni igba akọkọ
ti a kọ nipa "ipọnju" sọ ní Mateu ?
Pe tí awọn eniyan kò bá duro ṣinṣin kí wọn sì gbilẹ̀,
tí inunibini tabi ipọnju bá dide
nitori ọrọ naa, igbagbọ wọn le yẹ̀. Ẹ wo
nnkan ti Jesu sọ ni ori ibi-kika naa
tí ó kilọ fun wa ni ẹsẹ ekini:
(Johanu :) Mo sọ gbogbo nnkan yii
fun yin kí igbagbọ yin ma ba à yẹ̀
Oluṣọ-agutan Anderson: Ó n sọ pe tí oun kò ba
sọ fun yin nipa eyi, ti oun kò bá kilọ fun
yin nipa awọn inunibini ati ipọnju
ati idanwo ti ẹ maa là kọja ninu
ayé yin, tí wọn bá ṣẹlẹ, yoo ba yin lójijì.
Ẹ maa sọ igbagbọ yin nù. Ẹ le sọ pe, "Kilode
tí ẹ n waasu iru eyi, Oluṣọ-agutan Anderson?"
Mo n ṣe iwaasu yii kí
igbagbọ yin má ba à yẹ̀. Ẹ sọ pe, "Duro ná, iwaasu yii
n bi eniyan ninu jare!" Rara o, iwaasu yii n wá
kí igbagbọ rẹ má ba à yẹ̀ ni o, tori Jesu sọ
pe tí ẹ ba mọ̀ pé eyi n bọ̀, igbagbọ
yin kò ní í yẹ̀. Wo ẹsẹ kẹrin:
(Johanu :) Sugbọn mo ti sọ gbogbo
nnkan wọnyi fun yin, kí ẹ le ranti pe
mo ti sọ fun yin tẹlẹ, nigba ti ó bá yá, tí wọn bá n ṣe
é si yin. N kò sọ awọn nnkan wọnyi fun yin lati
ibẹrẹ nitori mo wà lọ́dọ̀ yin.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ó sọ ọ́ nibẹ pe nigba
ti awọn nnkan yii ba ṣẹlẹ, ẹ maa ranti pe
mo sọ bẹẹ fun yin, mo sì n sọ ohun kan naa
tí Jesu sọ naa lalẹ yii. Nigba ti nnkan wọnyi
bá bẹrẹ sí ní í ṣẹlẹ - o le mà jẹ́ ní sáà tiwa yii;
o le jẹ́ ọgọrun un ọdun sí ìsìnyii; boya o tilẹ
le jẹ́ ọdun diẹ sí akoko yii; a kò mọ igba
tí igbẹyin maa dé - sugbọn nigba ti ó ṣẹlẹ,
ẹ maa ranti pe mo sọ fun yin. Ni pataki ju eyi lọ,
nitori pe kì í ṣe lati ọgbọn ori mi
ẹ maa ranti pe Jesu sọ bẹẹ fun yin.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Igba miran tí ẹ tún le gbọ
ọrọ naa, "ipọnju" ni a rí ninu Ìṣe Aposteli :, ó
sọ pe,
(Acts :) Wọn n mú awọn onigbagbọ lọ́kàn le,
pe kí wọn duro ṣinṣin ninu igbagbọ.
ọn n fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ijọba Ọlọrun,
ó ni lati ní ọpọlọpọ ìṣòro.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Gbolohun tí ó fanimọra yii
n sọ pe "a ni lati la iṣoro pupọ kọja
kí a tó le wọ ijọba Ọlọrun" - gbolohun kan
yii lati inu Bibeli pe
awa yoo ni lati la ipọnju kọja fun wa nigba
ti a bá maa wọ ijọba Ọlọrun, kì í ṣe pe
a maa wọ ijọba Ọlọrun siwaju ipọnju.
Oluṣọ-agutan Anderson: Njẹ ó sọ pe, Eniyan yoo wà
laaye, yoo dara pe awa yoo ti lọ siwaju ipọnju naa!"
Rara o, ó sọ pe, "Ó dara ju kí a ní idaniloju nipa wọn.
Ó dara ju kí a mú wọn duro ṣinṣin nipa awọn nkankan.
Ó dara pupọ kí a dì wọn lámùrè nitori pe
ó sàn kí wọn mọ̀ pe nipasẹ ọpọ ipọnju
ni wọn maa wọ ijọba Ọlọrun." Njẹ nọmba kẹfa sọ nipa
igbasoke kan ti n siwaju ipọnju bi?
Emi kò rò bẹẹ.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ní Kọrinti :, Bibeli
sọ pe:
( Kọrinti :) Ọkàn mi balẹ̀ lori ọrọ yin.
Mo n fi ọwọ yin sọ̀yà, mo ti ní ìtùnú kíkún
ninu gbogbo ipọnju wa, mo ní ayọ lọpọlọpọ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Kò sọ pe, ayọ mi kún pupọ
nitori emi kò ní la ipọnju kọja.
Ayọ mi pọ̀ pupọ pe a maa gba wa soke
siwaju ipọnju naa!" Ohun tí ó sọ kọ niyi.
Ó sọ pe, "Ninu gbogbo ipọnju wa, mo ni
ayọ lọpọlọpọ." Nibo ni igbasoke siwaju
ninu ibi-kika yii? Kò sí nibẹ.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ó jẹ́ iyalẹnu fun mi pe bí
ẹ ṣe n fojúrí ọrọ naa, "ipọnju" kaakiri inu
iwe-mimọ, ẹ maa rí atọka nílọ̀póo-nílọ̀póo
sí awọn onigbagbọ tí n sọ pe wọn n la
ipọnju kọja. Ó sọ pe, "...ninu gbogbo ipọnju wa."
Kì í ṣe ohun ti oní-gbàgbọ́ kò ní í là kọja.
Ohun tí onígbàgbọ́ tí n là kọjá fún gbogbo
ọjọ aye wọn ni.
Lati ìrandíran, ni awa onigbagbọ ti la
ipọnju kọja.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ fi sọ́kàn o, ẹyin ara, Ọlọrun
kò lè fi júrujùru bò wá loju. Kò gbiyanju lati
dà wá báṣabàṣa. Eniyan ni ó ti n ṣe yin báṣabàṣa!
Awọn oniwaasu ni wọn ti n ṣe yin báṣabàṣa!
Eré ori móhùmáwòrán ati awọn fíìmù (Awọn Tó Kù Lẹ́yìn,
abbl.) ni n ṣe yin báṣabàṣa!. Ọlọrun kò lè ṣe
yin báṣabàṣa!
Oluṣọ-agutan Jimenez: Tí a ba gba Bibeli laaye
kí ó ṣiṣẹ atúmọ̀, tí a sì gba Bibeli laaye
lati ṣàlàyé awọn ọrọ fun wa, a wa yoo rí i pe
ọrọ naa, "ipọnju" kì í ṣe ni ibinu Ọlọrun.
Inúnibíni ni, ìnira ni. Wahala ni.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ maa rò pe ẹṅikan le
fi ọ̀kan lara awọṅ ẹsẹ mejilelogun naa hàn yin.
Ẹ fi ẹsẹ kan hàn mi tó sọ pe a ti maa
lọ kí ipọnju naa tó ṣẹlẹ, tabi pe a maa
pàdé lókè siwaju ipọnju naa, tabi pe igbasoke
yoo ṣẹlẹ siwaju ipọnju naa.
Sibẹ mo le fihàn yin ní daju-ṣáká awọn ibi naa
ti Bibeli ti sọ pe lẹsẹkẹsẹ lẹyin ipọnju naa,
Jesu m bọ lawọsanma, fèrè yoo
dún, tí awọn ayanfẹ yoo sì pade pẹlu
lókè ninu ìkùukùu. Kò jù bẹẹ lọ. Awọn tí wọn
gbagbọ ninu igbasoke siwaju ipọnju naa
ní lati gbarale awọn eniyan naa tí wọn n
ṣe gbédègbẹyọ̀ ati ọgbọn-ori, ati pe,
"Kò buru naa, nigba tó jẹ pe a kò kúkú mọ
ọjọ tabi wakati naa, ó jásí pe igbakuugba ni ó ṣẹlẹ,
tí ó bá sì le ṣẹlẹ nigbakuugba, a jẹ pe
siwaju ipọnju naa ni yoo jẹ." Tabi wọn yoo
ní awọn aworan tó ṣoro lati mọ̀ fun yin.
Sugbọn tí ẹ ba kàn gbe Bibeli yin, ti ẹ sì
ní gẹ́lẹ́ bí ẹ ṣe rí i ninu rẹ̀ - ki ẹ ka Majẹmu Tuntun
bẹrẹ lati Mateu ori ekini, - tí ẹ bá ti dé Mateu
ori , ibẹ ló wà, tó mọ́ gaara bí oju-ọjọ: LẸYIN
IPỌNJU NAA Jesu n bọ̀ lawọsanma.
Ìran - Ọ̀mọ̀wé Kent Hovind ni yii
Oluṣọ-agutan Anderson: Ọ̀mọ̀wé Kent Hovind jẹ
gbajumọ ajiyinrere tí ó gbagbọ ninu igbasoke siwaju ipọnju naa
tí ó sì tun nwaasu nipa rẹ̀ fun ọdun mejidinlogun.
Sugbọn ni bayii, ó wa lẹ́wọ̀n, lati igba tí ó sì ti
wà lẹ́wọ̀n naa, óti n ka Bibeli rẹ̀, ó sì wá han
gba-n-gba sí i pe igbasoke n siwaju ipọnju naa
kò sí ninu iwe-mimọ, mo sì fẹ pe e sori ago bayii
lati mọ sí i nipa ohun tí ó mú u
yipada ninu èrò rẹ̀. Ki lo mú u sọjí pe
LẸYIN IPỌNJU NAA ni?
Ọmọwe Kent Hovind: Orukọ mi ni Kent Hovind. Mo jẹ
olukọ imọ sayẹnsi ni girama fun ọdun mẹẹdogun
lẹyin naa ni mo di ajiyinrere fun ogun ọdun,
ti mo n kọni nípa ìṣẹ̀dá ati ìyírapadà. Mo sì ti
n kọminu lori ojuwoye mi nipa igba ikẹyin
ati bí ó ṣe tan mọra wọn ninu iwe-mimọ,
mo sì ti rí àrídájú bayii, eyi ṣẹlẹ ní bí ọdun mẹta
sẹyin, pe ohun tí wọn fi gbogbo aye mi kọ mi
kì ì ṣe otitọ. Mo ni lati yi ọkàn mi pada, sí
àìdunnú awọn ara-mi-ninu-Oluwa,
nitori iduro mi bayii tako igbasoke siwaju
ipọnju naa. Bibeli sọ pe ní ikẹyin ọjọ, awọn
awon ẹlẹgan yoo fínnúfíndọ̀ kọ eti ikún sí ìṣẹ̀dà,
ìkún-omi, ati idajọ ti n bọ. Kò burú, Mo lo
ogun fi kọ awọn eniyan kaakiri agbaye nipa
iṣẹda ati ikun-omi, sugbọn mo mọ̀ọ́mọ̀
má kọbi-ara sí kikọni ni idajọ ti n bọ̀, nitori idi
kan pe, kò fi bẹẹ ye emi gan an funra mi. Ní
Mateu ori , ni a ti rí iwaasu Jesu nibi ti awọn
ọmọ-lẹyin rẹ̀ ti beere lọwọ rẹ̀ kedere pe: kinni
awọn àmì pipadabọ rẹ? Ati pe nigba wo ni
yoo ṣẹlẹ? A rí itan yii kan naa kà ninu Maaku
ori ati ni Luuku , tori naa mo da awọn oju-iwe
Bibeli lati ibi-kika mẹtẹẹta naa kọ, mo sì gbé wọn
ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ànì awọn akọsilẹ mẹtẹẹta yii.
Lọgan tí ó bá ti yọ gbogbo awọn
àlàyé inu rẹ̀ jade tan, yoo sì bẹrẹ sí ní mọlẹ
gaara sí i pe ọrọ lori igbasoke siwàjù ipọnju
kì í ṣe otitọ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Kinni idi ti ẹ fi rò pe ọpọ
gbagbọ ninu igbasoke siwájú ipọnju naa? Ki lode
tí ẹkọ yii ṣe gbajumọ tó bẹẹ?
Ọ̀mọ̀wé Kent Hovind: Nitori pe ó bá wọn dahun awọn ibeere
adójútini kan. Onigbagbọ kò le dahun
awọn ibeere nipa ẹranko dáínósọ̀ọ̀. Nibo ni wọn
bámu? Nitori naa ni wọn ṣe ronu "kinni kí a sọ"
tí wọn sì gbà á bẹẹ. Mo lérò pe ọrọ lori
igbasoke siwájú ipọnju naa ṣe wẹ́kú pẹlu
ìsọ̀rí awọn eniyan elétí ikún ni. Ohun ti ó
n wùwọn gbọ ni yii.
Oluṣọ-agutan Anderson: Bẹẹ ni o.
-
-
Ọmọwe Kent Hovind: Wọn fẹ gbọ, " Wò ó,
Emi kò nílò lati farada ijiya." Ò dara, Jesu
sọ pe asiko ipọnju kan n bọ̀, iru eyi tí
oju kò rí iru rẹ̀ rí lati igba tí ayé ti bẹrẹ. Ànì,
ṣe iwọ rò pe Ìfipágbọ́tẹnu-ẹni awọn Spaniṣi búru?
tabi Ìpaláparun awọn Júù lati ọwọ awọn Jamani
jàì? Tabi ti Ìṣenúnibíni Awọn Romu sí awọn Kristiẹni?
Yoo buru ju gbogbo awọn yii
lapapọ lọ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ó ga o. Eyi lé kenkà o.
-
-
Ọmọwe Kent Hovind: Ayé bẹrẹ pẹlu pe Kaini pa Abẹli
- awọn eniyan buburu n pa
awọn eniyan rere.
Oluṣọ-agutan Anderson: Otitọ ni.
Ọmọwe Kent Hovind: Bí ó ṣe rí niyi lati ìgbà
tí aláyé ti dáyé. Jesu sì sọ fun wọn pe nigba ti
wọn ba pa yin tabi tí wọn ṣe inunibini sí yin,
ẹ yọ̀, nitori èrè yin tobi
ijọba ọrun.
Oluṣọ-agutan Anderson: Tí a bá mú itumọ Bibeli
fun ohun ti "ipọnju" tumọ sí (tí kì í ṣe
itumọ ìdibàjẹ̀ tí wọn fun) - tí a
bá mú itumọ inu Bibeli fun
"ipọnju," gan an, ṣe ẹ kò ní sọ pe ẹ n la ipọnju kọja
bayii bí?
Ọmọwe Kent Hovind: Bẹẹ ni o. "Ipọnju" ni awọn
ohun naa tí ayé n ṣe sí wa, ó sì ti
ṣẹlẹ fun ẹgbẹgbẹrun ọdun. Jesu sọ pe,
"Ninu ayé yii ẹ oo rí ipọnju: sugbọn
ẹ tújúká: tori ti mo ti bori ayé."
Kristiẹni ni lati reti ipọnju o, èrè
sì n bẹ fun wa tí a bá là á kọja pẹlu ifarada.
Ìran - Àlàkalẹ̀-àkókò ninu Ìwé Ìfihàn
Oluṣọ-agutan Anderson: Ọmọwe, ni bayii, nigba ti ó ti
jẹ́ pe isọri jẹ́ ti "Alákatakítí Ẹ̀sìn" eyi le bọ
sí isọri kan ni ọkàn awọn eniyan kan, lati
maa ró pe igbẹyin maa dé sí
ayé yii - pe ipadabọ ẹlẹkeji Jesu Kristi
yoo ṣẹlẹ gẹlẹ. Idi niyi tí
mo kàn fẹ ṣàlàyé fun yin ní kukuru - mo
kàn fẹ fun yin ní àlàkalẹ́-àkókò lérèfé
lori awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ gẹgẹ bi
Bibeli ṣe sọ, ati bí wọn yoo ṣe ṣẹlẹ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Mo lérò pé
kọ́kọ́rọ́ sí ìlóye Ìwé Ìfihàn ni lílóye bí
ó ti nṣẹlẹ̀. Ọlọ́run fún wa ní Ìwé Ìfihàn láti
sá wà ní bẹẹ gẹlẹ - ìfihàn kan - láti ṣe àfihàn
àwọn nnkan yìí fún wa, láti máṣe fi
wọ́n pamọ́. Kì í ṣe ìwé Ìfarasin. Ó jẹ́ ìwé
ti Ìfihàn, Ọlọ́run sì nfẹ́ kí ó yéni
pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Ìdí nìyi tí ó fi fún wa ní
ọ̀nà tí ó fi lè tètè yéni. Tí ẹ bá bẹ̀rẹ̀
sí íkà á ní orí ìkíní, ẹ wà
ní sáà ti Kristi àbí agbègbè ibẹ̀ nítorí pé
Johannu wà ní erékùsù Patimo, tí Johannu sì ti
nrí inúnibíni fún kíkéde Ìhìnrere, nítorí náà
a nsọ nípa sáà tí ó dín ní ọgọ́rùn ún ọdún
lẹ́yìn wíwá Kristi sí ayé yìí. Nígbà náà ni
ó nrí ìran níbi tí ó ti nrí Jesu
Kristi Olúwa tí ó nfi ara hàn án. Lẹ́yìn náà ní
orí ìkejì sí ìkẹta Jesu Kristi nránṣẹ́
sí àwọn ìjọ méje ti Asia yìí, tí ó sì hàn
pé àwọn yii ni ìjọ ti àkọ́kọ́
ní sáà ọgọ́rùn ún ọdún, ní àkókò naa. Lẹ́yìn
náà ní orí ìkẹrin sí ìkarùn ún, a rí ìran náà lókè ọ̀run níbi tí ó
júwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó nṣẹlẹ̀ ní Ọ̀run. Lẹ́yìn
náà ní orí kẹfà a dé ibi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí
ìpọ́njú náà gan an. Orí keje ni ibi tí ogunlọ́gọ̀
ènìyàn ti nfarahàn ní Ọ̀run - tí ó hàn pé òun ni
ìgbàsókè náà - gbogbo orílẹ̀-aye àti èdè ni ó
péjú níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ní ẹsẹ ìkẹjọ sí ìkẹsàn án, ẹyin
yoo rí Ọlọ́run tí ó nrọ̀jò ìbínú rẹ̀ lórí ayé yìí. Lẹ́yìn
náà ní orí ìkẹwàá jẹ́ orí ìwé tí ó lápẹẹrẹ
tí ó nsọ nípa àwọn nnkan díẹ̀ kí ipè keje
tó dún. Lẹ́yìn náà ní orí ìkọkànlá a rí
ipè keje tí ó ndún. Gbogbo ìyẹn láti
sọ èyí: tí ẹ bá wò ìwé Ìfihàn,
àwọn orí mọ́kànlá àkọ́kọ́ ntẹ̀lé àlàkalẹ̀
àkókò tí ó mọ́gbọ́n dání. Ẹ nbẹ̀rẹ̀ ní nnkan bí
sáà Kristi, tí ó pẹ́ tó Kristi. Lẹ́yìn
náà ẹ ó wọnú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fun
ọjọ́ iwájú: ti i se ìpọ́njú náà, lẹ́yìn náà ni ìgbàsókè,
lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run nrọ́jò ìbínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà nígbà tí
ipè ìkeje bá ndún ní orí ìkọkànlá, ìbẹ̀
ni òpin wà, níbi tí ó ti nsọ pé, Ìjọba
ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀;
on o si jọba
lai ati lailai. Ṣùgbọ́n ohun tí ó dùn mọ́ni
ni pé tí ẹ bá dé òpin orí
ìkọkànlá, ẹ rí òpin naa ní ìkẹyìn. Ó dára,
lẹ́yìn náà ẹ ó dé orí ìkejìlá, ìbẹ̀ sì ní
a ti ri ayipada nlá ninu iwe Ifihan
nitori pe ti a bá wo ẹsẹ ikinni ti ori ikejilá tí
a ṣẹ̀ṣẹ̀ wò. O nsọ pé:
Àmi nla kan si hàn li ọrun;obinrin kan ti a fi
õrun wọ̀ li aṣo, oṣupa si mbẹ labẹ ẹsẹ rẹ̀,
ade onirawọ mejila si mbẹ ni ori rẹ̀:
(Ifihan :) O si lóyun, o si kigbe ni irọbi,
o si wà ni irora
ati bimọ.
(Ifihan :) Àmi miran si hàn li ọrun;
si kiyesi i, dragoni pupa nla kan,
tí ó ní ori meje ati iwo mẹwa
ati adé meje li ori rẹ̀.
(Ifihan :) Ìru rẹ̀ si wọ́ idamẹta awọn irawọ, o sì ju
wọn si ilẹ aiye, dragoni naa si duro niwaju
obinrin na ti o fẹ bímọ,
pe nigbati o ba bí, ki o le pa ọmọ rẹ̀ jẹ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ wa fiyesi
ẹsẹ ikarun un daradara:
(Ifihan :) O si bí ọmọkunrin kan
ti yio fi ọpá irin
ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ède: a si gbà
ọmọ rẹ̀ lọ soke si ọdọ Ọlọrun, ati si ori itẹ́ rẹ̀.
Oluṣọ-agutan Anderson: O hàn bayii pe ọmọ yii
ni Jesu Kristi nitori pé ninu Majẹ̀mú Laelae
ati Májẹ̀mú Tuntun, Bibeli nsọ nipa
Jesu Kristi ti ó nfi ọpá irin ṣe akoso aye yii
ti ó sì ntọka si ijọba ẹgbẹrun ọdun
ti o mbọ lọjọ iwaju. Nitori naa, nitootọ
ọna ti o dara julọ ti mo fi lè ràn yin lọwọ lati lóye
iwe Ifihan ni pe ki nsọ fun yin lati ké e
sí meji ni ori ikọkanla gan an. Ẹsẹ ikinni si ikọkanla jẹ abala kan
tí ẹsẹ ikejilá sí ikejilelogun sì jẹ́ abala miran. Lẹyin naa, tí
ẹ bá fi abala wọnyi wé ara wọn, ẹ ó rí
awọn iṣẹlẹ kan naa lati oju-ìwò meji ti o yatọ:
Ikinni Ọdun kejila ti inú Ọgọrun un ọdun akọkọ
Ikeji
Ikẹta
Ikẹrin
Ikarun un
Ikẹfa Ipọnju Ikẹtala
Ikeje Igbasoke Ikẹrinla
Ikẹẹdogun
Ikẹjọ Ibinu Ọlọrun Ikẹrindinlogun
Ikẹsan an
Ikẹwaa
Ikọkanla
Babiloni Ikẹtadinlogun
Ikejdinlogun
Amagẹddoni Ikọkandinlogun
Ìtẹ Funfun Ogún
Ọ̀run/Ayé Tuntun Ikọkanlelogun
Ikejilelogun
Oluṣọ-agutan Anderson: Ki lo dé ti Ọlọrun yoo fi ṣe bẹẹ?
Ki lo de ti Ọlọrun yoo fi sọ itàn kan naa nigba meji ninu
iwe Ifihan? O dara, ki lo de ti ó fi sọ itàn Ihinrere fun
wa nigbà mẹrin ninu Mateu,
Maaku, Luuku, ati Johannu? Ki lo de ti ó fun wa ni
iwe Samuẹli Kinni ati Ikeji ati Awọn Ọba Kinni ati Ikeji, ṣugbọn
lẹyin naa ni ó tun fun wa ni Kronika Kinni ati Ikeji
lati fun wa lati igun miran, ìwòye miran, a sì
lè kẹ́kọọ pupọ nipa ṣiṣe afiwe iwe Àwọn Ọba
pẹlu iwe Kronika,
àbi ṣiṣe afiwe iwe Mateu pẹlu Maaku, ati Maaku pẹlu Luuku,
ati Luuku pẹlu Johannu, awọn yii sì nfun wa ni
ìwòye ọtọọtọ. O dara ọna kannaa
tí a fi mòye iwe Ifihan niyi.
Eyi yoo ràn ìmòye yín nípa iwe Ifihan
lọwọ nigba ti ẹ bá lóye bí ó ti tẹ̀lé ara wọn bẹẹ.
Awọn kan wá lérò pé iwe Ifihan kò wà
ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé rara, ṣugbọn àkànlò ede
"lẹyin eyi" abi àkànlò ede "lẹyin nnkan wọnyii"
waye nígbà mẹwaa ninu iwe Ifihan.
Tí a ba nrí "lẹyin eyi" ati "lẹyin nnkan wọnyii"
tí ó nfarahan leralera, eyi jasi pe Ọlọrun nfun wa
ní alakalẹ bi awọn iṣẹlẹ ti tẹle ara wọn.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ó jẹ́ nnkan ti o buni kù
lati gbiyanju lati tumọ Bibeli abi kà Bibeli
lati takò otitọ pé Bibeli nsọ pé "lẹyin eyi," tí awọn
eniyan sì nsọ pe, "Kò si ní
ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ko mọ́gbọ́n wá." Jakejado
Bibeli, bí ẹ ó ti ka iwe mimọ́ niyẹn.
Apẹrẹ kan ti o pani lẹ́rín: ninu Johannu,
ori kẹta, ẹsẹ ikọkanlelogun, o nsọ pé:
(Johannu :) Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá sí imọlẹ,
ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe,
a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Lẹyin naa ni ẹsẹ ikejilelogun nsọ pe,
"Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá
si ilẹ Judea;" yoo si buni kù fun mi
lati duro nihin ki nsì sọ pe, "Bẹẹkọ,
dajudaju, ẹsẹ ikejilelogun waye ṣaaju ẹsẹ ikọkanlelogun,"
nigba tí ẹsẹ ikejilelogun nsọ pe "lẹhin nkan wọnyi."
A ó bojuwo eyi ti a ó sì wipe,
nitootọ, bi a ti kọ ọ́ niyẹn, iyẹn si ni ohun
tí ó tumọ sí. Lẹyin naa ni a de inu iwe ịfihan,
gẹgẹ bi mo sì ti sọ, igba mẹwaa ni ẹ ó ka "lẹhin
nkan wọnyi" tabi "lẹhin eyi," sibẹ awọn eniyan nsọ pe,
"Bẹẹkọ, kò tẹle ara wọn.
Kò mọ́gbọ́n wá." Ó jẹ́ ọna ti ó lòdì
lati ka Bibeli.
Oluṣọ-agutan Anderson: Eyi jasi pe, tí ẹ ba ni ero pe
ó wà ni ṣíṣè-n-tẹ̀lé, ṣugbọn ó tun pada bẹrẹ lẹẹkan sí i
ni ori ikejila, eyi yoo jẹ ki ó ye yin.
Mo fẹ́ là ori iwe meji pere kọja
nihin lati fihàn yin bi awọn iṣẹlẹ igba ikẹyin
ti tẹle ara wọn. Eyi lè waye ni ọgọrun un ọdun sí
akoko yii. Gbogbo wa lè ti papòdà, ṣugbọn mo lero pe ó
ṣeeṣe ki ó ṣẹlẹ
laipẹ ọjọ. Ni tootọ, yoo ṣẹ̀rù ba mi tí ó ba jẹ pe
o kéré tan awọn nnkan yii ko ṣẹlẹ ní
oju ẹmi mi ti ó ba jẹ́ pe mo lò akoko ti ó yẹ kí nlo.
mo jẹ ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn, bi nnkan si ti
nsare ni lọọlọọ yii, yoo jẹ iyalẹnu fun mi
tí eyi ko ba ṣẹlẹ ni ogoji ọdun sihin yii.
Nigba ti mo bá bẹrẹ sí í wọnu iṣẹ́-iranṣẹ ti aṣalẹ yii,
mo lero pé ẹ ó lóye diẹ ninu idi ti
mo fi sọ bẹẹ. Ohun ti o nbẹrẹ ipọnju
naa niyi. Bibeli wi pe Eṣu,
abi Satani, ni a ó lé kuro ni Ọrun.
Ẹ wá nsọ pé, "Duro ná, Oluṣọ-agutan Anderson,
ṣe iyẹn ko ti ṣẹlẹ tẹlẹ?" Ṣugbọn idahun naa ni, Rara o.
Awọn eniyan ro pe Eṣu wa ni Ọrun Apaadi
ni lọwọlọwọ yii, ṣugbọn n itootọ, Eṣu ko ti i dé Ọrun Apaadi rí
nitori pe Bibeli nfi
yé wa pe Eṣu wa lori ilẹ aye yii ti ó nrin
kiri gẹgẹ bi kiniun ti ó nbú ramu-ramu ti ó nwa ẹni ti
yoo pajẹ kiri. Eṣu ati gbogbo awọn ẹmi aimọ́ rẹ̀ wà lori ilẹ
aye yii ninu Bibeli.
Ó nrin soke sodo laarin Aye ati Ọrun,
ó si n bá Ọlọrun sọrọ. Ti ẹ ba ka iwe
Jobu, Eṣu nwá ti ó si nduro niwaju Ọlọrun
ti ó si ni ìtàkurọ̀sọ pẹlu Ọlọrun ní Ọrun
nipa Jobu iranṣẹ rẹ̀. Nitornaa Eṣu
nlọ soke sodo nisisiyi. Ó dara, Bibeli nsọ
nipa ọjọ kan ti a ó lé Eṣu sọkalẹ
lati Ọrun:
(Ifihan :) Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati
awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na
jagun; dragoni si jagun ati awọn angẹli rẹ̀.
(Ifihan :) Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a
kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun.
(Ifihan :) A si lé dragoni nla na jade,
ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu,
ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e
jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀
jade pẹlu rẹ̀.
(Ifihan :) Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun,
nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati
agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti
Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awon
arakunrin wa jade, ti o nfi
wọn sùn niwaju Ọlorun wa lọsàn ati loru.
(Ifihan :) Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori
ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ
ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn
ani titi de iku.
(Ifihan :) Nitorina ẹ mã yọ̀, ẹnyin ọrun, ati
ẹnyin ti ngbé inu wọn. Egbé ni fun
aiye ati fun nitori okun!
nitori Eṣù sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla,
nitori o mọ̀ pe ìgba kukuru sá li on ni.
Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, kini a nrí nihin?
Ogun wà ni Ọrun, Bibeli sì nkọni
pé Eṣu npadanu ogun yii. Ó
npadanu ogun yii ni Ọrun, nitori pe o si padanu
ogun naa, oun ati awọn angẹli rẹ̀,
ti ó nfihan nihin pé ó jẹ́ idamẹta awọn angẹli, a
lé wọn sí aye. Satani gan an ni a
lé kuro ni ọrun yii, oun si mọ̀
akoko kukuru kúkú ni oun ní, oun yoo
si jade lọ lati pọ́n awọn onigbagbọ loju ki ó si pọ́n
awọn eniyan mimọ loju ki ó si gbiyanju lati pa wọn
run. Ẹ wo orí ikẹtala. Nibi yii ni ogun naa ti nbẹrẹ.
Ní Ifihan :, oun yoo jagun.
Bawo ni yoo ti ṣe é? Bawo ni Eṣu yoo ti
bá awọn onigbagbọ jagun?
Ìran : Asòdì-sí-Kristi
Oluṣọ-agutan Anderson: Ohun ti ó kàn ti a ó rí ti yoo
ṣẹlẹ ninu isọtẹlẹ ni ohun ti a npè ni
ipọnju naa. Ipọnju naa ni akoko tí
ọpọlọpọ iṣẹlẹ nṣẹlẹ
lori ilẹ aye yii ti ó buru. Ìyàn yoo
wà. Ajakalẹ arun yoo wà.
Ogun-jija yoo wà - ọpọlọpọ ogun-jija.
Ebi yoo maa pa ọpọlọpọ
eniyan kú, ti aisan yoo si maa pa wọn. Ọpọlọpọ ohun
buburu ni yoo maa ṣẹlẹ. Ó dara, ninu gbogbo
ogun-jija yii ati ajalu ti yoo maa
ṣẹlẹ nigba ipọnju naa, (kì í ṣe ajalu
ti ó ti ọwọ́ Ọlọrun wa, kì í ṣe pé Ọlọrun nrọjo iná ati imí-ọjọ́
ṣugbọn dipò bẹẹ awọn ajalu ti iṣẹda, ogun-jija, ìyàn,
tí awọn eniyan nfà) ẹnikan yoo wà ti yoo yọjú ti
yoo si di apàṣẹ-wàá
ti gbogbo agbaye ti a mọ̀ sí "asòdì-sí-Krist naa."
eyi kì iṣe àlọ́. Nitootọ ni eyi yoo
ṣẹlẹ, nitootọ, a sì lè ti bẹrẹ si i ri
awọn ami pé ó ti bẹrẹ si i ṣẹlẹ.
Bibeli nsọ fun wa pé lọjọ kan, ijọba agbaye
kan yoo wà. Ní lọwọlọwọ a ní
ọpọlọpọ ijọba ti o yatọ.
A ní Amẹrika, a ni Rọsia, a ni Ṣaina - gbogbo
wọn ni o jẹ orilẹ-ede ọtọọtọ, ti ó ni aṣẹ
(boya ẹ ti gbọ́ ọrọ naa "ni aṣẹ") - gbogbo
orilẹ-ede ti o ní aṣẹ yii. Ó dara, lọjọ kan, Bibeli
nsọ pe gbogbo awọn orilẹ-ede yẹn yoo
parapọ lati gbé ijọba agbaye kan kalẹ.
Kete lẹyin ti wọn ba ti gbe ijọba
agbaye yẹn kalẹ, wọn yoo fun ẹnikan ni gbogbo agbara naa
ti yoo jẹ́ olori ijọba yẹn,
ẹni yẹn ni a sì mọ̀ sí "asòdì-sí-Kristi" naa.
Tani ó ti gbọ nipa asòdì-sí-Kristi naa ri?
Gbogbo eniyan ni ó ti gbọ́ ọrọ yii rí. "Asòdì-sí-Kristi"
naa jẹ́ ọrọ inu Bibeli. Lemó-lemọ́ ni ẹ ó maa gbọ́
ti Bibeli nsọrọ nipa "ẹranko naa," abi "ẹranko naa
ti ó wa lati inu okun," tabi "ẹranko naa ti ó ni ori meje
ati ìwo mẹwaa," tabi "ẹni ẹṣẹ" naa, abi
"ọmọ egbe" naa, ṣugbọn Bibeli tún nlo
ọrọ naa "asòdì-sí-Kristi." Mo fẹ́ lati
lo ọrọ naa "asòdì-sí-Kristi: o jẹ́ ọrọ ti o yé awọn eniyan,
ó sì jẹ́ ọrọ inu Bibeli. Mo fẹ́ fihan yin nibi ti
Bibeli ti nmẹnuba ọrọ naa
"asòdì-sí-Kristi" nitori pé Bibeli nsọ fun wa pe
ẹnikan nbọ lọjọ kan ti a pe ni
asòdì-sí-Kristi naa. Kí Jesu Kristi to pada de,
ẹlẹtan kan yoo wà, èké Kristi kan.
Ṣé ẹ ri ohun ti mo nsọ? Asòdì-sí-Kristi naa
jẹ ọkunrin kan tí ó npe ara rẹ̀ ni ipadabọ
Kristi, ṣugbọn oun jẹ ẹlẹtan. Ṣugbọn niwọn igba ti
a ti nkọ awọn Kristiẹni bayii lati maa reti
Jesu lati pada wa nigbakuugba, ó jẹ́ pípé nitori pé
ẹ sọ ẹni ti ẹ ro pe ó nfi ara han gan an -
asòdì-sí-Kristi naa. Ki lo de ti Bibeli npe é ni
"asòdì-sí-Kristi"? Nitori pe ẹnikan mbọ ti a pe ni "asòdì-sí-Kristi"
(ẹyọ kan) ti yoo wi pe oun ni Jesu Kristi.
Nigba ti asòdì-sí-Kristi naa bá nfi ara han ni àkókò ipọnju naa
ti ó sì nwipe, "Emi ni Jesu Kristi," wọn yoo gba a
gẹgẹ bi mesaya wọn. Ọpọlọpọ eniyan yoo
kọni pé, "Ah, nigba ti Jesu Kristi bá mbọ ninu awọsanma,
awọn Juu yoo dá a mọ lẹyin-o-rẹyin pé
oun ni mesaya wọn, wọn yoo si gbà á."
Bẹẹkọ, wọn yoo gba asòdì-sí-Kristi naa!
Ohun ti Bibeli nsọ niyẹn. Jesu sọ pé:
(Johannu :) Emi wá li orukọ Baba mi, ẹyin kò si gbà mi:
bi ẹlomiran ba wá
li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà.
Oluṣọ-agutan Anderson: Mo lero pé ète Satani pẹlu
igbasoke ti ó siwaju ipọnju naa ni lati jẹ ki gbogbo eniyan
ni ero yii pé "Jesu Kristi nbọ nigbakuugba." A nreti
Jesu Kristi nigbakuugba! Ó lè dé lonii!
Ó nbọ lonii!" ṣugbọn ni tootọ
ẹni ti o nbọ naa ni asòdì-sí-Kristi naa.
Asòdì-sí-Kristi yii, nigba ti oun ba de, yoo jẹ
olori ijọba ayé-dọ̀kan ati ẹsìn ayé-dọ̀kan nibi ti ó ti npe ara
rẹ̀ ni mesaya naa.
Ó nsọ ninu ẹsẹ ikejidinlogun ti ori keji
iwe Johannu Kinni:
(I Johannu :) Ẹnyin ọmọ ni, igba ikẹhin li eyi:
bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Asodisi-Kristi
mbọ̀wá, ani nisisiyi Asodisi-Kristi pupọ̀
ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣe igba ti a kọkọ mẹnuba á yẹn jẹ́ ẹẹkan
kan tabi ni amimoye igba? Nitori naa wọn ti gbọ pe asòdì-sí-Kristi
(ẹyọ kan) yoo wá. Nitori naa, asòdì-sí-Kristi ẹyọ kan
ni o mbọ̀, abi bẹẹkọ? Ṣugbọn ṣe ko si ọpọlọpọ
asòdì-sí-Kristi nisisiyi gan an? Ohun ti ẹsẹ
naa nsọ niyẹn. Awọn wo ni asòdì-sí-Kristi yii?
( Johannu :) Tani èké, bikose ẹniti o ba sẹ́
pe Jesu kì iṣe Kristi? Eleyi ni Asodisi-Kristi,
ẹniti o ba sẹ́ Baba ati Ọmọ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Lati gbagbọ pe
Jesu kì í ṣe Kristi naa, ẹ ni lati gbagbọ
pé Kristi kan wà tí kì í ṣe Jesu. Ọrọ naa "Kristi"
tumọ si "Mesaya."
Bibeli nsọ ninu iwe Johanu, ori ikinni, ẹsẹ ikọkanlelogoji pé,
"Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyiti ijẹ,
Kristi." Nitori naa, Bibeli ntumọ ọrọ naa
"Kristi" sí "Mesaya. A lè fi mejeeji paarọ ara wọn.
Nitori naa, ẹ jẹ ki nbeere eyi lọwọ yin:
njẹ e le ronu nipa ẹsìn kan nibẹ̀ yẹn ti ó nsọ pe
mesaya kan wà ti ó nbọ, ṣugbọn kì í ṣe Jesu
- Jesu kọ́ ni ẹni naa. Ẹsìn Juu nkọni
pé mesaya kan wà, ó dara,
ṣugbọn kì íṣe Jesu ni. Wọn ṣì nreti
mesaya naa. wọn nsọ pé Jesu
kọ́ ni mesaya naa, tí ó sì jẹ́ pé wọn ṣì nreti
mesaya naa. Bibeli nsọ pe wọn yoo gba asòdì-sí-Kristi
gẹgẹ bi mesaya wọn.
Kristiẹni ajiyinrere ti ó gbagbọ
pé Jesu lè dé nigbakigba, awọn ti a kò
gbala, awọn ti kò gba otitọ gbọ,
ọpọlọpọ wọn ni a ó tanjẹ tí wọn yoo sì rò pé "Eyi
ni ipadabọ Jesu Krist lẹẹkeji!
Lonii, awọn musulumi nreti ànábì nla kan
ati mesaya nla kan lati wá
ti ó pọ̀ ju Mohammadu lọ. Aarẹ Ahmadinejad,
Aarẹ ilẹ Ìráànì - tani ó ti gbọ́ nipa rẹ̀ rí? Aarẹ Ahmadinejad sọrọ
ninu Àjọ Àpapọ̀ awọn Orilẹ-ede ní ọdun kan tabi meji sẹyin,
nigba ti ó si ṣe bẹẹ, ó funni ni
alayé ranpẹ́ nipa ẹsìn Islamu.
Mahmoud Ahmadinejad: "Koko iṣẹ́-riran àwọn woolii jẹ́
ọ̀kan ṣoṣo ati ọ̀kan naa. Iranṣẹ kọọkan
ti gbóriyìn fun iranṣẹ ti ó ṣaaju rẹ̀ ti
ó si ti funni ni iroyin ayọ nipa iranṣẹ ti ó kàn
lati wá tí ṣe agbekalẹ ẹ̀dà ẹsìn naa ti ó
jinlẹ̀ si i gẹgẹ bi okun eniyan
ni akoko yẹn. Ilana yii tẹ siwaju
titi ti iranṣẹ Ọlọrun ti o kẹyin ti o ṣe agbekalẹ pípé
ẹsìn kan ti o ṣe àkópọ̀. Nimrọdu tako iwalaaye Abrahamu.
Farao tako iwalaaye Mose,
olojukokoro si tako iwalaaye Jesu Krist ati
iwalaaye Mohammadu - ìkẹ́ ati ọlà ki ó maa bá gbogbo
awọn ànábì wa."
Oluṣọ-agutan Anderson: O sì wipe
Islamu gbagbọ pe Abrahamu jẹ ànábì nla. Mose jẹ
ànábì nla, nigba naa ni Jesu si wà. nigba
naa ni Mohammadu si wà - tí Musulumi naa
si nmì ori rẹ̀ ki nlè maa gbọ́ ọ ni agbọye!
Ohun ti Ahmadinejad sì kuku sọ
ni pé ọkọọkan ninu awọn gbé otitọ tí ó
pọ̀ ju ti ẹni ti ó ṣaaju rẹ̀ lọ bí eniyan ti ṣetan
fun un. Wọn tubọ tàn imọlẹ ati afikun alaye
ati afikun otitọ. Ó sọ pé ní
ọjọ iwaju ànábì miran yoo wá ti yoo tilẹ
ju Mohammadu lọ ti yoo sì
gbé ipele imọlẹ ti o kàn wá. nitori naa Islamu
nreti ki eniyan kan bi i mesaya wa.
Wọn nreti Lemọmu Mahdi.
Mahmoud Ahmadinejad: Ọlọrun o, jẹ ki dídé
Lemọmu yá kánkán ki o sì fun un ni alaafia pipe
ati iṣẹgun, ki o sì ṣe wá ní sàábé rẹ̀, ati awọn ti yoo jẹrii si otitọ rẹ̀.
Oluṣọ-agutan Anderson: Awọn ẹlẹ́sin
Buddha nreti ki Buddha Karun un dé. Awọn ti ó wa
ni ilẹ̀ Tibeti ti wọn ntẹle Dalai Lama: wọ́n gbagbọ pe
Dalai Lama naa npada wá silé aye ni gbogbo igba
gẹgẹ bi elomiran - ẹmi inu Dalai
Lama yẹn. Wọn yoo gbagbọ pé asòdì-sí-Kristi
ni ifarahan Dalai Lama tuntun. Awọn
Musulumi yoo kà á sí Lemọmu Mahdi.
Awọn Kristiẹni yoo kà á sí ipadabọ Kristi
lẹẹkeji. Awọn Juu yoo kà á sí
mesaya naa. Gbogbo awọn ẹsìn pataki yii
yoo fara mọ́ ọ, awọn eniyan yoo si wipe,
Ṣé eyi ko wuyì bi a ti nparapọ lẹyin-o-rẹyin!
A ngbe gbogbo aidọgba wa tì sí apa kan,
ọkunrin yii si buyaari tó bẹẹ!" wọn yoo si
sìn ọkunrin yii. Ẹlẹtan yii, asòdì-sí-Kristi yii,
tí ó nbọwá. Ijọba agbaye yoo fi í sipò wọn
yoo sì fun un ni gbogbo agbara,
wọn yoo si kede rẹ̀ gẹgẹ bi Ọlọrun. Wọn yoo kede
rẹ̀ gẹgẹ bi ipadabọ
Kristi lẹẹkeji. Wọn yoo pa a. Bibeli wi pe
oun yoo gba ọgbẹ́ aṣápa
ní ori rẹ̀, a ó wò ọgbẹ́ aṣápa rẹ̀ sàn,
ara rẹ̀ yoo dá. nigba naa ni a ó
kede rẹ̀ gẹgẹ bí ipadabọ Jesu Kristi lẹẹkeji. A ó kede rẹ̀
gẹgẹ bi Ọlọrun ninu eniyan, gbogbo orilẹ-ede
agbaye, ati gbogbo eniyan agbaye yoo sì
sìn ọkunrin yii. Gbogbo ẹsìn ni yoo gbà á gẹgẹ
bi mesaya wọn, ṣugbọn
Bibli sọ pé a kò ní tan awọn ti a gbala jẹ.
Iyooku gbogbo agbaye
yoo sìn in ti wọn yoo sì gbà á gbọ́ nitori pé
oun yoo ṣe awọn iṣẹ iyanu, ni Bibeli wi,
oun yoo sì ṣe gbogbo iṣẹ́ amì yii, yoo si gbà
ijọba agbaye mọ́ra nigba miran ẹ ó gbiyanju lati
kilọ fun awọn eniyan nipa ijọba agbaye-dọkan.
Ẹ ó gbiyanju lati kilọ fun wọn nipa awọn iṣẹlẹ
kan ti a nri tí ó nṣẹlẹ nipa ti rírà ọja lailo owó
ni awujọ. Ọpọlọpọ Kristiẹni ni ó wà ti ó jẹ́ pé
- ẹ bá awọn Kristiẹni sọrọ nipa agbaye kan ṣoṣo
abi ki ẹ ba wọn sọrọ nipa awujọ rírà ọja lailo
owó ati gbogbo awọn oniruuru ojúkò ayẹwo wọnyi
ti a ngbé kalẹ ati bi ijọba ti di ti ọlọpaa, wọn yoo
si sọ yin lorukọ gẹgẹ bi "elérò ọ̀tẹ̀."
Ó dá mi loju pé a ó ti pè yin ní elérò ọ̀tẹ̀ fun ọpọlọpọ ọdun.
Ọmọwé. Kent Hovind: Bẹẹni, ni ọpọlọpọ igba.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣugbọn ṣe eniyan lè jẹ́ Kristiẹni
ti ó gba Bibeli gbọ nitootọ ki ó sì sẹ́ pé
ijọba agbaye kan ṣoṣo yoo dé lọjọ kan?
Ọmọwé Kent Hovind: Mi ò lero pe ẹ lè ka Bibeli lairi otitọ naa pe ó
ti jẹ́ ète Satani ni gbogbo igba ṣe akoso agbaye
gẹgẹ bi ti eré ori itage kan, ó sì nfẹ́
ijọba agbaye kan ṣoṣo. Ó fẹ́ di Ọlọrun.
Abala - Ami Ẹranko naa
Oluṣọ-agutan Anderson: Nigba ti ọkunrin yii bá
nṣakoso gbogbo agbaye, oun yoo paṣẹ pe ki gbogbo eniyan
gbà ohun ti a pè ní "ami Ẹranko naa."
tani ó ti gbọ́ nipa ami ẹranko naa ri?
Bibeli wipe ami ẹranko naa yoo jẹ́ nnkan kan
ni ọwọ́ ọtun yin abi ni
iwaju ori yin, kò sì sí ẹni ti yoo lè rà tabi tà laini ami yii.
Awọn lè wá ti kà nipa eyi fun ọgọrun ọdun diẹ sẹyin
ki wọn si wipe, "Bawo ni ẹ ó ṣe lè ṣe iyẹn? Bawo ni
ẹ ó ṣe lè maṣe jẹ́ ki awọn eniyan rà tabi
tà laini ami yii? Ẹ ò tilẹ̀ ṣe
kó owó jade?" Ẹ wò bí imọ-ẹrọ ti ri. Owó
yii ti mo kó lọ́wọ́
owó ti ilé ifowopamọ ijọba apapọ tẹ̀, jẹ́ beba
lasan. Kò niye lori. Ko ni
adiyele ninu. Nigba ti ẹ ba ri awujọ ti a ti nraja
lailo owó tí ó ntẹsiwaju - nṣe ni a tubọ nsare lọ
kuro ninu lilo owo…
Ọkunrin ori ẹro amohun-maworan: Igba kan
yoo wa ti owo ti a nna yii ko ni si mọ́.
Olootu Iroyin: Nitori naa owó oni-beba ti di ohun itan o ti lọ?
Ọkunrin ori ẹro amohun-maworan: Ìdá marun-din-lọgọrun
ninu ọgọrun kara-kata ni Amẹrika abi ju bẹẹ lo ni kò ni nnkan íṣe mọ́
pẹlu owó oni-beba abi owó ẹyọ.
Obinrin Oniroyin: Njẹ́ ẹ ti dà á rò rí boya ni
ọjọ kan ojulowo owó kò kàn ní í sí mọ́?
Ó jẹ́ otitọ ti awọn kan sọ pé a gbọdọ fi ara mọ́.
Owó oní-beba ati owó ẹyọ ti di ohun idiwọ kan.
Alaṣẹ ilẹ eniyan dudu: Ilana naa ni pé a ni
lati gbe ọrọ̀-ajé yii lati eyi ti o nlo owó
sí ti kii lo owó. Eyi kàn awọn ilé ifowopamọ.
Eyi kan awọn ile-iṣẹ ẹrọ ibanisọrọ.
Ó kàn awọn ti o npese awọn ẹrọ ti ó npọ̀ owo
ati awọn ojuko kara-kata. O kan ayipada àṣà
Olootu Iroyin: Kinni ẹ npè ni owó gan an lode
oní? Ṣé ẹkunwọ́ owó ẹyọ ati beba ni?
Abi awọn kaadi ti gbòde. Ti irú owó tí a mọ̀ si ti nkogbá silé,
Bí iwe sọwé-dowo?
Ọmọwé Kent Hovind: Ẹ jẹ́ ki a gba pé gbogbo
ile itaje ilú yin sọ pe, "Ẹ gbọ́, a kò gba owó mọ́,"
ki a si gba pe wọn wipe, "A kò ni gba iwe
sọ̀wé-dowó mọ́ abi kaadi ìsanwó nitori pé
gbájúẹ̀ ti pọju - ọpọlọpọ kaadi isanwó ni wọn ti
jí lọ tí ọpọlọpọ iwe sọ̀wé-dowó kò sì dowó. Ó
gbọdọ jẹ́ kara-kata ti ẹrọ."
Oluṣọ-agutan Anderson: Let's face it: the paper
money is not really worth anything anyway.
Ẹyọ beba kan ni. Ó tun lè jẹ́ owó
Gbogbo-niṣe. Kiiṣe goolu. Kiiṣe
fadaka. Kò ni iye kankan lori. Nitori naa,
wọn kọkọ jẹ́ kí ó mọ́ wa lara lati lò
awọn ẹyo beba ti kò wulo. Lonii mo lè ṣe
paṣi-paarọ ẹyọ beba kan fun awọn ọja,
ṣugbọn ti ẹnikan ba sọ lọla pé, "Owó yẹn kò ni
iye kankan lori," nigba naa ni o jẹ́ pe
kò ní ní iye kankan lori. Njẹ́ ẹ ranti awọn Ipinlẹ
Alajọṣepọ ti Ilẹ Amẹrika? Njẹ́ ẹ ranti owó ilẹ alajọṣepọ?
Awọn eniyan kó owó ilẹ alajọṣepọ pamọ sinu
timu-timu. Ki lẹ ro, kò niye lori
rara. Ó dara wọn lè ṣe iyẹn si ẹ̀yin naa,
kí wọn si wipé, Ó dara, owó oni-beba yin
kò dara. Gbogbo rẹ̀ sá wà ninu àṣùwọ̀n yin. A so
gbogbo rẹ̀ pọ̀ mọ́ àṣùwọn Facebook ati ìkànnì Youtube
ati gmail yin, ó si wuyi pupọ nitori kò sí pé a
nṣerú sí ami idanimọ. Ẹ kò ní í
ki ẹ maa daamu nipa gbigbagbe ọ̀pọ́ọ̀ yin sile.
Kò nilo pé ẹ ndaamu nipa gbigbagben kaadi
jiji kaadi yin lọ. Gbogbo rẹ̀ ni kò sá nilò owó r
ara." A lè dari oogun nitori pé
kò nilò pé kò ní sí ọna lati ṣeto kara-kata ti ó la
owó lọ. Ó wà fun didena iwà ọdaran.
Obinrin Oniroyin: O jẹ́ imọ̀-ẹrọ igbalode ti ó fe gbode lorukọ
ere-sisa ati itura. Ẹ ó lè ra ohunkohun lati burẹdi si ọtí tí ẹ bá fẹ́
lati fun ile-itaja naa ni ami idanimọ yin ti o ga julọ.
Ọkunrin lati ẹgbẹ ẹtọ́ ọmọniyan: Ó maa nkọmi lóminú.
Obinrin Oniroyin: Ni kete ti a ba ti ṣe ayẹwo
awọn eso yin, kini ẹ ó wá ṣe? Ẹ ó nà ika yin aarin
sí ẹrọ ti ó njuwe awora, ẹ si ti sanwó niyẹn ni
iṣẹju aaya mẹta pẹlu ifọwọkan
orí ìka. A npè é ni ijuwe: ọna ti imọ-ẹrọ ti a fi nda
yin mọ̀ eyi ti ó dá lori idayatọ yin
nipa àjẹbí.
Ọkunrin lati ẹgbẹ ẹtọ́ ọmọniyan: Ẹ maṣe jẹ́ ki
eyi mú yin mọlẹ nitori itura kan.
Oṣiṣẹ́ QT nigba kan: Ẹ mọ pe, oni ìka titẹ̀ ni, ọla ki a fi nnkan há ara. boya iyẹn
ni ó nlana fun ami ẹranko naa.
Obinrin Oniroyin: Ọkunrin yii fi iṣẹ rẹ̀ silẹ ni ipo ọga ni Quik Trip nigba ti ile-itaja naa
sọ fun u pe ó gbọdọ fi ìka rẹ̀ kàn agogo kí ó tó wọṣé ati kí ó tó lọ silé.
Oṣiṣẹ́ QT nigba kan: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má pọn dandan lonii, ta ló mọ ilẹ̀ ti yoo mọ́ lọ́la.
Obinrin Oniroyin: Awọn onimọ̀ sọ pé ijuwe ti fẹ́ borí gbogbo ẹka ọrọ aje wa
ati igbe-aye wa.
Obinrin Oniroyin: O fi ìka rẹ sinu rẹ̀, orukọ mi sì jade, ó si ti ri gbogbo
ifitonileti mi.
Obinrin Oniroyin: Ó sí̀ yá tó bẹyẹn?
Obinrin ori ẹrọ amohun-maworan: Ó yá jọjọ.
Obinrin Oniroyin: Abi ẹ fẹran rẹ̀?
Obinrin ori ẹrọ amohun-maworan: Mo nifẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Obinrin Oniriyin: Awọn ni gbogbo agbaye nlo ti
nlo ijuwe tẹlẹ. Ijọba Amẹrika, awọn ilé-iṣẹ ọkọ ofurufu
,
awọn ilé-epo - Walt Disney paapaa nlo imọ̀-ẹrọ
tí ó lè rí iṣan-ara awọn onibàára
afi ẹni ti ó bá mú iwe irinna ojoojumọ́ dani.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ijọba agbaye kan
ṣoṣo yii yoo lagbara to bẹẹ ti ó fi jẹ́ pé yoo lè
paṣẹ pé kò sí ẹnikan lori ilẹ̀ aye yii ti yoo lè rà tabi tà laini
ami ẹranko naa. O wá dun mọni pé Bibeli Ẹ̀dà
ti Ọba Jakọbu sọ ọ́ yekeyeke pé
ami ẹranko naa - ami yii tí a ó beere lọwọ yin
lati rà ati lati tà - yoo
wà NÍ ọwọ ọtun wọn abi NÍ iwaju ori wọn. Eyi lè
jẹ́ irú nnkan kan ti a lè fi hà inu ara
tí ó jẹ́ pé lati rà abi tà, ẹ ó kàn ní lati yẹ̀
ìfihára yii wò. Ohun tí yoo
ṣẹlẹ ní ọjọ́ kan ni pé wọn yoo sọ pe, "Owó oní-beba yii -
Ogọ́run dọla yẹn ninu
apò yin - kò niyelori. Ẹ ni lati ṣe ayẹwo kí ẹ tó
sanwo. Ti ẹrọ ni bayii. Ẹ ó lọ sí
ṣọọbu eléso, ẹ ó tẹ̀ eléso laago, kí ẹ sì *sàpẹ*
lasan. Tí ẹ kò ba ní
ọwọ́, kò séwu, a lè fi sori yin nitori pé gbogbo
eniyan ni ó ni ori! Ẹ ó kàn
*sàpẹ* kí ẹ jade nibi ijade. gbogbo owó naa
yoo kan jẹ́ ti ẹlẹ́rọ,
ó si ti nṣẹlẹ̀ bẹyẹn. Awọn ẹrọ alágbèéká ti bẹrẹ
si í ni ohun iṣayẹwo. Nitori naa, ẹ jẹ́ ki a sọ
pé paṣipaarọ awọn ọja laarin eniyan meji. Ó dara,
iyẹn yoo jẹ́ dọla mẹwaa ati abọ̀.
Ẹ tẹ siwaju kí ẹ si fun mi ni ọwọ ọtun yin ki nle fi
ẹrọ ibanisọrọ igbalode mi yẹ̀ ẹ́ wo. *sàpẹ*
Ó dara, nisisiyi mo ṣẹṣẹ gbowo ninu aṣùwọn mi.
Ah, ẹ ṣẹṣẹ kọ ọmọ mi ọkunrin ni duuru titẹ. Ẹ jẹ́ kí
n sanwó fun yin. *sàpẹ* Ẹ ronu nipa rẹ̀ nisisiyi: a lè
lo ẹrọ ibanisọrọ naa lati ṣe ayẹwo ami
ẹranko naa, ẹ kò sì lè rà abi tà laisi i.
Obinrin Oniroyin: Ninu iroyin ìṣègùn ni aṣalẹ yii,
ìfihára bíi woro raisi lè gbà
ẹmi yin la.
Olootu Iroyin: Ọdun naa jẹ́ . Wọn gbé yin
digba-digba lọ si ilé iwosan laimọ̀ ibi tí ẹ wà laisí kaadi idanimọ̀ abí
itan nipa ilera yin, ṣugbọn a dupẹ lọwọ ìfihára kekere
kan labẹ awọ yin, gbogbo rẹ̀ wà nibẹ̀. Itàn arosọ sayẹnsi
ogun ọdun sẹyin, ṣugbọn ó di otitọ ti ijúwe lonii.
Ọjọgbọn: Mo ro pe ó ṣeeṣe lati tú wa silẹ̀ patapata
kuro ninu awọn ọ̀pọ́ọ̀ ati kọkọrọ nipa
imọ̀-ẹ̀rọ ti ijuwe tí ó bá jẹ́ pé ohun tí awọn eniyan
nfẹ́ niyẹn ni ọdun mẹwaa sihin.
Olootu Iroyin: Ipenija naa ni lati daabo bò aṣiri wa
ninu aye ọdaju igbalode yii.
Olootu Iroyin: Imọ-ẹrọ tuntun ti ìfihára kekere ti wá
njẹ́ kí ó ṣeesẹ fun awọn oṣiṣẹ pajawiri
lati wadii nipa itan ilere yin nipa fifi ọwọ tẹ̀ ẹrọ a-yara-bi-aṣa.
Oniṣegun lati Harvard: Ọpọlọpọ oniṣegun pajawiri ni
ó ti ní lati ṣiṣẹ́ abẹ lailaju. A gbọdọ gbé igbesẹ lori eto iṣegun
laimọ irú oogun tí ẹ nlò abi ohun ti kò bá yin lara mu.
Olootu Iroyin: Oniṣegun lati Harvard nsọ pé ìfihára
Idanimọ ti ó mbá ẹrọ a-sọrọ-ma-gbesi ṣiṣẹ yii lè yanju
iṣoro yẹn. O ti fi í sinu apa rẹ̀ ọtun. Ẹrọ ayẹwo
kan yoo wò nọmba
idanimọ kan. Awọn wóró nọmba mẹrindinlogun yẹn
ni a ó tẹ̀ sí oju òpó kan ti aabo wa lori rẹ̀ nibi ti itan iṣegun rẹ̀
ti wà ni ipamọ. Oṣiṣẹ EMT nsọ pé ìfihára naa lè
ràn awọn oṣiṣẹ pajawiri lọwọ.
Oṣiṣẹ EMT: Ọkan lara awọn nnkan pataki ni igba
tí ẹ bá ni alaisan yoowu ti ó bá ní aisan ìjayà nibi tí
wọn yoo ti wá, tí wọn kò si ní lè ṣalaye nipa
ara wọn abi itan iṣegun
wọn.
Olootu Iroyin: Oniṣegun lati Harvard nsọ pé
awọn anfaani rẹ̀ yè kooro.
Oniṣegun lati Harvard: Mo maa ngun oke, mo si
gbagbọ pé ti mo ba jabọ lẹ́sẹ̀ oke, tí ẹ sì
ri mi ti ni ò mọ ibi ti mo wa, itura pé ẹ lè ṣe ayẹwo
mi kí ẹ sì fi inu ro ẹni ti mo jẹ́ rekọja
ijaya mi fun aṣiri mi.
Olootu Iroyin: A fi ìfihára naa sinu ike tí ó sì tobi tó wóró
irẹsi. A ó ṣe eto naa pẹlu ikùnlóorun tí ó sì
jẹ́ pé kò sí títa ríro.
Oniṣegun lati Harvard: Nṣe ni ó dabí fífi abẹrẹ
iranṣọ gunni.
Olootu Iroyin: Ṣugbọn ní ti eyi, ó nsọ pé fífi
nnkan pamọ sara ẹni jẹ́ nnkan
tí ó dara.
Olootu Iroyin Ọkunrin: Bí ó ti nbẹrẹ niyi: ologbo
yii niyi, lẹyin ọdun marun, a si rí i
pé ó pada dé. Ẹnikan wá sọ pé, “Ẹ mọ pé ó
dara tó fun ologbo, mo ti ní
iyá ati baba nilé tí ó sì dabi ẹni pé baba maa
nrin kiri nigba miran tí a sì lè fi ìfihára kekere
ti itan iṣegun rẹ̀ wà nibẹ tí nnkan ba ṣeeṣi ṣẹlẹ.
Ó wù etí gbọ́" nigba naa ni ẹnikan
wipe, “Ó dara, tí ó bá dara to fun ologbo mi, ó
dara to bakan naa fun iyá agba ati baba agba,
ọmọ mi jòjòló nkọ́?" Kò sí ìtani-lólobó awọn
ajọmọgbé mọ́. Kò sí ifoya mọ́ nipa
ọmọ ti a jí gbé. Nigba naa ni a ó sọ pé, "Ó dara,
ṣẹ́ ẹ dá nnkan mọ̀? Boya ó ƴe kí A ní wọn.
Lára ìfihára yẹn, a ó sì ní ohun gbogbo. Kaadi
isanwó, iwé àṣe ìwakọ̀. Ẹ ronu nipa
rẹ̀. Awọn kaadi isanwó ọkọ̀. Kò sí ọ̀pọ́ọ̀ mọ́. Ẹ
ronu nipa eyi, ẹ kò ní kó kọkọrọ kaakiri mọ. Nitori naa
ibeere tí mo fẹ́ kí gbogbo eniyan ninu ile beere
ni pé: Ṣé ero rere niyẹn? Nitori ibẹ̀ yẹn
ni ó kàn tí a nlọ.
Olootu Iroyin Obinrin: O ti fi ara pẹ́ itan jù fun mi, mo nsọ iyẹn fun yin.
Olootu Iroyin Ọkunrin: Nihin ló wà! Nihin ló wà.
Olootu Iroyin Obinrin: Mo mọ̀ pé ihin ló wà tí ó sì wà pẹlu
ẹran ọsìn ní ọna tí ó sì ní gbèdéke ṣugbọn fun awọn eniyan…
Olootu Iroyin Ọkunrin: Ṣugbọn ọmọde ni yin…
Olootu Iroyin Obinrin: Ọmọde ni yin…mo ní kí ẹ sojí...
Steven Anderson: Awọn eniyan ni atijọ ti lè
dà á rò pé, “Bawo ni a ó ṣe ṣe eyi?
Bawo ni ẹ ó ṣe dí awọn eniyan lọwọ ninu tita ati
rira ti wọn kò bá ni ami?”Ṣugbọn a nrí But we see
imọ-ẹrọ tuntun bayii tí ó njẹ jade tí yoo jẹ́ kí ó
rọrun jọjọ lati maṣe jẹ́ kí ẹnikẹni rà
abi tà laini ami yii. Ẹ si fi inu rò nnkan? Awọn
eniyan tí ó pọju ni ó ní onjẹ tí ó tó fun ọjọ meje péré
ninu ile wọn abi onjẹ ọjọ mẹwaa ninu ile wọn,
nitori naatí ẹ kò bá lè rà abi tà
ẹ ó wà ninu aye inira. Bibeli sì nsọ ṣaaju pé ofin
kan yoo wà tí ó nsọ pé bí ẹ kì yoo bá sìn
asòdì-sí-Kristi naa a ó pa yin. Ọkunrin yii
pọ̀ jọjọ, ó nṣe ọpọlọpọ ohun nla, ó nkó awọn
eniyan jọ. Ẹyọ
akopọ̀ kan: Ẹ dara pọ̀ abi kí a pa yin. Tí ẹ bá sì
gbọ́ nipa iyẹn, nigba tí ẹ bá wò
iyẹn, boya ẹ ó sọ pé, Ó dara nigba yẹn, mo lérò pé gbogbo wa
tí a jẹ́ onigbagbọ ni a ó kú, awọn tí ó gba Kristi gbọ.
mo lero pé a ó bẹ́ ori gbogbo wa. Tí
Bibeli sì nsọrọ nipa ori bibẹ. Nṣe ni a ó bẹ́ ori
gbogbo wa. Ṣugbọn nihin ni
nnkan naa wa. Ti ́ a bá fi aaye gba eyi lati tẹ̀ siwaju,
ẹ tọ́nà, gbogbo onigbagbọ ni a ó pa. Nitori pé
ẹ rò ó wò, ẹ wo imọ-ẹrọ, ẹ wò awọn ẹrọ iyaworan
tí ó nṣọni tí ó nyọju
nibi gbogbo, awọn ẹrọ oju ofurufu. Awọn ọlọpaa ti wa
nlò ọkọ ofurufu ti eniyan kii tukọ rẹ tí ó ní ẹrọ ayaworan lati kaakiri
ati lati ṣọ́ yin. Njẹ́ ẹ ti ri iyẹn? Awọn ọkọ ofurufu
ti eniyan kii tukọ rẹ̀ tí a fi nṣọ́ni. Wọn ti wá ngbé ẹrọ gbohun-gbohun kalẹ̀
sí awọn igun igboro nibi tí wọ́n ti lè tẹti sí
ohun tí ẹ nsọ. Ó sì dabi
iwe akagbadun nì “.” Bí orilẹ-ede wa
ti nlọ niyẹn, sibi tí yoo ti dà
awujọ aṣóni patapata. Nṣe ni ẹ kàn dede
nwọnu ọkọ ofurufu tẹlẹ. Bayii a ní lati
ṣe yín ní iwọsi lati ọdọ ajọ alaabo irinna. Bayii ẹ
nilati kọja nibi ẹrọ aṣayẹwo ara. Bayii ẹ ní lati
ṣe ayẹwo. A ni lati wá gbogbo ara yin. Ẹ gbọdọ
ní iwe idanimọ pẹlu yin ní
gbogbo igba tí awọn ọlọpaa sì nbeere ni gbogbo igba pé,
“Iwe idanimọ yin nkọ? awọn iwe yin dà? Awọn iwe yin
kò pé!” Iyẹn sì ni orilẹ-ede tí a ngbe ninu rẹ̀ ní
lọ́ọ́lọ́ọ́. Nitori naa eyi yoo si
tẹ̀ siwaju debi pé yoo ti nira gan an lati bọ́ ninu ẹwọn
aye yii. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí nsọ eyi: Kì íṣe gbogbo wa
ni a ó pa. Ọpọ;ọpọ ni a ó pa, ẹ maṣe
ṣì mi gbọ́. Ọpọlọpọ Kristiani ni a ó bẹ́ lori
nitori Kristi. Ṣugbọn ng ó
sọ eyi: A kò ní pa gbogbo wa nitori pé a ó
ké eyi kuru. Bibeli sì nwipe:
(Matteu :) Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni
kuru, kò si ẹda ti iba le la a;
ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru.
Oluṣọ-agutan Anderson: Bibeli sì nwi pe
laarin eyi, Jesu Kristi yoo pada dé.
Ẹ ranti pé a sọrọ ṣaaju nipa ipadabọ Kristi
lẹẹkeji. yoo pada wá. ní akoko gan an
tí wọ́n bá ró pé wọ́n ti bori ẹsìn Kritstiani,
wọ́n ti gbà ijọba agbaye wọn, wọ́n ti
gbà ijọba agbaye wọn kan ṣoṣo pẹlu Satani
gẹgẹ bi olori rẹ̀, jesu Kristi mbọ̀wá ninu awọsanma
iyẹn sì ni igba ti igbasoke bá nwaye tí ó sì
jẹ́ igba tí ó nbẹrẹ sí í rọjò
ibinu rẹ̀ sori aye yii. Ẹ sì lè nipa rẹ̀ ninu
Ifihan. Yoo maa yí
omi pada sí ẹjẹ̀. Yoo maa jó awọn igi ati koriko
run. Yoo maa rán
awọn esú yii wá lati ọrun apaadi ti wọn yoo maa
fi ìrù wọn ṣán eniyan bii ti akeekee.
Tí ẹ kò bá ti kà iwe Ifihan, mo rọ̀ yin gidigidi. Ẹ má sì ṣe kà
Ẹ̀dà ti Agbaye Tuntun. Ẹ kà Ẹ̀dà ti Ọba Dafidi, ṣé
ẹ gbọ́? Tí ẹ ó bá wá akoko lati kà
á, kí ló dé tí ẹ kò kà ojulowo? Ẹ maṣe gba idiwọ.
Ẹ wò ori ikẹtala, ẹsẹ ikinni:
(Ifihan :) Mo si duro lori iyanrìn okun, mo
si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá
o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori
awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ̀
na ni orukọ ọrọ-odi.
(Ifihan :) Ẹranko [Asòdì-sí-Kristi]
ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀
si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na [Satani]
si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla.
Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, ẹranko yii
tí a juwe, Bibeli nsọ pé dragoni naa ni ẹni tí ó fun
u li agbara tí ó sì fun u ni itẹ́ rẹ̀ tí ó sì fun u
ní aṣẹ. Ẹ wò ẹsẹ ikẹta:
(Ifihan :) Mo si ri ọkan ninu awọn ori rẹ̀ bi
ẹnipe a sá a pa, a si ti
wo ọgbẹ aṣapa rẹ̀ na san, gbogbo aiye si fi
iyanu tẹle ẹranko na. Nwọn si foribalẹ fun dragoni na
nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si
foribalẹ fun ẹranko na, wipe, tali o dabi
ẹranko yi? tali o sile ba a jagun? A si nfun u li ẹnu
mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u
lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu
mejilelogoji.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣé oṣu mejilelogoji wá
ntọka sí akoko ati awọn akoko ati ilaji
akoko ati ẹgbaafa ọjọ́ ati mẹfa? Ẹ wò bi awọn nnkan
yii ṣe wọnu ara wọn? Ó nsọ ní ẹsẹ
ikẹfa:
(Ifihan :) O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun,
lati sọ ọrọ-odi si
orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ kiyesi eyi. Ẹsẹ ikeje.
Nihin ni kọkọrọ naa wà:
(Ifihan :) A si fi fun u lati mã ba awọn enia
mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun
Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣé a kò ti wá rí i ninu ori
ikejila ẹsẹ ikeje pé ète dragoni naa ni lati
wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia,
ati ède, ati orilẹ.
bá awọn tí ó gbà Kristi gbọ́ tí wọ́n sì npa ofin
Ọlọrun mọ́ jagun? Nihin ó
nsọ pé a fun u lati bá awọn eniyan mimọ jagun -
Ẹ kiyesi eyi - lati ṣẹgun
wọn. tani yoo borí ninu ogun yii laaarin awọn
eniyan mimọ ati eṣu lori ilẹ̀ aye yii?
Eṣu ni. Ó sọ pé oun yoo bá awọn eniyan mimọ
jagun ti yoo si bori wọn. Gẹgẹ bi
Iwe Ifihan ori ikẹtala, afojusun asòdì-sí-Kristi ni lati
bá awọn eniyan mimọ jagun. Nitori naa kò fẹ́ kí
Kristiani gbà ami eranko naa lati yẹra fun inunibini.
Ó nfẹ́ kí Kristiani kọọkan
kú. Ẹ nsọ pé, "Ó dara iyẹn nbani ninu jẹ́." Ó dara,
ẹ sá kà á dé opin iwe naa
ẹ ó sì rí ẹni tí ó ṣẹgun nikẹyin. Eyi kàn jẹ́ ijakulẹ
igba diẹ ninu ori ikẹtala. Ṣugbọn
ó nsọ ní ẹsẹ ikeje pé:
(Ifihan :) A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun,
ati lati ṣẹgun
wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia,
ati ède, ati orilẹ. Gbogbo awọn ti ngbe
ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a
kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè
Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.
Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, ọkunrin yii ti a
npè ni ẹranko naa, ọkunrin yii ni agbara lori gbogbo
ẹyà, eniyan ati edè, afojusun rẹ̀ ni lati bá awọn
eniyan mimọ jagun ti Bibeli si
nsọ pé gbogbo eniyan lori ilẹ̀ aye yoo sìn í. Ẹ
duro na. Rara, kò maa sọ bẹẹ. Ó nsọ pé
awọn tí yoo sin í ni gbogbo eniyan lori ilẹ aye
ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iye
Ọdọ-Agutan tí a pa lati ipilẹsẹ aye. Nitori naa
ẹ jẹ́ kí nbeere eyi lọwọ yin. Ṣé awọn tí
orukọ wọn WÀ ninu iwe iye nsin i? Rara. Ó dara,
Bibeli nsọ pé oun yoo
ṣe é gbagbọ ti yoo sì kúná tó bẹẹ debi pé yoo tan
awọn ayanfẹ jẹ ti ó bá ṣeeṣe. Ṣugbọn Ọlọrun kò
ní fi aaye gba ọkunrin yii lati tan awọn ti a gbala jẹ.
Nitori naa gbogbo eniyan tí ó
bá ti di ẹni igbala nitootọ, awọn tí ó ti wọlé nigba
igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju paapaa, nigba ti wọn bá bẹrẹ
sí í rí i tí ó nṣẹlẹ, abi kí á ní ireti pé tí wọn bá rí
fọ́nrán yii, wọn yoo sọji pé, “Ẹ duro
ná. Eyi nṣẹlẹ. Asòdì-sí-Kristi naa niyi. Mi ò
lè fi ara mọ́ eyi. Kò yẹ kí nsìn
ọkunrin yii. Kì íṣe ojulowo Kristi niyi. Nitori
naa a ó pa ẹnikẹni tí kò bá ní sìn í.
Ẹnikẹni tí kò bá sì ní sìn í kò lè rà tabi tà.
Kì í kàn án ṣe pé ẹ ó
lọ sí Walgreen lati lọ gba ami ẹranko naa. Kì í
ṣe nnkan tí ó jẹ́ pé
ẹ ó kàn fi ara hàn ni ile ifiweranṣẹ pé “Ó dara, njẹ́
mo lè rí ìfihára temi gba ki nlè rà tabi tàl?” Rara,
Bibeli yè kooro. Ẹ gbọdọ sin asòdì-sí-Kristi naa kí
ẹ tó lè gbà ìfihára naa. Nisisiyi
lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin gan an, ẹrọ olóòótọ wà.
nisisiyi wọ́n nṣẹ ẹrọ tí ó lè ṣe ayẹwo ọpọlọ. Mo
gbagbọ pé boya lati lè gbà ami ẹranko naa, ẹ ó ní
láti sìn asòdì-sí-Kristi naa kí ẹ sì jẹ́jẹ̀ẹ́ ijoloootọ
labẹ asòdì-sí-Kristi naa tí oun yoo si mọ̀ boya ẹ
nsọ otitọ.
Olootu Iroyin: Itan imọ sayẹnsi ti wà. Ọjọ ọla ti dé bayii
Oluṣọ-agutan Anderson: Iyẹn nikan kọ́, ṣugbọn tí
ẹ bá ronu nipa rẹ̀, igboke-gbodo ọkọ̀ ti wá
wà labẹ akoso tó bẹẹ. Awọn ojuko ayẹwo wa
loju popo fun igbiyanju lati wà ọkọ̀ tí ẹ bá sì
gbiyanju lati wọ̀ ọkọ̀ ofurufu, ajọ alaabo irinna
yoo mú kí ẹ kọja lara ẹrọ tí ó nṣayẹwo ihooho ara nitori naa ó sì
dabi ẹni pe a ti ngbe opó ìsakoso kalẹ kí ẹ má bà
lè ṣe ohunkohun ni awujọ ayafi tí ẹ bá fi ori
balẹ fun ẹranko yii ki ẹ sì sìn ẹranko naa
kí ẹ sì gbà ami naa.
Kent Hovind: Bẹẹ gẹgẹ ni o ri. A ó sì sọ wá di ẹni
ibi. Jesu sọ yekeyeke
pé a ó koriira awọn ọmọ ẹyin oun nitori orukọ oun.
Ẹnikẹni ti ko ba fi ọwọ so ọwọ pọ pẹlu
eto iyanu tuntun ti agbaye yii ti wọn npete
rẹ̀ ni a ó kà sí ọta.
Fun apẹẹrẹ, pẹlu ile-iwe, tí ẹ bá lọ fi ọmọ
yin sí ile iwe jẹle-sinmi
ti wọn sì wipe ẹ kò lè wá sile iwe naa ayafi tí ẹ
bá gba abẹrẹ ajẹsara. Ó dara, tí ó bá jẹ́ pé
ẹ ní ikorira fun abẹrẹ ajẹsara nkọ tí ẹ sì wipe, “Ẹ
gbọ́, mo lero pé eyi lè sọni di dindinrin. Ó lè
maa fa ọpọlọpọ nnkan. Mi ò mọ̀, ṣugbọn
mi ò fẹ́ ta tẹtẹ. Mi ò sì
rí ibamu abẹrẹ ajẹsara ninu iwe mimọ nibi ti e ó
ti fi majele diẹ̀ sí agọ́ ara yin lati
ní ajẹsara fun eyi tí ó pọ̀ jù bẹẹ.”
Oluṣọ-agutan Anderson: Bẹẹni, bẹẹni.
Kent Hovind: Otitọ naa ni pe, ile iwe naa sọ pé ẹ kò
lè wá laigba abẹrẹ ajẹsara
nitori naa nisisiyi ẹ lè yàn. Ṣé ẹ ó tẹle ohun ti ẹ
gbagbọ ni abi ẹ ó tẹriba tí ẹ ó sì
fun ọmọ yin ni abẹrẹ ajẹsara nitori itura? Yoo jẹ́
ọkan naa pẹlu ami ẹranko naa. Ó
rí bakan naa ni ọgọrin ọdun sẹyin pẹlu nọmba
igbaye-gbadun. Awọn eniyan lodi sí
nini nọmba kan. “Ah, orukọ ni mi.” Nigba naa ni
wọn fi pẹlẹ pẹlẹ de ibi
ti gbogbo eniyan ti ni ti wọn kò sì tilẹ ronu nipa rẹ̀
mọ́. Ṣé iyẹn ni igbesẹ̀ kinni, ikeji, abi ikẹta
si afojusun ikẹyin ti sisọ gbogbo agbaye di ijọba kan?
Oluṣọ-agutan Anderson: A lé Satani kuro ni ọrun.
Ó mọ pé akoko kukuru ni oun ní. Ó nlọ lati
bá awọn onigbagbọ ati awọn eniyan mimọ
jagun. Kinni ó sì nṣe? Ó nṣe é nipa fifi
ẹnikan sori oyè, abi kò maa ṣe bẹẹ? Dragoni naa fun
un ni agbara rẹ̀. Ó fi ẹnikan sipo lori
gbogbo agbaye, lori gbogbo ẹya ati gbogbo ede.
Ẹni yii yoo si ja ogun eṣu
lodi sí awọn eniyan mimọ. Bibeli nsọ
ni ẹsẹ ikọkanla pé:
(Ifihan :-) Mo si ri ẹranko miran goke l
ati inu ilẹ wá, o si ni
iwo meji bi odo-agutan, o si nsọ̀rọ bi dragoni.
O si nlò gbogbo agbara ẹranko
ekini niwaju rẹ̀, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti
ngbe inu rẹ̀ foribalẹ fun ẹranko ekini
ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ̀ san.
Oluṣọ-agutan Anderson: nitori naa ọkunrin
naa nbeere fun ijọsìnfun. Ó nsọ ninu ẹsẹ ikẹtala pé:
(Ifihan :-) O si nṣe ohun iyanu nla
[awọn iṣẹ́ iyanu], ani ti o fi nmu iná sọkalẹ
lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia.
O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ
nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati
ṣe niwaju ẹranko na; o nwi
fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan
fun ẹranko na ti o
ọgbẹ nipa idà, ti o si yè
(Ifihan :) A sì fi fun lati fi ẹmi
fun àwòrán ẹranko naa; kí
o si maa sọrọ, kí ó sì
mu kí á pa gbogbo awọn tí kò foribalẹ fun
àwòrán ẹranko náà.
Oluso-agutan Anderson: Ẹyin si wi pe, “Ki ni àwòrán
ẹranko yii ti a fun ni
ẹmi? bí a se n sunmọ eyi, mo lérò pé a le è ni òye
erọ naa diẹ sii, nitori bẹẹ emi ko tilẹ
mọ iru àwòrán ti eyi yoo
jẹ. Sugbọn o jẹ iru àwòrán
ẹranko naa ti ó lè sọrọ,ti o si le mu
kí á pa awọn ti kò foribalẹ fun.
Eyi si mu mi ranti Danẹili, orí
ikẹta, ẹ rántí Nebukadinẹseri ti o jọba lori
ayé ti o laju nigba náà? Njẹ ẹ rántí
bi o ti se ère nla ti wọn si ni lati
jọsin fun ère náà? Ati ohun ti yoo sẹlẹ
ti wọn kò bá jọsin fun ère náà?
A pa wọn, abi bẹẹ kọ? njẹ eyi ko farapẹ irú eyi
ti a ri nibi yii? Eyi jẹ apẹrẹ asodi-si-Kristi.
ẹ wo ẹsẹ . kókó rẹ niyi:
(Ifihan :-) O si mu gbogbo wọn,ati
kékeré ati nla, ọlọrọ ati talaka, ominira
Ati ẹru,ki a fi àmì kan fun wọn ni
ọwọ ọtun wọn, tabi ni iwaju wọn, ati ki ẹnikẹni
má le rà tabi ki o tà, bikose ẹnití ó bá ní àmì
orukọ ẹranko na, tabi iye
orukọ rẹ. Nihin ni ọgbọn gbé wà. Ẹniti o ba ni
òye, ki o siro iye ti mbẹ lara ẹranko naa:
nitori iye eniyan ni,iye rẹ na si
jẹ ọtalelẹgbẹta o le mẹfa
Eyi jẹ ọkan ninu awọn ohun èlò ti Satani má n lo
lati fi gbógun ti awọn onigbagbọ.
àmí ẹranko yii jẹ ohun èlò ti Satani
n lò lati gbógun ti awọn ayanfẹ, nitori pe
tí ò kò bá lè rà tabi tà, o nira lati gbe ayé òde
òní, abi bẹẹko? Tabi ni ayé yoowu. nitoribẹ
kì í se pé o se òfin ti o sọ pé bí o kò
jọsin fun asodi-si-Kristi ki a ó pa ọ nìkan.
inúnibíni wà nibẹ pẹlu.
eyi jẹ gbígbé ogun ti awọn ayanfẹ. Ó tún mú
ki o sòro fún awọn ayanfẹ lati rà
tabi tà nitori wọn ko ni àmì
ẹranko naa, àmì ẹranko yii si ni
a o fun awọn ti o jọsin fun ẹranko náà nìkan.
Awọn ti a ti gbala, awọn
ti o jẹ ayanfẹ, wọn ki yoo jọsin fun ẹranko náà.
Bibeli salaye eyi daradara ninu iwe Mateu
ati níbòmíràn.nitoribẹ wọn ki yoo
le rà tabi tà, wọn yoo si
fun awọn eniyan ni asẹ lati pa wọn. Nisinsinyi,
wo ara rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o wa ninu aye kan- n kò
sọ pe ilu kan tabi orilẹ-ede kan,
Mo wi pe ninu AYE kan- tí o kò le rà
tabi tà ti a si tun fi asẹ fun awọn
eniyan lati pa ọ. Njẹ o le ro
bi yoo se nira tó lati lè gbé ni iru
ayé bẹẹ? Kì í se iyẹn nikan, kinni ka sọ
nipa awọn kamẹra asọniwo ti o n wọle?
Kini ka sọ nipa awọn kamẹra ti n wo nọmba mọto?
kini ka sọ nipa awon ẹrọ ti n yẹ ara ẹni wo fínífíní?
Tabi fífi káádì idanimọ rẹ hàn ni gbogbo ìkóríta ayẹwo? fífi
káádì idanimọ rẹ hàn kí o tó le wọ ọkọ oju-irin tabi
ọkọ òfurufú? Njẹ o mọ eyi?
laipẹ iwọ yoo ni lati fi ohun miran han wọn.
“Oya, jẹ ki a wo ọwọ ọtun rẹ
ọtun rẹ. O dara, máa lọ. kí ọjọ òní san ọ.
Èyí kò jinna rárá. Bóyá
nígbà ti awọn eniyan ka èyí ní bi ọgọrun un ọdun
sẹyin wọn kò wó lọna kanna
bí àwa se n wò ó. Nigba ti awa ba wò ó, ó da
bi ẹni pe awọ kan boni loju, abi bẹẹkọ?
ìdí níyí ti mo se rò ó pe eyi le ti ku si dẹdẹ.
Awọn Kristiẹni ode-oni ko mura silẹ fun eyi
rara. Wọn kò gbaradì fun eyi rara. Njẹ o
mọ ohun ti o ni lati se? O ni lati murasilẹ
ninu ẹmi ki o si gbaradi ki o ma ba a di,
“Kilo n sẹlẹ?” O
ní lati mura silẹ. O ní lati gbaradì.
Idi niyi ti Ọlọrun se n kilọ fun wa
ti o si tun n kilọ fun wa. Idi niyi ti Pọọlu se n kilọ fun
awọn eniyan to wa ni igba aye rẹ. O han gbangba pe wọn
kò gbé ni aye ipọnju nla naa, sugbọn wọn la
ipọnju ti wọn kọja bi gbogbo onigbagbọ se n là á kọja
O wi pe, “ A kilọ fun yin. Nitootọ, nigba ti a
wà pẹlu yin, a sọ fun yin tẹlẹ awa yoo
la ipọnju kọja bi o ti se waye yii,
bi ẹyin ti se mọ, nitori eyi ni a se nilo lati kilọ
fun wa kí á sì ní òye pé eyi nbọ kí á lè
a le è kápá rẹ
Iran - Ikusidẹdẹ
Ronald Rasmussen: A kò kilọ fún àwọn Kristiẹni
òde ìwòyí nípa àwọn isẹlẹ tí wọn yoo kojú
nínú ipọnju ńlá naa, dípò èyí, àwọn olusọ àgùntàn
káàkiri ilẹ Amerika nkọ àwọn ènìyàn pé
ìgbásókè yoo sẹlẹ kí asòdìsí-Kristi tó gbé
ogun rẹ ti àwọn àyànfẹ àti pé
ìgbásókè ni yoo jẹ isẹlẹ akọkọ nínú itolẹsẹẹsẹ
àwọn asọtẹlẹ Ọlọrun. Ekọ yii,
ti a mọ si “ ikusidẹdẹ” n kọ ni pé Kristi le e padà
wá ninu awọsanma nigbakugba àti pé
ki yoo si awọn ààmì bibọ rẹ. Bí ó ti wù kórí
Bibeli nkọni pe bibọ Kristi
kì í se ní kiakia àti pé àwọn isẹlẹ miran
wà tí o gbọdọ kọkọ sẹlẹ
Olusọ-agutan Anderson: O seése kí o ti gbọ ekọ
yi ti o nsọ pe Jesu lè dé loni yii.
Taa ní o ti gbọ yen ri? ? A ń pè ní “ ikusidẹdẹ ìpadàbọ Kristi.
Wọn gbagbọ pé
Jesu ń padà bọ nigbakugba. Mo ti béèrè lọwọ
àwọn ènìyàn lọpọ ìgbà, nígbà tí wọn sọ fún mi
pé Jesu lè dé nígbàkugbà, " Níbo ni Bíbélì ti sọ èyí? "
sùgbọn ohun tí wọn
kò lè fi saláì padà wà kòmí lòjù ni pé, " Bíbélì wí pé
kò sì eni tì ó mọ ọjọ tàbí wákàtí
ti yoo wa." àti pé ọpọ ìgbà ni wọn kò le fi èyí hàn ọ
sùgbón mo níló láti ràn wọn lọwọ
láti w aa. Sugbọn o wi pé, “Nkò ní aridaju yii.
N kò mọ pàtó
orí Bibeli naa. Sugbọn mo mọ pe Jesu
sọ pé kò si ẹni ti o mo ọjọ tabi wakati." Mo wi pé
"Jẹ ki n ràn o lọwọ. Ó sọ bẹẹ ninu Iwe Mateu :."
Jẹ ki n kà á fun ọ ohun ti bibeli
sọ, nitori mo fẹ fi han ọ bi eyi ko se bá Bibeli mu
nitori o jẹ aarin gbùn-gbùn ẹsin Kristiẹni
Tí o ba lọ si ilé ìtàwé Kristiẹni lọwọlọwọ bayii,
wọn yoo ni orisirisi ìwé
ati awọn fidio, tani o ti gbọ nipa eré ori itage yii
"Awọn To Kù Lẹyin"?. o jẹ itan arosọ patapata.
kò ni ohun kan se pelu Bibeli. Kò ba Bibeli mu rara.
Bibeli si sọ ninu iwe Mateu ::
(Mateu :) Sugbọn ni ti ọjọ ati wakati náà, kò si
ẹnikan ti o mọ ọ, rara, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ ọ,
baba mi nikan
Olusọ-agutan Anderson: Awọn eniyan yoo tọka sí
ẹsẹ Bibeli yii, wọn yoo sì wí pé "wo eyi? ko si ẹnikan
tí o mọ ọjọ tabi wakati naa. Eyi tumọ si
pe o le sẹlẹ nigbakugba."Sugbọn ẹ kiyesi pe
o sọ pe "Sugbọn ni ti ọjọ naa ko si ẹnikan tí o
mọ ọjọ tabi wakati ."Ibeere naa ni pé
“ọjọ wo?" ọjọ ti o sẹsẹ sọrọ tan nipa rẹ. oun niyi
ní ẹsẹ , O wi pe ọjọ náà nbọ lẹyin
ipọnju naa. O sọ ninu ẹsẹ
ní kété lẹyin ipọnju
awọn ọjọ naa ni òrùn yoo di òkùnkùn tí
osupa ki yoo fi imọlẹ rẹ han,awọn
irawọ yoo jabọ lati oju ọrun, ti awọn agbara
tí o n be lọrun yoo sì mì tìtì
Olusọ-agutan Anderson: ó se apejuwe awọn isẹlẹ ti
yoo sẹlẹ. Lẹyin eyi o wi pe:
(Mateu :) Sugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si
ẹnikan ti o mọ ọ, rara, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ ọ, bikose
baba mi nikan.
Olusọ-aguntan Anderson: nitoribẹ a kò mọ ọjọ
tabi wakati na sugbọn ohun kan ti a mọ ni pé
yoo waye lẹyin ipọnju naa. Awọn eniyan ti o gbagbọ
ninu igbasoke siwaju sáà ipọnju nla náà yoo se awọn
àforírò àràmàndà nibi tí iwọ yoo ti gbiyanju lati fi han
wọn," ẹ wò ó, o sọ nibi yii pe LẸYIN
IPỌNJU NAA." Ohun ti wọn yoo sọ niyi,
"eyi kì í se nipa igbasoke. Eyi
kì í se igbasoke." iwọ wi pe, " sugbọn bawo
ni mo se mọ eyi? nitori pe yoo sẹlẹ leyin
ipọnju náà. Ati paapaa, a mọ wi pe igbasoke
yoo sẹlẹ siwaju sáà ipọnju náà
Sugbọn nigba náà ni iwọ yoo beere lọwọ wọn,
" Nibo ni Bibeli ti sọ pe igbasoke lè
sẹlẹ nigbakugba?" o sọ bẹ nibiyi,
o wi pe ko si ẹnikan ti o mọ ọjọ tabi wakati náà"
"o sọ nisisiyi pe eyi ki i se nipa igbasoke"
nigba ti o ba wi pe lẹyin igba ipọnju ni,
ajẹpe iwe Mateu kò sọ nipa igbasoke niyẹn.
sugbọn nigba ti o wi pe ko si ẹnikan ti o mọ ọjọ tabi
wakati naa, nisisiyi lójijì ni Mateu tun bẹrẹ si ní sọ
nipa igbasoke.Ati pe nígbà tí o ba sọ pe ẹni meji wa
ní oko,a mú ọkan a fi ekeji silẹ,
eyi tún tumọ si igbasoke. " sa
pa ẹnu mọ kí o si se ohun ti wọn wi fun ọ.sá pa
ẹnu mọ ki o si gbagbọ ninu igbasoke siwaju saa ipọnju náà nitoripe
mo wí bẹ." iwọ wi pe, " salaye lọna mejeeji
je olootọ, salaye lọna mejeeji." O dara, eyi ni
ọna keji. Pa ẹnu mọ ki o si gba ohun ti mo ni ki o
so gbọ ki o si dẹkun ibeere.
pa ẹnu mọ ki o si gbagbọ nitori pe mo sọ bẹ.
Eyi jẹ abala igbasoke siwaju sáà ipọnju. otitọ ni. wọn
kò ní ohunkóhun.
Emi ní ọpọlọpọ ẹsẹ bibeli, sugbọn wọn
kò ní ohunkóhun. Bí ó ti wù kí ó rí awọn ekọ òdì míràn má n
dá lórí awọn ẹsẹ bibeli kọọkan
ti a yí sihin-sọhun ,awọn eniyan yóò yọ ẹsẹ
bibeli kan jade wọn yóò dori rẹ kodo
wọn a sí yii sihin-sọhun. Ekọ igbasoke siwaju ipọnju naa
kì í se ẹsẹ bibeli ti a n yí sihin-sọhun. wọn kò
ní ẹsẹ bibeli rara ni. Kò sí ẹsẹ bibeli tí o sọ
ohunkohun nipa pe igbasoke yóò
waye kí sáà ipọnju na to de. Ó jẹ
ẹkọ kan ti ko ba bibeli mu
rara. Ó da lori isẹse. ó da
lori iwe tabi aworan asàpèjùwe kan ti ẹnikan kà.
kò dá lori bibeli.
kò wá lati inu bibeli. kò fi
ẹsẹ mulẹ ninu bibeli. Mo ri wi pe igbakugba ti
mo ba se alaye yìí fun awọn eniyan ti o wà ninu ijọ
kì í sòro fun wọn lati ni òye ẹkọ yii.
Awọn ti o wa lori aga iwaasu ni kì í
gba ẹkọ yii gbọ, èmi yoo si sọ idi rẹ.
ẹkọ igbasoke siwaju ipọnju naa ni o jẹ gbajúgbajà ẹkọ
tí o ba fẹ di ilumọka, o ní lati waasu
nipa igbasoke siwaju sáà ipọnju naa. Sugbọn ti o ba bẹrẹ sí ní
waasu pe igbasoke yoo waye lẹyin sáà
ipọnju naa, won yoo dẹyẹ si ọ
wọn yoo yọ ọ kuro lẹgbẹ,
wọn yoo si kọ ọ ni ile ijọsin,nitoripe
wọn kò fẹ iyipada lori ẹkọ yii.
nitori awọn eniyan kan wa lóde ti wọn ní
ètò lati ri wi pe ẹnikankan kò gbọ
otitọ lori ẹkọ yi. otitọ ni.
ọna ti wọn n lo lati fi ẹkọ yii sinu
okunkun ni nipa ibẹru ati ìdáyàjani. Mo má n ba
ba awọn olusọ-agutan sọrọ lori eyi lọpọ ìgbà. Mo ma n fi otitọ
han wọn lori eyi.wọn gbagbọ pelu mi. sugbọn wọn
kì í kọ ẹkọ yii lori aga iwasu wọn,
nitori wọn bẹru ki gbogbo awọn
ọrẹ wọn to jẹ olusọ-agutan ma kọ ẹyin si wọn. wọn
ko ni le ni itakurọsọ lori eyi.
wọn ko ni le waasu ninu awọn
ijọ wọnyi nitoripe o gbọdọ je ẹni ti o
gbagbọ ninu igbasoke siwaju saa ipọnju náà ki o to le ba
wọn kẹgbẹ pọ. Sugbọn ti o ko ba gbagbọ ninu eyi,o kò sí ninu agbo won. ọpọ
ìgbà ni wọn ki yoo gbà nitori
wọn ko fẹ jẹ majele ati pe wọn ti
se iwaasu ti o lòdì lati ọpọ ọdun sẹyin. Wọn
kò fẹ gba eyi gbọ. wọn kò fẹ
gbà pe ẹkọ òdì ni ile ẹkọ bibeli wọn kọ wọn.
wọn kò fẹ gba pe wọn
se àsìse. Gbogbo eniyan lo ma n se àsìse.
Sugbọn a ma n dagba sii. A sì ma n kọ ẹkọ titun.Tí o ba
se àsìse lori ohun kan, o ni lati se atunse
lori rẹ. Bibeli sọ ni nu iwe Galatia ::
(Galatia :) Njẹ nisisiyi eniyan ni emi nyi lọkan pada
tabi Ọlọrun? tabi eniyan ni emi nfẹ lati wu? nitoripe bi emi
ba si nwu eniyan, emi ki yoo le se iransẹ Kristi
Olusọ-agutan Anderson: Awọn oniwaasu yii ni lati pinnu
boya wiwu eniyan lo se pataki jù, nipa
wiwaasu ohun to jẹ gbajugbaja,wiwaasu nipa
igbasoke siwaju sáà iponju naa nitoripe ohun ni gbogbo eniyan
fẹ gbọ, nitoripe wọn fẹran ere ori itage
ati erọ àmúseré fidio pelu erọ àmúseré ori pátákó
ati erọ DVD. tabi ki wọn ki o tẹle ohun ti bibeli
sọ ni pàtó ki wọn si dide lati waasu pe
igbasoke yoo waye lẹyin sáà ipọnju naa. Eyi jẹ
apẹrẹ pataki awọn to gbe ohun ti eniyan
sọ lékè ohun ti Ọlọrun sọ. Ó jẹ apẹrẹ pataki
ailo bibeli gẹgẹ bi
alasẹ tó gaju ati titẹle àsà,titẹle
ohun ti wọn kọ wa, titẹle
ohun ti awọn eniyan nsọ, titẹle ohun ti n sẹlẹ laye
dípò ka tẹle ohun ti bibeli sọ.
Olusọ-agutan Jimenez: Ní ìgbà kan rí mo gbagbọ ninu
igbasoke siwaju sáà ipọnju naa o jẹ ohun ti a kọ mi lati ìgbà ti mo
wà ni ọmọde, ako si le jiyan
ohun ti wọn ba sọ fun wa sugbọn ni ìgbà ti a mu mi mọ
otitọ, ti mo si bẹrẹ si ni ka bibeli ati ohun ti bibeli
kọ ni pato, mo ni lati
se ìpinnu fun ara mi boya maa
tẹle ohun ti aye tẹle, boya
maa tẹle ohun ti gbogbo aye tẹle, tabi,
ki n mu iduro mi ninu ohun ti mo gbagbọ
tí mo si mọ pe o je otitọ.
Ninu igbesi aye mi mo ti ni adojukọ
nipa pe awọn eniyan n sọ ọrọ buburu nipa mi nitori
iduro mi ninu igbasoke siwaju sáà iponju náà
sugbọn mo ni ireti pe boya o n gbọ
eyi tabi ò n wò ó, tabi o ti bẹrẹ
sí ní rí otitọ nipa eyi,
pe iwọ yoo fi igbagbọ jade ti iwọ yoo
duro lati ran wa lọwọ lati
koju ìjà si ẹkọ ti ko ba bibeli mu yii
eyi ti n se ẹkọ igbasoke siwaju sáà ipọnju naa.
Ẹsẹ bibeli miran ti o mu mi gbagbọ ni
iwe Tẹsalonika keji,ori keji, ẹsẹ ikini si
ẹsẹ kẹta
( Thessalonians :-) Sugbọn awa mbẹ yin ara,
nitori ti wiwa Jesu Kristi Oluwa wa
[ó n sọ nipa pe Jesu Kristi n bọ], ati nipa
ipejọpọ wa sọdọ rẹ [eyi ti o tọka si igbasoke]
ki ọkan yin ki o ma se tètè mì
tabi ki ẹ mase jáyà, yálà nipa ẹmi,tabi
nipa ọrọ, tabi nipa iwe bíi lati ọdọ wa wá,bi ẹnipe
ọjọ oluwa de. [ó tún sọ nipa igbasoke lẹẹkansi]
Olusọ-agutan Jimenez: ó wi pe," ẹ wò ó, kò kù si dẹdẹ.
kì í se isẹlẹ ti o kàn ti
yoo sẹlẹ." ó wi pe," Ẹ mase jẹ ki ẹnikẹni
tan yin jẹ lọnakọna nitoripe ọjọ náà (o n sọ
nipa ọjọ náà tí a ó wà ni ipejọpọ)
kì yoo de bikosepe ìyapa nì
bà kọ de ki a si fi ẹni ẹsẹ nì han,
tí í se ọmọ ègbé". A ti fi idi rẹ mulẹ nibiyi
ninu bibeli wi pe ọjọ ipejọpọ wa
pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa ki yoo
bikosepe ìyapa nì bà kọ de
ki a si fi ẹni ẹsẹ nì han.ohun kan soso
tí ó kù si dẹdẹ ni bibọ Asodi-si-Kristi
Olusọ-agutan Anderson: Bibeli sọ fun wa ni pàtó
pe ọjọ Kristi kò tí ì sun mọ etílé
o wi pe bi ẹnikẹni ba gbiyanju lati sọ fun yin pe
ọjọ Kristi kù si dẹdẹ, ẹni náà
n parọ tàn yin jẹ ni. Ẹni náà jẹ ẹlẹtan.
o wi pe ẹ ma se jẹ ki a tan yi jẹ nipa ọrọ tabi
ẹmi tabi iwe lati ọwọ wa,
iwe ti o wa lati ọdọ wa to wi pe
ọjọ bibọ Kristi kù si dẹdẹ. Ẹ ma se jẹ ki ẹnikẹni tàn
yin jẹ lọnakọna. Ọjọ náà ki yoo wá bikosepe
awọn ohun kan kọkọ sẹlẹ.
igbasoke ko le waye nigbakugba. ipọnju náà
kọkọ gbọdọ waye ná. Asodi-si-Kristi gbọdọ kọkọ
gba ijọba ná. Òrùn ati Òsùpá yoo
dí okunkun kí ọjọ nla ati
ọjọ ẹru Oluwa to de. Bibeli
sàlàyé rẹ daradara. Ọjọ naa ki yoo wá bikosepe ìyapa
nì ba kọ de ki a si fi ẹni
ẹsẹ ni han. A o fi asodi-si-Kristi
hàn. Asodi-si-Kristi yoo joko ninu tempili
Ọlọrun yoo si pe ara rẹ ni Ọlọrun.
Asodi-si-Kristi yoo wà ni ijọba ki igbasoke
tó sẹlẹ.Eyi kò le rárá.
Sugbọn ti a ba wo iwe Luku , o waye ní sisẹntẹle
siwaju Mateu , nitoripe Mateu ati
Luku farapẹra. Nitoribẹ ninu Luku
a kà nipa isẹlẹ akosilẹ akọkọ
ti Jesu ti n kọ awọn ọmọ eyin rẹ ni
ẹkọ yii. Bibeli wi pe:
(Luku :) Bí ó ti rí ní ọjọ Noa,
bẹni yoo ri ni ọjọ
ọmọ-eniyan [Jesu Kristi]
Olusọ-agutan Anderson: Ọpọ eniyan ni yoo tumọ eyi
sí pé awọn eniyan
di ẹni buburu bí
ti ọjọ Noa. Pẹlupẹlu, O sọ pe bí ó ti rí
nigba aye Lọti, bẹẹni yoo rí
ní ọjọ bibọ ọmọ eniyan.
awọn eniyan yoo si wi pe "bẹẹni, yoo buru gẹgẹ
bí ó ti rí ní Sodomu ati Gomora."
wọn yoo si tọka si awọn ohun tí ó n
sẹlẹ lawujo wa gẹgẹ bi
irú eyi tí ó sẹlẹ ni Sodomu ati Gomora.
wọn yoo si wipe o buru gẹgẹ bi
bí ó ti rí ní Sodomu ati Gomora tabi ki wọn wipe
yoo buru bí ó ti rí ní ìgbà aye Noa
Sugbọn nitootọ, eyi kì í se àfiwé
ti Jesu n se.
Olusọ-agutan Jimenez:ní ẹsẹ o wi pe:
(Luku :-) Gẹgẹ bí ó ti rí ní
ọjọ Lọti, wọn njẹ,wọn nmu,
wọn nrà, wọn ntà, wọn ngbìn, wọn nkọle;
sugbọn ni ọjọ na ti Lọti jade kuro
ni Sodomu, òjò iná ati sulfuru rọ
lati ọrun wa, o si run gbogbo wọn
Olusọ-agutan Jimenez: ohun tí a rí kọ ninu ayọka bibeli
yi ni pé nigbati a mu Lọti jade
ni Sodomu, eyi se apẹrẹ Igbasoke.
A ri angẹli meji nlọ si Sodomu ti
o n sapẹrẹ ayé ti wọn si mú awọn onigbagbọ
jade kí á tó tú ibinu Ọlọrun
sori ilu naa. Iwe Ifihan kọ
wa ni ohun kan naa. Bibeli sọ ninu iwe
ifihan pe Jesu Kristi rán
awọn angẹli rẹ lati kó awọn ayanfẹ jọ ati lati mu wọn jade
kuro ninu ayé. Iwe ifihan
sọ fun wa ni pato pé aabọ wakati kọja
lọ,lẹyin eyi ni o bẹrẹ si ni tú ibinnu rẹ jade.
Scene - Apejuwe Igbasoke
Olusọ-agutan Anderson: Awose "awọn ti o ku sẹyin" yii
ninu eyi ti gbogbo eniyan pòóra ti gbogbo eniyan si
si n sọ pe, " nibo ni gbogbo wọn lo?" Eyi
kì í se ohun ti awọn eniyan yoo ma wi. Nitori
Bibeli nsọ pé ní ọjọ kan naa tí a ó gbà
wá, Ọlọrun yoo bẹrẹ sí í
rọ̀jò idajọ. Ọlọrun yoo bẹrẹ sí í rọjo
iná ati imí-ọjọ́ sori aye yii. Awọn eniyan
yoo bẹrẹ sí í mọ̀ pé nnkan kan nṣẹlẹ.
Awọn eniyan yoo maa sá àsálà.
Awọn eniyan yoo bẹrẹ sí í sọ fun awọn oke
pé kí ó ṣubu lù wọ́n ki ó sì daabo bò wọn nitori
iná, imí-ọjọ́, ibinu naa tí yoo wá.
Ọjọ kan naa tí a bá gbà wá
kuro nihin ni ọjọ kan naa tí Ọlọrun yoo
bẹrẹ sí í rọ̀jò ibinu rẹ̀. Idi niyẹn
tí ó fi jẹ́ pé nigba tí oorun ati oṣupa bá
ṣookun bibeli nsọ pé ọjọ nlá ibinu oun ti dé
tani yoo sì lè duro? Nitori pé ọjọ kan naa yẹn,
ọgbọn iṣẹju lẹyin rẹ̀, Ọlọrun nbẹrẹ sí í rọ̀jò
iná ati imí-ọjọ́. Nitori naa ní ori kẹfa iwe Ifihan,
oorun ati oṣupa ṣookun. Ori ikeje,
ogunlọgọ awọn onigbagbọ nfi ara hàn ni
ọrun. Ori ikẹjọ, ó nbẹrẹ sí í rọ̀jò
ibinu rẹ̀. Ó jẹ́ ohun ti Bibeli nkọni ninu iwe Matteu
ori ikẹrinlelogun gan an. Oorun ati oṣupa ṣookun, lẹyin naa
igbasoke. Ó rọrun tó bẹyẹn. Mo maa nbá awọn
eniyan tí ó gbagbọ ninu igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju sọrọ
wọn yoo sì maa sọ fun nnkan kan fun mi ninu
meji ni gbogbo igba. Boya wọn yoo sọ fun mi pé
a kò tilẹ mẹnuba igbasoke ninu
Iwe Ifihan tí ó jẹ́ ohun tí ó ṣajeji pupọ
lati sọ niwọn igba tí ó jẹ́ pé iwe Ifihan
nṣalaye ni kikun tó bẹẹ nipa awọn iṣẹlẹ igba
ikẹyin. Lati yọ irú iṣẹlẹ tí ó ṣe pataki tó bẹẹ
bí bibọ̀ Jesu Kristi ninu awọsanma ati gbogbo
onigbagbọ lati atẹyinwa tí a ngba
soke pẹlu rẹ̀ ní awọsanma...iyẹn
jẹ́ irú iṣẹlẹ pataki tó bẹẹ. Lati sọ pé
a kò mẹnuba á rara ninu iwe Ifihan,
pé kì í ṣẹlẹ rara ninu iwe Ifihan,
kò ṣe é finu rò. Ṣugbọn nitori
pé ó tabuku nnkan tó bẹẹ lati sọ
pé a kò rí igbasoke ninu iwe Ifihan rara
ọpọlọpọ awọn eniyan tí ó ṣaaju ipọnju ti
gbiyanju lati wá a kí wọ́n sì lè rí nnkan kan tí wọ́n lè
lò gẹgẹ bi igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju,
ohun tí mo sì ngbọ nigba gbogbo niyi
lera-lera – Ifihan :. Ifihan ori kẹrin, ẹsẹ ikinni wipé:
(Ifihan :) Lẹhin nkan wọnyi emi wo, si
kiyesi i, ilẹkun kan sí silẹ li ọrun: ohùn kini
ti mo gbọ bi ohùn ipè ti mba mi sọrọ,
ti o wipe, Goke
wa ihin, emi o si fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn ọ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa eyi jẹ́
ohun kan bí ipè. Kò sí ipè ninu ẹsẹ yii
tí ó nsọrọ tí ó sì nsọ fun Johannu (ẹyọ kan,
eniyan kan), “Goke wa ihin, emi o si
fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn Ọ.”
Wọn yoo sì wipe, “Wò ó, igbasoke niyẹn
tí ó wà nibẹ gan an.” A ngba ọkunrin kan soke.
wọn yoo sọ pe igbasoke niyẹn. Ohun tí ó tabuku ẹni
nipa eyi ni pé wọn kìí tilẹ kà ẹsẹ keji.
Nitori pé ní ẹsẹ keji o nsọ pé:
(Ifihan :) Lojukanna mo si wà ninu
Ẹmí, si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan
li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na.
Oluṣọ-agutan Anderson: Igbasoke kì í
ṣe ẹmi tí ó ngoke lọ sí ọrun. Igbasoke jẹ́
ajinde ara. A ó gbà wá soke lojukooju
sí ofurufu. Eyi kì íkàn íṣe
irú nnkan kan nibi tí ẹmi wa ti ngoke lọ.
Bibeli yè kooro pé igbasoke jẹ nnkan,
afojuri ti ajinde awọn oku ninu Kristi
tí yoo kọ́kọ́ jinde. awa tí a wà laaye
tí a ṣẹku ni a ó gbà soke pẹlu rẹ̀ ninu
ara. Nitori naa igbasoke ti ẹmi yii
fun ẹnikan, iyẹn Johannu, dajudaju kì í
ṣe igbasoke naa. Tí ẹ bá sì rò pé eyi ni
igbasoke naa, nṣe ni ẹ nsọ itumọ tí ó
mẹ́hẹ jọjọ. Ó pani lẹrin nitori pé awọn eniyan
tí mo bá sọrọ tí wọ́n gbagbọ ninu igbasoke
ṣaaju ipọnju nsọ pé awọn ntumọ Bibeli ní ọna taara.
sibẹ nigba tí ẹ bá beere lọwọ wọn pé kí wọ́n
fi igbasoke hàn yin ninu iwe Ifihan, wọn yoo mú
yin lọ sinu iwe Ifihan
Ori ikẹrin, ẹsẹ ikini. A ngba ọkunrin kan soke sí ọrun.
Wọn kò tilẹ nkà á dé ẹsẹ ikeji nigba tí ó nwipe,
“Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́
kan li ọrun." Kò
tilẹ goke lọ ninu ara. Àgọ́-ara rẹ̀ ṣì wà nibẹ
ni Erekusu Patimo. awọn oku ninu Kristi
ni yoo kọkọ jinde. Lẹyin naa ni a ó gbà
awa tí a wà laayè tí a sì ṣẹ́kù soke pẹlu
wọn ní awọsanma. Eyi kì íkàn íṣe irú iṣẹlẹ ti
ẹmi kan. Eyi jẹ́
iṣẹlẹ afojuri. Iyẹn jẹ́ ifẹloju gidi lati sọ pé i
gbasoke niyẹn. Awọn tí
ó gbagbọ ninu igbasoke ṣaaju ipọnju ní lati sọ
pé iwe Ifihan, ori kẹrin, ẹsẹ ikini ni igbasoke naa
nitori pé iyẹn nikan ṣoṣo ni wọn kò tilẹ
lè rí ninu iwe Ifihan ṣaaju
ipọnju naa. Kò kàn sá bá a mu. Mo
lero pé, wọ́n ní lati wá nnkan kan. Mo gbọ́njú
bá ikọni nipa igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju ni.
Nigba tí mo wà léwe, a kọ́ mi pé a
kò mẹnuba á rara ninu iwe Ifihan. Gbogbo
igba ni mo nronú pé nnkan kan wà nibẹ tí ó mú ifura wá
nipa iyẹn. Iṣẹlẹ tí ó ṣe pataki tí ó sì jọjú bí
igbasoke...Ẹ ti ní iwe kan nipa
asọtẹlẹ igba ikẹyin, iyẹn iwe Ifihan, kì ísì íṣe pé ó mẹnuba á? Kì í
mọgbọn wá rara. Gbogbo igba ni nkọ́ mi gẹgẹ
bi èwe pé igbasoke naa yoo wà nibi tí ẹ sá ti
ngbé igbe-ayé yin lọ tí ó sì jẹ́ pé lojiji ẹ poora. Ṣugbọn ó
pọ̀ pupọ jùgoing about your life and all of a sudden
you just disappear. But it’s so much greater
jù iyẹn lọ, nitori pé bibeli nsọ pé gbogbo oju ni yoo rí i. A ó rí oorun
ati oṣupa tí ó ṣookun. Ó nsọ ninu iwe Luuku, ori
ikọkanlelogun pé nigba ti ẹ bá nrí awọn nnkan yii tí ó
nwá sí imuṣẹ, ó nsọ pé ẹ wòkè, nitori pe irapada yin
ti sunmọ etile. Ẹ fi inu rò ohun ti yoo
jọ ni saa yẹn nigba tí oorun bá ṣookun, oṣupa
ṣookun, awọn irawọ bẹrẹ sí í jabọ,
a sì wòkè tí a sì nmọ̀ pé oun ni. Ó wà nihin. A ti ṣe é yọri.
Kent Hovind: Ó fẹ́ fi ara jọ sinima ṣíṣe. Njẹ́ ẹ
ti wo awọn eniyan olokiki
kí wọ́n wá sí ibi kan. Gbogbo igba ni wọn maa
nni itanṣan imọlẹ ati didun ibọn ati
èéfín ati gbogbo nnkan miran. Wọ́n fẹ́ mú ori eniyan wù. “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí." Tí
ẹ bá nkà iwe ifihan, ori ikẹfa abi Matteu, ori ikẹrinlelogun,
Maaku, ori ikẹtala, abi Luuku, ori ikọkanlelogun, eyikeyii ninu ibi awọn ibi kika naa tí ó
njuwe oorun ati oṣupa tí ó nṣookun, ó njọni
lójú pupọ nigba tí ẹ bá wò ó. Oorun
ati oṣupa ṣookun eyi tí yoo sá fẹ́rẹ̀ ẹ́ pè akiyesi
gbogbo eniyan lori ilẹ aye.
Ṣugbọn ó tún nsọ pé ilẹ-ríri kan wà, nitori naa tí
ẹ bá jẹ́ afọju, yoo ṣì
pè akiyesi yin.
Oluṣọ-agutan Anderson: Nigba naa ni ó sì jẹ pé ní
saa okunkun biribiri yẹn, Jesu Kristi mbọ ní
awọsanma, tí ó ntan imọlẹ sí gbogbo oju ofurufu
bí manamana
nibi tì ó ti ntan imọlẹ lati ìkangun ọrun kan dé
ekeji, a ó sì woke tí a ó sì rí
Jesu Kristi tí ó mbọ Jesus ninu awọsanma. A ó
mọ nigbakigba tí a bá ti fẹ́ gba wá
soke pẹlu rẹ̀. Mo ni ireti pé ng ó wà laaye lati ri
ọjọ yẹn. Mi ò ng ò mọ̀ boya eyi yoo
ṣẹlẹ loju ẹmi wa. Mo ní ireti pé eyi yoo ṣẹlẹ loju
ẹmi mi. Mo ni ireti pé ng ó lè fi ara dà
inunibini ati ipọnju yẹn. Irú ohun ẹru wo ni
yoo jẹ́ lati wà laye ní
ọjọ yẹn nigba tí Jesu Kristi mbọwa ninu
awọsanma. Ó ga pupọ jù bí a ti mú wa
gbagbọ lọ.
Kent Hovind: Ero pé ipadabọ lẹẹkeji ìdákọ́nkọ́
yoo wà nibi tí awọn eniyan
ti ní lati wadii ohun tí ó ṣẹlẹ nikẹhin kò kàn
jẹ́ otitọ rara. Gbogbo eniyan ni yoo
kiyesi i pẹlu ìṣíde alárinrin yii.
Oluṣọ-agutan Anderson: Ootọ gan an ni ẹ sọ.
Ninu iwe Ifihan, Ori ikinni, ó wipe "Kiyesi i, o
mbọ̀ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i.
"Ẹ kiyesi i pé "mbọ̀" jẹ nnkan tí ó
nṣẹlẹ lọwọ lọwọ. Iyen ni igba tí ó bá tún wá. Ó
mbọ̀ ninu awọsanma gbogbo oju ni yoo sì rí
i. Ó yéni yekeyeke. Sí awọn tí a kò gbala eyi
yoo ṣẹru bawọn doju ikú. Bibeli
wipe nigba tí wọ́n bá rí i tí ó mbọ̀ ninu awọsanma,
wọn yoo maa pohun rere ẹkun, wọn yoo
maa sọkun, ẹru yoo bà wọ́n doju iku. Ṣugbọn fun awa tí
a nwọna fun ifarahan rẹ̀, ara wa yoo yá gágá, inu wa yoo dun, yoo
sì jẹ́ imọlara iyanu lati mọ̀ pé oun niyi.
Abala Ikẹtala - Ìkádìí
Oluṣọ-agutan Jimenez: emi funra mi nfẹ́ kí
fanran yii yọri sí rere. Ng ó fẹ́ kí fanran yii
lè wulo fun Ọlọrun lati là oju awọn eniyan
sí otitọ. Mo kàn lero pé ó
ṣe pataki tó bẹẹ tí a bá lè pada sinu Bibeli.
mo ranti nigba tí mo wà ní ọ̀dọ́ langba tí mo sì
ndagba, mi ò tilẹ̀ fẹran lati maa kà iwe Ifihan
nitori pé mo kàn sá rò pé
Kò lè yé mi abi pé gbogbo igba tí mo bá ti nkà
nnkan kan, mo maa nbeere boya,
“Ṣé nitootọ ni ó sọ bẹyẹn? Ṣé nitootọ itumọ
rẹ̀ niyẹn?” nigba tí mo lè kẹkọ̀ọ́ nipa
otitọ nipa igbasoke, nṣe ni ó kàn ṣí iwe
mimọ silẹ fun mi. Mo nifẹ̀ẹ́ lati maa kà iwe
Ifihan nisisiyi. Bi mo ti nlọ ninu rẹ̀, ó kàn
sá nmu ọgbọn wá tó bẹẹ. mo sá lero pe
tí a bá lè kàn sí ẹgbẹ Kristiani nibẹ yẹn,
sí ẹgbẹ alakatakiti ẹsìn,
sí ẹgbẹ Onitẹbọmi nibẹ yẹn, tí a sì lè là oju
wọn sí ọ̀ràn yii, a jẹ́ wipe
boya yoo mú ifẹ ọrọ Ọlọrun wá ati isọji ọrọ Ọlọrun ati
iṣoji kíkọ́ ọrọ Ọlọrun pada sori awọn aga iwaasu
orilẹ-ede wa, nitootọ a sì lère
rí i kí iṣẹ́ nla di ṣíṣe fun Ọlọrun.
Oluṣọ-agutan Anderson: Idi tí a fi ṣe fanran
yii kì íṣe lati ṣe aṣelékè abi lati
sá tọ́ka sí aṣìṣe ẹnikan tí ero rẹ̀ nipa asọtẹlẹ
Bibeli yatọ diẹ sí tiwa. Iyẹn
kọ́ ni koko naa. Awọn iṣẹlẹ yii jẹ́ iṣẹlẹ otitọ
tí yoo waye. bibeli nsọ fun wa pé
ijọba agbaye kan ṣoṣo YOO wà. Ẹsìn agbaye
kan ṣoṣo YOO wà. Owó ìna kan ṣoṣo
fun gbogbo agbaye yoo wa. Eyi kì íṣe ero ọtẹ lasan
tí awọn eniyan lè fi ọwọ rọ́ sẹyin. Awọn iṣẹlẹ yii
yoo ṣẹlẹ nitootọ. A ó pa awọn eniyan. A ó pa
awọn eniyan ní yanturu. Ìyan yoo
wà. Ajakalẹ arun yoo wà. Inunibini yoo wa. Yoo
yatọ sí ohun yoowu ti aye yii ti là kọja rí tí ó
sì jẹ́ pé awọn Kristiani kò
mura silẹ fun u rara. Nitori pe wọn ti gbagbọ
ninu itan àtọwọ́-dọ́wọ́ ti igbasoke
tí ó ṣaaju ipọnju. Mo gbagbọ ninu igbasoke.
Ikọni Bibeli ni. Ṣugbọn igbasoke nwaye
LẸYIN ipọnju.
Oluṣọ-agutan Jimenez: Ẹ nsọ pé, “Oluṣọ-agutan Jimenez,
kí ló dé tí eyi fi ṣe pataki?” Idi tí ó fi ṣe pataki niyi.
Igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju jẹ́ ikọni tí mo gbagbọ
pé kò fi bẹẹ ṣe pataki
nipa ohun tí a ṣe. Nitori pé ohun yoowu kí ó jẹ́, boya mo
maa fi ọwọ rọrí kú gẹgẹ bí arugbo
abi ng ó kàn là aye kọja, tí ng ó maa lò awọn aaye
isinmi mi, tí ng ó maa dokowo ninu owó mi,
tí ng ó maa gbadun, tí ó sì di ọjọ kan tí ng ó kàn poora,
kí nnkan buburu yoowu tó ṣẹlẹ.
Ikọni tí a nkọ́ ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan
ni mo gbagbọ pé ó jẹ́ kí á ti
ya ọlẹ pupọ tí a si ní itẹlọrun pupọ ninu ẹsìn
kristiẹni wa. A ní lati kede ihinrere. a ni lati jade
sita nibẹ yẹn. A ni lati kọ́ awọn eniyan lẹkọọ
kí a sì sọ fun wọn pé, Ẹ wò ó, inunibini mbọ̀.
Ẹ lọ sí aaye isinmi ranpẹ yin kí ẹ sì ṣe ohun
gbogbo tí ẹ fẹ́ ṣe, ṣugbọn ó sàn
kí ẹ fun ọkunrin ti inú yín lókun. Ó sàn kí ẹ mú
Bibeli yin wọle. Ó sàn kí ẹ bẹrẹ sí í kẹkọọ
nipa Bibeli. Ó sàn kí ẹ bẹrẹ sí í bá Ọlọrun rin kí
ẹ sì mọ̀ Ọlọrun. Ó sàn kí ẹ bẹrẹ sí í kà
Bibeli. nitori pé ọjọ kan lè wà nigba tí wọn
yoo mú Bibeli yii kuro lọdọ yin," Lonii a
fun wa ní ẹkunrẹrẹ ominira lati pejọ pọ̀, lati ṣí
Bibeli, lati waasu ọrọ naa, ṣugbọn
ọjọ kan lè dé tí ikórajọpọ yii yoo lodi sí ofin,
nigba ti Bibeli yii yoo
lodi sí ofin, nigba ti ohun tí a nṣe nisisiyi yoo
lodi si ofin. Tí a ó bá ní ọkàn
fun Ọlọrun, a ó gbé ihinrere Jesu Kristi tọ̀ awọn eniyan lọ.
Oluṣọ-agutan Anderson: Gbogbo iyẹn lati sọ
eyi. awọn nnkan tí mo ti waasu rẹ̀ fun yin yii lè ti
má ti bí yin ninu. Nigba tí inunibini bá dé,
nigba tí a bá ní kí ẹ gba ami ẹranko naa
sí ọwọ ọtun yin abí iwaju ori yin, ẹ ó ranti
iwaasu yii. Boya kò ní í ṣẹlẹ
loju ẹmi wa, boya yoo ṣẹlẹ.ṣugbọn tí ó bá
rí bẹẹ, ẹ ó ranti iwaasu yii. Iyẹn
ni idí ti Jesu fi sọ ọ́ idí sì niyẹn tí mo fi nsọ ọ́.
Ẹ nṣo pé, "Ṣé eyi wà lati dayafo wá ni?" Rara,
Bibeli nsọ pé ninu aye ẹ ó ní ipọnju. Ẹru bà yin nipa rẹ̀? Rara. Ó sọ
pé ninu aye ẹ ó ní ipọnju, ṣugbọn ẹ tujuka,
"Mo ti ṣẹgun aye."
Ẹ tujuka. Ẹ maṣe daamu. Ẹ maṣe binu jade kuro
nibi iwaasu naa pe, "Ọkunrin yii, ṣé ara rẹ dá?
Orí bibẹ? Tuubu? Iyàn? Ajakalẹ arun?
Ṣé ara rẹ dá?" Rara, ẹ tujuka. Ó
ti bori aye. Boya yoo ṣẹlẹ loju ẹmi wa,
boya kò ní ṣẹlẹ, Ṣugbọn eyi o
wù kí ó jẹ́, bí Ọlọrun bá wà fun wa, tani ó lè
kọju ija sí wa? Ẹ yin Jesu Kristi. Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀ orí wa ba
kí a sì gbadura. Baba, a dupẹ́ lọwọ rẹ tó bẹẹ
fun otitọ tí ó yè kooro ninu ọrọ rẹ
a sì dupẹ lọwọ rẹ tó bẹẹ fun fifun wa ni Ẹmi
Mimọ rẹ lati tọ́ wa. mbá má ti
lè fi inu rò nnkan yii funra mi pẹlu gbogbo
igbọ́kúgbọ́ tí mo ngbọ lati ọdọ awọn eniyan yii
tí wọn nparọ́ fun emi ati Scofield, ṣugbọn a
dupẹ lọwọ rẹ fun Ẹmi Mimọ pé ninu yará yẹn fun ọpọlọpọ
ọdun ni wọ́n fi nla gbogbo iyẹn kọja tí wọ́n sì
nfi koko ọrọ mẹta yii sinu ọkàn mi. Awọn koko ọrọ
ọrọ tí ó ṣẹse wọnu ọkan mi lati inu iwe Matteu ori
gẹgẹ bí ọdọmọkunrin ọdun mejila ni: LẸ́YÌN ÌPỌ́NJÚ NÁÀ.
Mo gbà á ladura pé awọn koko ọrọ yẹn yoo wọle
sinu ọkàn àti ọpọlọ ẹnikọọkan tí ó wà nihin
ní àṣálẹ́ yii. A nifẹẹ yin a sì dupẹ lọwọ yin ní orukọ
Jesu ni a sì gbadura, amin. Ẹ jẹ́ kí a kọrin
ranpẹ́ kan kí a tó maa lọ.
-
ORIN: Ó Dara Fun Ọkàn Mi
Oluṣọ-agutan Jimenez: Aayo orin mi niyi
a ó sì kọ aayo ẹsẹ mi
nisisiyi. Ọpọlọpọ igba tí ẹ bá nkọ awọn
orin, nṣe ni ẹ kàn nbẹrẹ orin. Ẹ kì í
ronu nipa awọn ọrọ naa ati ohun tí ó nsọ.
Ẹ wò ẹsẹ ikẹta orin yii.
Ó nsọ pé, “Ẹṣẹ mi, ah, ayọ pipé ti ironu
ologo." Ẹ nsọ pé, "Ó dara, kínni
ayọ pipé nipa rironu nipa ẹsẹ mi?" Ṣugbọn
ẹ wò ohun tí ó nsọ. Ó nsọ pé, Ó
kàn á mọ́ agbelebuu tí mi ò sì rù ú mọ́.
Ọkàn mi, yin Oluwa, yin Oluwa.”
Ẹ sá tilẹ ronu nipa awọn ọrọ yẹn bí ẹ ti nkọ
wọ́n lórin. Ẹ kọ ọ́ soke, a ó sì ṣetan fun
iwaasu yii.
Ẹṣẹ mi, ah ayọ pipé ti ironu ologo yii! Ẹsẹ mi,
kí íṣe abala kan ṣugbọn gbogbo rẹ̀,
Ni a kàn mọ agbelebuu, mi ò sì rù ú mọ.
Ọkàn mi, yin Oluwa, yin Oluwa!
Ó dara fun ọkan mi, Ó dara, ó dara, fun ọkan mi.
Oluwa, sì mú ọjọ tí igbagbọ mi yoo hàn yá kánkán,
Kí a ká awọsanma bí ẹni ká iwé; Ipè yoo tun dun, Oluwa yoo sì
sọkalẹ wá. Ani nitori naa, ó dara fun ọkan mi.
Ó dara, fun ọkàn mi. Ó dara, ó dara, fun ọkàn mi.
-
Bibeli diidi yè kooro nipa ọrọ igbala. Kò dá lori
bí ó ti jẹ́ ẹni rere tó. Ọpọlọpọ eniyan
nrò pé awọn jẹ́ ẹni rere gan an pé awọn yoo sì dé
ọrun nitori pé wọ́n jẹ́ ẹni rere gan an.
Ṣugbọn Bibeli wipe, Gbogbo eniyan li o sa ti
ṣẹ ti wọn si ti kuna ogo Ọlọrun."
Bibeli wipe, “Kò si ẹnikan ti iṣe ododo,
ko si ẹnikan." Emi ki iṣe olododo.
Ẹyin ki iṣe olododo. Tí ó bá jẹ́ pé ododo
wa ni yoo gbé wa dé ọrun, kò
sí ẹnikan ninu wa ti yoo lọ.
. Gbà pé ẹlẹṣẹ ni ọ.
Bibeli tilẹ sọ ninu iwe Ifihan, ori ikọkanlelogun, ẹsẹ ikẹjọ pé:
(Ifihan :) Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́,
ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè,
ati oṣó, ati abọriṣa, ati [ẹ fi eti silẹ̀ si eyi] -
GBOGBO eke, ni yio ní ipa tiwọn
ninu adagun ina ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.
Mo ti parọ́ rí. Gbogbo eniyan ni ó ti parọ́ rí.
gbogbo wa ti ṣẹ̀, a ti ṣe nnkan
tí ó buru jù irọ pipa. Ẹ jẹ́ kí a sọ otitọ.
Ọrun apaadi tọ́ sí gbogbo wa.
. Dá ijiya fun ẹsẹ mọ̀.
Ṣugbọn Bibeli wipe:
(Romu :) Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa
hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi
kú fun wa.
Nitori naa, Jesu Kristi, nitori pé Ó fẹ́ wa, Ó wá sí aye
yii. bibeli wipe Ó jẹ́ Ọlọrun tí a fihan
ninu ara. Ọlọrun pilẹ̀ gbé awọ̀ eniyan wọ̀.
Ó gbé igbe-aye ailẹṣẹ. Kò
dẹṣẹ kankan. Nitootọ, wọ́n nà Á tí wọ́n sì tutọ́ sí
i lara tí wọ́n sì kàn á mọ́ agbelebuu.
Bibeli wipe nigba tí Ó wà lori agbelebuu yẹn,
Òun funra Rẹ̀ rù ẹsẹ wa lara Rẹ̀ lori
igi naa. Nitori naa, gbogbo ẹṣẹ tí ẹ ti ṣẹ̀ rí, ẹṣẹ
yoowu ti mo ti ṣẹ rí, nṣẹ ni ó dabi ẹni pe Jesu
ni ó dá a. A njẹ ẹ́ niya nitori ẹṣẹ wa.
Nitootọ, wọ́n gbé oku Rẹ̀ nigba ti Ó
kú wọ́n sì sin Í sinu iboji, ẹmi Rẹ̀ sì lọ
sí ipo-oku fun ọ̀sán mẹta ati
oru mẹta (Iṣe :). Lẹyin ọjọ mẹta,
Ó tun jinde kuro ninu okú. Ó fi
iho ọwọ Rẹ̀ han awọn ọmọ ẹyin. Bibeli
diidi yè kooro pé Jesu kú fun
gbogbo eniyan. Ó wipe Ó kú kì iṣe fun ẹṣẹ
wa nikan, ṣugbọn fun ẹṣẹ gbogbo
aye. Ṣugbọn nnkan kan wà tí a gbọdọ ṣe ki
a lè di ẹni igbala. Bibeli ní ibeere yẹn
ninu iwe Iṣe Awọn Aposteli, ori ikẹrindinlogun pé:
Kinni kí emi ó ṣe kí nlè là? Wọn wi pe:
(Iṣe :-) "Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a
o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu.”
Oun sì niyẹn. Kò sọ pe, Darapọ mọ́ ijọ kan a ó
sì gbà ọ́ là. Ṣe iribọmi
(Johannu :) Nitori Ọlọrun fẹ araye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ̀ kan ṣoṣo funni, ki ẹni
ti o ba gba a gbọ ma ba ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.
Ainipẹkun ntumọ̀ sí ainipẹkun. Ó ntumọ̀ sí ayeraye.
Jesu wipe:
(Johannu :) Emi si fun wọn ni iye ainipẹkun; nwọn ki o si ṣegbe lailai; ko si
si ẹniti o le ja wọn kuro li ọwọ mi.
Bibeli nsọ ninu iwe Johannu ::
(Johannu :) Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin,
Ẹniti o ba gba mi gbọ, o ni iye ainipẹkun.
Nitori naa, tí ẹ ba gbà Jesu Kristi gbọ́, Bibeli yẹn
nsọ pé ẹ ni iye ainipẹkun. Ẹ
ó yè titi aye. Ẹ kò lè padanu igbala yin. Ó jẹ́ ti
ainipẹkun. Ó jẹ́ ti ayeraye.
Ní kete tí ẹ bá ti di ẹni igbala, ni kete tí ẹ ba ti gba A
gbọ́, a ti gba yin là titi lae ohun yoowu,
ki o ṣẹlẹ ẹ kò lè padanu igbala yin laelae. bi mo tilẹ lọ dẹṣẹ buburu kan,
Ọlọrun yoo fi iyà rẹ̀ jẹ mi ni aye yii. Ti mo ba lọ pa
ẹnikan lonii, Ọlọrun
yoo rí i daju pé mo jẹ iya rẹ̀. Ng ó lọ sí ẹ̀wọ̀n abi eyi ti ó buru ju bẹẹ abi kí n
gbà idajọ ikú, abi ohun yoowu ti aye yii nfi jẹ mi niya.
Ọlọrun yoo rí i daju
pé ng ó jẹ iya abi ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn mi ò ní lọ si ọrun
apaadi. Kò sí nnkan
ti mo lè ṣe lati lọ si ọrun apaadi nitori pé a ti gba mi là. ti
mo ba si lọ si ọrun apaadi, Ọlọrun ṣèké, nitori pe Ó
ṣeleri pé ẹnikẹni tí ó bá gbà Á gbọ́ ni iye ainipẹkun. Ó wipe:
(Johannu :) Ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gba mi
gbọ, ki yio ku lailai.
Idi niyẹn ti a fi ri apẹẹrẹ awọn eniyan ninu Bibeli ti
wọn ṣe ohun ti ó buru jọjọ
sibẹ, wọ́n dé ọ̀run. Bawo? Nitori pe wọn jẹ ẹni rere
to bẹẹ? Rara. Ó rí bẹẹ nitori pe
wọn gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ. a dari ẹṣẹ wọn jì.
Awọn eniyan miran ti wọn ti le gbé
igbe aye didara loju awọn eniyan, abi boya wọn tilẹ
gbé igbe aye didara nitootọ, ṣugbọn
wọn kò gba Kristi gbọ, wọn yoo ni lati lọ si ọ̀run
apaadi lati jiya fun
ẹṣẹ wọn.
. Ẹ fi ọkàn tán Kristi nikan gẹgẹ bi olugbala yin.
Ẹ sì jẹ́ ki ng sá pa ironu yii dé, nnkan kan ti
mo fẹ rí i daju lati mú
jade lonii. Ibeere kan wà tí ọkan lara awọn ọmọ
ẹyin Jesu beere. Ibeere yẹn
niyi: Ṣé awọn eniyan diẹ ni a gba? Ibeere daradara
niyẹn, abi? Ṣe a gba awọn eniyan ti o pọju la?
Abi awọn eniyan diẹ ni a gbala? Tani ó nronu nihin
pé awọn eniyan ti o pọju ni aye yii ni yoo lọ sí
ọ̀run? Ẹ fi inu rò ohun ti idahun naa jẹ́? Ó sọ
ninu iwe matteu, ori keje pe:
(Matteu :-) Ẹ ba ẹnu-ọna hiha wọle;
gboro li ẹnu-ọna na, ati onibu li
oju ọna na, ti o lọ sibi iparun; ọpọlọpọ li awọn
ẹniti mba ibẹ wọle. Nitori pe hiha
ni ẹnu-ọna na, ati toro li oju-ọna na, ti o lọ si
ibi iye, diẹ li awọn ẹniti o nrin
i.
Nigba naa ni ó tẹ siwaju lati sọ eyi:
(Matteu :-) Ki iṣe gbogbo ẹniti npe
mi li Oluwa, Oluwa, , ni yio wọ
ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti ɓaba mi ti mbẹ
li ọrun. Ọpọlọpọ enia ni yio
wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko
ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ
ki a fi le awọn ẹmi eṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe
ọpọ iṣẹ iyanu nla? Nigbana li emi o si wi
fun wọn pe, Emi ko mọ yin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹṣẹ.
Ṣaaju ohun gbogbo, awọn eniyan ti ó pọ julo ninu aye yii
kò tilẹ sọ pé awọn gba jesu gbọ. A dupẹ,
awọn ti ó pọ julọ ninu yara ikẹkọọ yii nsọ pé awọn gba Jesu
gbọ. Ṣugbọn awọn ti ó pọ julọ ninu aye kò
maa sọ pé awọn gba Jesu gbọ. Ṣugbọn Ọlọrun kilọ pé laaarin
awọn ti wọ́n sọ pé awọn gba
Jesu gbọ, lara awọn ti wọn npe e ni Oluwa paapaa,
ọpọ ni yoo maa wi pe, “A ṣe
gbogbo iṣẹ iyanu yii. Ki lo de ti a ko gba wa là?"
Oun yoo wi pe, "Ẹ kuro lọdọ
mi, emi ko mọ yin ri.”Eyi yoo ri bẹẹ nitori pe igbala
kì i ṣe nipa iṣẹ. Ti ẹ bá sì
gbarale iṣẹ ọwọ yin lati gba yin la, ti ẹ ba ro pe ẹ
nlọ si ọrun nitori pe ẹ ti
ṣe iribọmi, abi ẹ lero pe “Ó dara, mo lero pe ẹ ni lati
gbe igbe-aye rere. Mo lero
pe ẹ ni lati pa awọn ofin mọ lati di ẹni igbala. Mo
lero pe ẹ ni lati lọ si ile ijọsin. Mo lero pe
ẹ ni lati yipada kuro ninu ẹṣẹ yin…”
Ti ẹ ba ngbarale iṣẹ yin, Jesu
yoo sọ fun yin lọjọ kan pe, “Ẹ kuro lọdọ mi,
emi ko mọ yin ri." Ẹ ni lati
fi gbogbo igbagbọ yin sinu ohun ti o ṣe. Ẹ ni lati
fi igbagbọ yin sinu ohun ti Jesu ṣe ni
ori agbelebuu, nigba ti ó kú fun yin ti a sì sin ín ti
ó si tun pada jinde. Iyẹn ni iwe irinna yin
sí ọ̀run. Ti ẹ ba ngbarale pé, “Ah, mo nlọ si ọ̀run nitori pe mo jẹ́
Kristiẹni rere to bẹẹ ti mo sì nṣe gbogbo nnkan iyanu wọnyi,”
oun yoo wipe, “Ẹ kuro lọdọ mi.”
Ẹ si kiyesi ohun ti Ó sọ pé: “Ẹ kuro lọdọ mi,
emi kò mọ yin RI.” Ki i ṣe pe, “Mo mọ yin
tẹlẹ.” Nitori pe bi O ba ti le mọ yin, bi mo ti
mẹnuba tẹlẹ, ti ayeraye ni. Titi lae ni.
Bi Ó ba ti le mọ yin, a ti gba yin la titi laelae.
Ṣugbọn Oun yoo wi pe, Ẹ kuro lọdọ mi,
Emi ko mọ yin ri.” Bi ẹ ba lọ si ọ̀run apaadi,
a jẹ́ nitori pé ko mọ yin ri ni. Bi Ó ba ti lè mọ yin,
Ó ti mọ yin niyẹn. Nṣe ni ó dabi ẹni pe awọn ọmọ
mi yoo maa jẹ ọmọ mi sibẹ. nigba ti ẹ bá
di atunbi, nigba ti ẹ ba jẹ ọmọ Rẹ, ẹ ó maa jẹ ọmọ Rẹ sibẹ. Ẹ le jẹ
ẹni ti ó nba orukọ ẹbi jẹ. Ẹ le jẹ ẹni ti Ọlọrun
nba wi gidigidi laye yii.
Ẹ lè ṣe aye yin baṣu-baṣu nihin, ṣugbọn ẹ
kò lè ṣe iyẹn bẹẹ. a gba yin la.
Àṣepari ni. nitori naa, eyi ni nnkan pataki ti mo fẹ fun yin nipa
igba ikẹyin. A ṣì tun ni iṣẹju diẹ fun ibeere nipa igbala abi nipa
igba ikẹyin.
Jesu mi Ọ̀wọ́n, mo mọ pe ẹlẹṣẹ ni mi. Mo mọ pe ó tọ́
ki nlọ si ọrun apaadi, ṣugbọn mo gbagbọ
pé o kú fun mi lori agbelebuu ti o si pada jinde.
Jọwọ gba mi la nisisiyi ni agbatan ki o si fun mi ni
iye ainipẹkun. Iwọ nikan ni mo ngbarale, Jesu. Amin.