"New World Order Bible Versions" with Yoruba subtitles

Watch Video

October 24, 2015

Mo gbàgbọ́ pe Eṣu fẹ ṣakoso ìjọ.

Mo gbàgbọ́ pe Eṣu fẹ ṣakoso lori ìjọ yii...

... ní ọkọọkan èjèejì.

-Anfaani n bẹ niwaju wa, lati ṣe agbekalẹ ààtò ayè-dọtun

Fun arawa ati fun àwọn ìran tó n bọ̀.

-Ti ferese rẹ.

Pada lọ sinu ilé rẹ.

-Pada sílé nisisiyii! -Mo wà ninu ilé.

-Anfaani gidi n bẹ fun wa lati ṣe ààtò ayé-dọ̀tun yii,...

...ààtò kan tí Àjọ àwọn Orilẹ-ede Àgbáyé olórúkọ rere...

-...àwọn ọta rọ́bà, àwọn ibọn ẹran-ipá...

-... le lo fun ojuṣe ìpẹ̀tùsíjà rẹ̀ lati mú ileri ati àfojúsùn...

...àwọn oludasilẹ àjọ U.N wá sí ìmúṣẹ.

-Lẹyin ọdun Aarẹ Bush wi pe - ó sì jẹ́ awẹ gbolohun kan tí mo maa ń sáába lò

funrami - pe a nílò ààtò ayé-dọ̀tun kan.

Sugbọn dípò eyi ó dabi pe ọpọlọpọ rúkèrúdò ni a ní.

Ó ti pẹ tó ti n bọ̀ lọna.

Nitori ohun ti a ṣe ni ọjọ òní yii ní iṣẹju lọ́wọ́lọ́wọ́ yii

ayipada ti dé sí ilẹ Amẹrika.

-Loniii, Aarẹ Obama ati Olootu ijọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Gordon n

pè fun ààtò ayé-dọ̀tun lati kojú wahala wa ètò

ìsúná wa lágbàáyé.

-Iṣẹ tó yẹ fun ṣíṣe bayii ni lati ṣagbekalẹ ni pàtó

ààtò ayé-dọ̀tun kan.

-Ojúṣe rẹ̀ yoo jẹ́ lati ṣeto ìlànà kan tó kárí fun ilẹ Amẹrika

ni asiko yii nigba ti, ó jẹ́ pé nítootọ, ààtò ayé-dọ̀tun kan ṣe e da silẹ.

Anfaani nla leyi jẹ́.

-O sọrọ nipa àlàyé ààtò ayé-dọ̀tun naa gẹgẹ bí o ti rí i sí, ànì

gẹgẹ bí o ti jẹ́ olùjọ́sìn-Lúsíférì. -Bẹẹ ni

-Bawo lo ṣe mọ̀?

-Awọn iwadii mi jẹ́ ki n wo ẹ̀yìn owó dọla Amẹrika.

Mo si ri àwọn èdìdí abàmì yii ni ori dọ́là naa. Wọn jẹ́ èdìdí Iluminati

tí í ṣe ẹgbẹ-okunkun ti wọn dá silẹ ni ọdun

lati ọwọ ọkunrin kan ti n jẹ́ Adam Weishaupt.

Lẹyin dọ́là naa ni ẹ ti maa rí èdìdí naa ní

apá-osi rẹ̀, tí oju kan tí n bẹ ninu aworan onigun-mẹta kan. Oju Horusi

inu itan Íjíbítì ní í ṣe, tí a mọ̀ sí oju Lusiferi tabi Satani ní bayii.

Awọn ọ̀rọ̀ meji kan nbẹ loke rẹ̀, "ANNUIT COEPTIS", tó tumọ si

"Kíkéde idasilẹ",

tí "NOVUS ORDO SECLORUM" sì n bẹ ní isalẹ rẹ̀.

-Tí a sì rí nibi oke èdìdí nla ti ilẹ Amẹrika;

"NOVUS ORDO SECLORUM": Ààtò Ọ̀tun.

Ibeere naa tí ó yẹ kí àwọn eniyan beere ni, "Kini aworan pírámídì ilẹ Íjíbítì

n ṣe ni ẹ̀yìn owó dọ́là Amẹrika?

Kini àṣepọ̀ tí nbẹ laarin ilẹ Amẹrika ati ilẹ Íjíbítì?"

Idahun sí eyi ni pe: Ko si nnkankan yatọ sí ti ẹgbẹ okunkun.

Nipa bayii ni a fi mọ̀ pe eto lusiferi kan ni a n kojú yii, tí àwọn eniyan sì

nílò lati mọ̀ pe orisa Ẹgbẹ Lọ́ọ̀jì yoo ṣe ìdarí gbogbo ayé lọ sí

èrèdí àrà-ọ̀tọ̀ kan eyi tí a tori rẹ̀ tẹ ilẹ Amẹrika dó

eyi ti yoo darí gbogbo ayé lọ si inu agbekalẹ

Iṣejọba ayé-dọ̀kan, ẹ̀sìn ayé-dọ̀kan,

ètò ofin ayé-dọ̀kan, ati irufẹ owó ayè-dọkan

tí Bibeli pe ni àmì ti ẹranko naa.

-...dajudaju, ohun kan tí a mọ̀ sì òdodo ni,

pé ayipada yoo wà lati ààtò ogbó

sí ààtò ọ̀tun, eyi ti Satani funrarẹ̀ yoo jẹ́ adarí.

Eyi ni ohun ti àrokò naa n tọka si

eyi naa sì ni ohun ti a n pe ní Ààtò Ayé-dọ̀tun.

ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu, sọ ní Kọrinti : pe, "Nitorinaa bi ẹnikẹni ba wà

ninu Kristi, o jẹ́ ẹda tuntun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi

ohun gbogbo ti di tuntun. " Sakiyesi bi ẹ̀dà Bibeli Gẹ̀ẹ́sì Tuntun, NEB

ti sọ nipa ẹsẹ yii. Ó wi pe, " Ààto atijọ ti lọ, tí

ààto ọ̀tun sì ti bẹrẹ. " Ìpèdè kannaa ni awọn mejeeji lò.

ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu sọ pe, "Tí ó duro lori jíjẹ ati mímu, ati

orisirisi wíwẹ̀, ati àwọn ilana ifẹkufẹ, ti a fi mu wọn ní tipatipa titi di igba

isatunṣe", tí a bá n sọ nipa ipadabọ Kristi. Sugbọn kíyèsí

bí ẹ̀dà Bibeli NIV ti pè é, "titi di igba ààtò ọ̀tun naa. "Wọn n gba awọn

eniyan láradì silẹ ni. Ni bayii, mo fẹ́ ki o sakiyesi eyi. Ninu Isaya : ti

ẹ̀dà Ọba Jakọbu, Bibeli sọ pe, "Nitorinaa bayii ni OLUWA ỌLỌRUN wi, Wo o, mo fi lelẹ

ni Sioni fun ipilẹ okuta kan, okuta didanwo, okuta iyebiye igun ilé,

ipilẹ to daju". Ṣebi Jesu ni eyi n tọka sí, abi bẹẹ kọ? Mo sì fẹ́ ki o

sakiyesi pe ninu ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu naa wọn n sọ fun ọ pe Jesu

ni okuta igun ilé ti ipilẹ naa. Bayii, nibo ni ipilẹ wà lara

kíkọ́ ilé, ṣé l’oke ni tabi isalẹ rẹ̀?

Isalẹ ló wà, abi bẹẹ kọ? Hẹn?

Nitori naa, nigba ti wọn ba sọ pé Jesu ni okuta igun ilé ti ipilẹ naa,

eyi wa ni isalẹ, abi?

"Fun ẹ̀yin ti ẹ gbàgbọ́ nigbanaa o ṣe iyebiye:"- eyi ni bí ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ṣe sọ ọ́ -

"sugbọn fun àwọn to ṣe aigbọran, okuta kan ti àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ silẹ,

ohun kannaa lo di pataki igun ilé," lẹẹkan si i, lóri ipilẹ ló n sọ.

Sakiyesi pe ẹ̀dà Bibeli NIV pe e ni okuta ìborí.

Wọn n sọ pé Kristi ni àmì naa tí o n rí yii duro fun.

Ko ri bẹẹ o; tani o wá duro fun? Asodisi-kristi ni.

-Mo gbadura pe ẹ maa tara duro, bo ti wu kori, ẹyin ọrẹ mi, pẹlu iwe àrà yii,

àní Ọrọ Ọlọrun yii. Lotitọ, eyi ni ohun ti a nilo lati pada si.

Asiko naa kúrú. Iyapa nla kuro ninu òdodo naa:

Ó ti n ṣẹlẹ o; ó ti wà nibi ní bayii.

-Orukọ mi ni Steven Anderson, oluṣọ-agutan fun Ijọ Faithful Word Baptist

ni ilu Tempe, Arisọna. Ijọ wa jẹ́ ti olùlò Bibeli ti ẹ̀dà Ọba Jakọbu nikan; ọpọ

àwọn eniyan kò loye idi rẹ̀. Sugbọn eredi fíìmù yii ni lati

safihan iyatọ tó lápẹ́ẹrẹ laarin ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu

ati gbogbo àwọn ẹ̀dà miran.

-Orukọ mi ni Roger Jimenez. Emi mi oluṣọ-agutan fun Ijọ Verity Baptist

ni ilu Sakramento, California, idi naa tí inu mi sì fi dun lati kópa

ninu fíìmù yii ni nitori Ọrọ Ọlọrun wà labẹ àtakò lode oni

ti a sì nilo lati mú iduro ṣinṣin fun Bibeli naa ki a le dojukọ

ọ ninu ijakadi ti ẹmi.

-Orukọ mi ni Dennis McCain. Emi ni Oluṣọ-agutan ni Ijọ Northside Baptist

ni ilu Modesto, California. Mo ti nṣe Oluṣọ-agutan nibi fun ọdun mẹrindinlogun

Mo sì tún ti jẹ́ ojiṣẹ Ọlọrun tí n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ajiyinrere adájọsílẹ̀ fun

bí i ogoji ọdun.

-Ni bayii, ète kan wa lonii, ti o jẹ́ ète Satani lati ṣe ayipada

Bibeli. Ọpọlọpọ eniyan rò pe, "Ó daa bẹẹ, ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu jẹ́

itumọ kan tó-lóòrìn; ó ní ẹwà-èdè ninu. Tí àwọn ẹ̀dà yooku sì jẹ́

ọ̀fọ́ọ̀rọ̀. Boya wọn kò tilẹ tumọ dáadáa pàápàá. Sugbọn mo wá lati sọ

fun yin pe ó jinlẹ ju bẹẹ lọ. Ni pato, awọn ẹ̀dà tuntun yii jẹ́

igbiyanju Satani lati ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní báṣubàṣu. Mo maa fihan ọ

pe àwọn iyatọ yii kò ṣèèsì wáyé. Wọn kì í ṣe

Iyatọ tó jẹ́ mọ níwọǹba tabi tí kò já mọ́ nnkankan. Ero mi ni pe, àmọ̀ọ́mọ̀ṣe ni awọn iyatọ yii jẹ́.

Wọn finnufindọ ṣe wọn lati ṣe idibajẹ àwọn ilana pataki kan ti Bibeli n kọ wa ni.

Bibeli sọ fun wa ni Efesu :, "Nitori ijakadi wa kii ṣe ti

ẹranara ati ẹjẹ, Sugbọn lodi si àwọn ijoye, àwọn ọlọla,

àwọn alaṣẹ ibi okunkun aye yii, lodi si àwọn ẹmi

buburu ni àwọn ibi giga. " Awọn eniyan wà ti wọn ní ọpọ

miliọnu ati biliọnu owo dọ́là ti wọn n pète lati ṣagbejade àwọn

Bibeli àdàmọ̀dì, tí wọn sì n ipolowo ọja gbé e larugẹ,

ti wọn n gbe e larugẹ ní àwọn ilé itaja ti yoo tò ó siwaju ati ní gbangba

ọja wọn fun àwọn eniyan lati rí wò, "Bibeli ti ó yẹ ki o maa ka leyi. Pa

ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu tì. Lọ ra tuntun, tó dára ju u lọ, ẹ̀dà tó bojumu ju u lọ."

Laipẹ, mo ṣe ọ̀fìntótó lori ohun tí àwọn ẹ̀dà tó gbajúgbajà lódè oni jẹ́.

Eyi ni àtòkọ àwọn tó wa lórí igbà bayii. Mo ṣayẹwo eyi pẹlu àwọn orisirisi

Eniyan, tí ó sì jẹ pe awọn ẹ̀dà marun un kan naa nigbogbo wọn darukọ. Bibeli

akọkọ ti òde oni kì í ṣe ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu (KJV). Ẹ̀da Bibeli

Kárí-ayé Tuntun (NIV) ni. Ekeji ni ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu (KJV). Ẹkẹta,

ni Ẹ̀dà Igbe-aye Ọ̀tun (NLT). Ẹkẹrin ni ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun (NKJV), tí ẹkarun,

jẹ́ Ẹ̀dà Bibeli Gẹ̀ẹ́sì Pípé (ESV). Iyatọ diẹdiẹ ni mo kàn rí laarin

Bí wọn ṣe tò awọn ẹ̀dà naa ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé, sugbọn gbogbo wọn ló ní márààrún ninu.

-Ọpọ eniyan ko mọ̀ pe ọ̀gọ̀ọ̀rọ ẹ̀dà Bibeli ní n bẹ ogorun lorisirisi, tí ó

sì jẹ pe a kò ní àkókò lati ka gbogbo wọn ni ọkọọkan.

-Ó mọgbọn dani pe kí a kan kọju mọ́ àwọn ẹ̀sà Bibeli naa

tí wọn ti di gbajú-gbajà. Odindi ẹsẹ Bibeli mẹrindinlogun ní kò sí ninu ẹ̀dà NIV mọ́

lati inu majẹmu tuntun. Ànì tí wọn yọ wọn kuro patapata, ki a tó maa sọ

nipa ẹgbẹẹgbẹrun ayipada, ẹsẹ Bibeli mẹrindinlogun ni kò si nibẹ

rara. Mateu : – kò sí nibẹ. Matteu : - kò sí nibẹ. Iṣe Aposteli : - ẹsẹ yii

ko si ninu ẹ̀dà NIV, ko si ninu ẹ̀dà ESV, kosi ninu ẹ̀dà Igbe-aye Ọ̀tun (NLT)...

Wọn kò sí nibẹ rara!

Iṣe awọn Aposteli :, ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu: "Bi wọn ti nlọ lọna,

wọn de ibi omi kan: iwẹfa naa sì wi pe, « Wo o, omi niyii;

kinni o dà mi duro lati baptisi? Filippi"- ajere-ọkàn naa sì-

"wi pe, ‘’Bi iwọ ba gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè baptisi rẹ.’’

Tori bẹẹ, iwẹfa naa – tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ - wi pe, "Kini idiwọ fun mi,

Kini o dà mi duro lati baptisi?" Filippi, ajèrè-ọkàn naa,

sọ pe, "Bi iwọ ba gbàgbọ́ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, o le ṣe bẹẹ,

Tí – iwẹfa naa – sì "dahun wi pe, mo gbàgbọ́ pe Jesu Kristi

ni Ọmọ Ọlọrun. " Kini o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ si iwẹfa naa? Ó rí igbala.

Kinni idi? Bi o ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu ní Oluwa pẹlu gbàgbọ́ ninu

ọkàn rẹ pe Ọlọrun ti ji i dide lati ipo oku, a o gba ọ la.

Ó gbàgbọ́ ninu ọkàn rẹ̀. Ó jẹwọ pẹlu ẹnu rẹ̀. Ò sì rí igbala.

Tori bẹẹ, kinni wọn maa ṣe? ẹsẹ :

"Ó sì paṣẹ kí kẹkẹ duro jẹ́: àwọn mejeeji sì sọkalẹ lọ sinu

omi, ati Filippi ati iwẹfa; ó sì baptisi rẹ̀."

Ẹsẹ sọ: Kini o n dà mi duro lati baptisi?

Ẹsẹ : Niwọn igba ti o ba gbàgbọ́ pe o le ṣe iribọmi

Òun fi ẹnu rẹ̀ jẹwọ, ó gbàgbọ́ ninu ọkàn rẹ̀;

Ẹsẹ : wọn ṣe iribọmi fun un. Amin.

Kini ẹ̀dà Bibeli Kárí-ayé Tuntun, NIV sọ?

"Bi wọn ṣe nlọ ni ọna, wọn de ibi ti omi wà, iwẹfa naa sì wi pe,

'Wo, omi niyi. Kini o le ṣe idiwọ siṣe iribọmi fun mi?'

Ó sì paṣẹ lati da kẹkẹ ẹṣin naa duro. Nigba naa ni Filipi ati iwẹfa naa sọkalẹ

sinu omi naa tí Filipi sì ṣe iribọmi fun un." Njẹ o n fi ọkàn bá

ohun tó n ṣẹlẹ lọ bayii? Kini ó sọnu nibi?

Emi ò mọ̀ boya o ṣakiyesi. Gbogbo ẹsẹ kò sí nibẹ.

Gẹgẹ bi ẹ̀dà Bibeli Kárí-ayé Tuntun ti kọ ọ́, wọn n lọ lọna naa.

Òun wi pe, "Kini o n ṣe idiwọ fun mi lati ṣe iribọmi?

Gẹgẹ bi ó ti wà ninu ẹ̀dà NIV, kosi nnkankan! Jẹ ki a kàn ṣe iribọmi fun ọ.

Kini kò sí níbí? Gbagbọ ninu Jesu Kristi!

Kini kò sí níbí? Ihinrere ni.

Kini kò sí níbí? Kilode ti àwọn Bibeli yii n tako Jesu Kristi?

Kò tilẹ ye mi rara.

Sugbọn o maa ye ọ bí o bá mọ̀ pe Satani ló wà lẹhin rẹ̀.

-Sugbọn ki i kàn ṣe pe wọn fa àwọn ẹsẹ mẹrindinlogun yii yọ ninu ẹ̀dà NIV,

Wọn tun fi arokọ sori awọn ẹsẹ mẹtadinlọgbọn miran, pe àwọn ẹsẹ yii le má

wà ninu Bibeli ìwásẹ̀, tí wọn sì n jẹ́ ki o maa ní iyèméjì si Ọrọ Ọlọrun.

Awọn ẹsẹ bi i Maaku :. E lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì waasu ihinrere fun

gbogbo ẹ̀dà. Awọn ẹsẹ bi i "Baba, dariji wọn; nitori ti wọn kò mọ̀

ohun ti wọn n ṣe.’’ Wọn kò yọ àwọn ẹsẹ bí eyi kuro, Sugbọn wọn ti fi arokọ tí ó

sọ ọ́ di yẹpẹrẹ ati ailẹsẹnilẹ sinu ọkàn ẹni tí n kà á ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wi pe, Bó ṣe wà yii,

àwọn ẹsẹ yii gan an lè má wà ninu Bibeli ìwásẹ̀ pàápàá. Eyi kò kuku ní

aṣẹ kankan jàre. " A gbàgbọ́ pe Jesu Kristi jẹ́ Ọlọrun ní ti ẹran ara.

Eyi jẹ́ ohun kan tí àwọn ẹ̀dà ode oni yii maa n yipada, tí wọn sì n takò.

Jẹ́ ki n fun ọ ni àwọn apẹẹrẹ kan. Johannu :; "Nitori àwọn mẹta

ni n ṣàkọsílẹ̀ ní ọ̀run, Baba, Ọrọ, ati Ẹmi Mimọ:

tí àwọn mẹta yii sì jẹ́ ọ̀kan." Nibi yii ni a ti ri ọ̀rọ̀ naa"mẹ́talọ́kan".

Mẹta ninu ọ̀kan.

"Awọn mẹta yii jẹ́ ọ̀kan."

Sugbọn ní ti ẹdà Bibeli NIV ni tirẹ̀, ó kàn sọ pé, "Nitori àwọn mẹta lo jẹ́rìí"

Kò darukọ Baba, kò daruko Ọrọ naa, kò darukọ

Ẹmi Mimọ, ati pe kò darukọ pe àwọn mẹta jẹ́ ọ̀kan.

Wo ohun ti wọn tun ṣe pẹlu Timoteu :. Bibeli kà pé, "Ati laisi

awawi titobi ni ijinlẹ ti iwa bi Ọlọrun" - wo eyi - "Ọlọrun wa

farahan ninu ẹran ara, ni idalare ti Ẹmi, a ri nipa àwọn angẹli, waasu rẹ̀ fun

àwọn Keferi, a gbà á gbọ́ ni ayé, a gba soke sinu ogo."

Ọlọrun ni a gbàgbọ́ ninu rẹ̀ ni ayé, Ọlọrun ni a gbà

sinu ogo, Ọlọrun ni a sọ di ẹran-ara ti ó si n gbé aarin wa, tí

Bibeli jẹ́ ki o yé wa kedere ninu Timoteu : pe Jesu Kristi jẹ́ Ọlọrun.

-Ni Timoteu :, o jẹ́ àyọkà pataki nitori mo maa n kà àwọn àròkọ-abẹ́

inu ẹ̀dà Bibeli Òdiwọ̀n Amẹrika Tuntun (NAS) deede ti mo ní nigba tí mo n bẹ ni ile-ẹkọ iṣẹ-iranṣẹ

Tí mo tún kà ninu ẹ̀dà NIV, ati àwọn àyọkà miran, tí wọn yoo kọ ọ́ sinu

àwọn àròkọ-abẹ́, tabi kí wọn tún kọ ọ́ sinu àwọn àwíjàre wọn, tabi ninu àwọn ẹ̀kọ́

lati inu ẹ̀dà NIV tabi ninu ẹ̀dà Bibeli Òdiwọ̀n Amẹrika Tuntun, wọn a wi pe

kosi ìyàtọ̀ kan ninu imọ-ijinlẹ Bibeli. Ko si ṣe ipalara kankan fun ilana

ẹ̀sìn. Sugbọn, o han gbangba pe ìyàtọ̀ wa laarin "hos" ati "Theos".

Bi o ba fi "ẹni ti o ti wà, 'hos' " dipo "Theos", dipo pe ó

jẹ́ Ọlọrun, ó daju pe ẹsẹ yii kò koju osuwọn mọ niyi, nitori o nilati rò ó

pe Kristi ni Ọlọrun, tabi tí ó farahan. Sugbọn ni "Theos", ko si pe a ṣẹṣẹ n ronu

lori ohun ti ẹsẹ naa n sọ. Ọlọrun ni ó farahan ninu ẹran-ara, tí

ẹni yii sì ni lati jẹ́ Kristi, tí ó jẹ́ pe laisi aniani, eyi sì n nípá lori

bí awọn eniyan ti n ronu nipa pe Jesu Oluwa ni Ọlọrun. -Ó dára.

-Ẹ̀rí nla miran lati fidi rẹ̀ mulẹ pe Jesu Kristi ni Ọlọrun n bẹ ní Heberu :.

"Sugbọn si Ọmọ ni ó wi pe, ìtẹ̀ Rẹ, Ọlọrun, wa lai ati titi lailai".

Kinni Bibeli n pe Ọmọ ni ibi yii?

Ó n pè é ni Ọlọrun. Ó wi pe, "sí Ọmọ...ìtẹ́ Rẹ, Ọlọrun, wa lai

ati lailai. Gbọ bí ẹ̀dà NIV ti sọ.

"Sugbọn nipa Ọmọ ó wi pe".

-Laipẹ mo n ba Ajẹri Jehofa kan sọrọ ni ibudo ọkọ oju-irin - Mo lọ

gbe iyawo mi wale. Tí Ajẹri Jehofa naa sì bẹrẹ si ni kà àwọn kàwé lati inu

iwe ẹ̀sìn pelebe kan tí n bẹ lọwọ rẹ̀ Sugbọn mo ri ẹ̀dà Bibeli Itumọ Ayé Ọ̀tun rẹ̀.

Tori naa mo sọ pé, "Ko buru, ṣe lati èdè Giriki ni wọn ti tú ẹ̀dà Bibeli Itumọ Ayé Ọ̀tun yii?"

Ó wi pe, "Lati inu Majẹmu Tuntun tí Westcott ati Hort kọ ni."

Mo wi pe, "Ṣe ó péye?"

Ó wi pe, ‘’Bẹẹ ni."

Mo wi pe, Ṣé o ti kẹkọọ ede Giriki rí?" Ó sọ pe, "Rara."

Mo wi pe, "Kinni o maa ṣe tí Jehofa funrarẹ̀ bá sọrọ pẹlu Jesu, tí ó sì pè é

ní Ọlọrun?" "Eyi kò ṣẹlẹ ri."

Nitori idahun rẹ̀, mo ka Heberu : fun un. "Si Ọmọ ó wi pe,

ìtẹ́ Rẹ, Ọlọrun, wa lai ati lailai".

Ara rẹ̀ kò balẹ mọ́, ọkàn rẹ dàrú tó bẹẹ tí ó sì yara gbe àwọn àpamọ́wọ́ rẹ̀, ó ṣí ilẹkun,

mo sì tẹle jade tí mo sì n ba a sọrọ lọ. Sugbọn nigbati mo ka lati

inu ẹ̀dà Itumọ Ayé Ọ̀tun lẹyin naa, wọn ti ṣe ayipada rẹ̀ patapata:

-Tí ó sì jẹ́ pe ninu ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu, kò le dàrú mọ́ ọ loju. Sugbọn ki i ṣe eyi nikan,

Sugbọn wọn ṣe àtakò ìbí wundia Kristi. Lọ si Luku :

Bibeli wi pe, "Ati Josẹfu ati iya rẹ̀ woye àwọn nnkan yii

ti a ti sọ nipa rẹ̀."

Sugbọn ní ti ẹ̀dà NIV ní tirẹ̀, ati ẹ̀dà ESV, ati Itumọ Ayé Ọ̀tun

wọn wi pe, "Baba ọmọ naa ati iya woye ohun ti a sọ nipa rẹ̀."

Nibẹ gẹlẹ ni a ti ri i pe ẹ̀dà NIV ati àwọn ẹ̀dà igbalode yooku n pe

Josẹfu ni baba Jesu Kristi, nnkan ti ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu

sọra lati maṣe pè é bẹẹ.

-Ṣe Josẹfu ni baba Jesu Kristi ni? Rara o, ko jẹ́ bẹẹ.

Ọkọ iya Jesu Kristi ní í ṣe. Kí o gba eyi bẹẹ.

Sugbọn oun ki i ṣe baba Jesu Kristi.

-Bi a ti mọ̀, tí a bá ka ori yii kan naa siwaju sí i, Maria pe Josẹfu ni baba Jesu

ó sì bawí lẹsẹkẹsẹ, Ó wi pe, "nigbati wọn ri i ẹnu yà wọn:

iya rẹ̀ sì sọ fun un pe, Ọmọ, kinni ṣe ti iwọ fi ṣe bẹẹ fun wa?

wo, baba rẹ̀ ati emi ti wa ọ pẹlu ibanujẹ."

Ṣe ki i ṣe Josẹfu ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pè ní baba Jesu yii? Wo bi ó ti

bawí lẹsẹkẹsẹ. "Oun sì sọ fun wọn,

bawo ló jẹ́ ti ẹyin fi n wa mi? Ẹyin kò mọ̀ pe mo gbọdọ

wà ni ibi iṣẹ Baba mi?" Ohun tí n sọ ni pé, Wò ó, iṣẹ Baba mi ni

mo n ṣe nigbati mo ba n waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun nitori Josẹfu

kì í ṣe baba mi, Ọlọrun Baba ni Baba mi."

Awọn eniyan to gbàgbọ́ ninu ẹ̀dà NIV, ni wọn ti fọju, mo tilẹ ti jẹ́ ki wọn

fi eyi han mi, tí wọn sì sọ pe, "Wò ó? Bibeli naa ni n pe

Josẹfu ni Baba Jesu."Rara, Maria lo n pe Josẹfu

ni Baba Jesu ẹniti ó sì gba ibawi lẹsẹkẹsẹ a jẹ pe ẹnikan nilo lati

ba ẹ̀dà NIV naa wí. Ẹnikan nilo lati ṣatunṣe sí ẹ̀dà Itumọ Ayé Ọ̀tun naa.

Ẹnikan nilo lati bá ẹ̀dà ESV, kí ó sì wí pe, "Duro ná. O kùnà.

Ẹni yii ki i ṣe baba Jesu. Baba Jesu ni Ọlọrun Baba."

O wi pe, Ó dáa, ṣebi kí ó le jẹ́ kí ó rọrùn sí i fun àkàyé. Ó dara bẹẹ, àwọn

ayipada yii kò fi bẹẹ ṣàkóbá fun ilana."

Awọn yii jẹ́ àwọn ilana pataki, tabi bẹẹ kọ?

Pípe Kristi ní Ọlọrun, ìbí wundia naa.

Ki i ṣe eyi nikan; wọn ṣe àtakò wíwà káyé-tó-wà rẹ̀ titi ayeraye. Wò ó, Jesu kò

kàn wa sáyé n ibujẹ-ẹran ni Bẹtilẹhẹmu. Jesu Kristi ko kàn wàyè

nipasẹ inu ilé-ọmọ Maria. Dipo bẹẹ, Jesu Kristi ti wà títí, tí yoó sì maa

wà sibẹ, Oun ni ibẹrẹ ati opin, oun ni Alfa ati Omega,

oun ni ibẹrẹ ati opin, eyi sì ṣe kókó sí jíjẹ́ Ọlọrun rẹ̀.

Bi ó ba jẹ́ ẹda ti a dá, ko le jẹ́ Ọlọrun.

Bibeli sọ ni Mika :, "Sugbọn iwọ, Bẹtilehẹmu, Efrata,

bi o tilẹ jẹ́ pe iwọ kere laarin ẹgbẹẹgbẹrun Juda, sibẹ lati inu

rẹ ni oun yoo ti jade wa si mi ẹni ti yoo jẹ́ alaṣẹ ni Israẹli; ẹni ti jijade

rẹ̀ ni a ti sọ nipa rẹ̀ lati ìgbàanì," - wo eyi - "lati ayérayé."

Tori naa, ní Mika :, Bibeli sọ fun wa pe Jesu Kristi ti n bẹ lati " lati ayérayé."

Awọn ọ̀rọ̀ meji tó lagbara pupọ niyi nitori wọn sọrọ lori ìwàláyè

ayérayé ti Jesu Kristi. Kò ní ibẹrẹ. Kì í ṣe ẹni ti a ṣẹda rẹ̀ rara

Oun ni Ọlọrun ninu ẹran-ara. Ó wà ní ibẹrẹ pẹlu Ọlọrun, ati pe Ọlọrun ni. [Johannu :]

Bayii, "ayérayé" tumọ si, o n bẹ titi lae; ó wà titi laelae.

Nitori bẹẹ, "lati ayérayé" yoo jẹ́ ohun ti o wa lati igba ìwásẹ̀

tabi ohun tó wà lati àtẹ̀yìnwá àìlópin, ohun to jẹ́ pe

ó ti wà tipẹtipẹ. Gbọ bí ẹ̀dà NIV ti sọ ọ́:

"Sugbọn iwọ Bẹtilehẹmu Efrata, bi ó tilẹ kere laarin àwọn ẹya ti Juda,

ninu rẹ ni yoo ti jade wa fun mi ẹni ti yoo jẹ́ alaṣẹ lori Israẹli, ti ipilẹ rẹ̀

ti wa lati igba wọnnì, lati igba lailai."

Ni bayii, kini ipilẹ?

Eyi ni igba ti ohun kan bẹrẹ sí ní wà, abi bẹẹ kọ?

Nigbati nnkan bẹrẹ sí ní jade, nigba naa ni ó bẹrẹ sí ní wà.

Wò ó, ṣe Jesu bẹrẹ sí ní wà ni àkókò kan ni?

Rara, ó ti wà lati igba laelae ninu ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu.

Sugbọn gẹgẹ bi ẹ̀dà NIV, ó ní ibẹrẹ.

Bi Jesu bá ní ibẹrẹ, ó jẹ́ pe oun kì í ṣe Ọlọrun, nitori Ọlọrun

ti wà, o sì tún wà, yoo sì maa wà. [Ifihan :]

Ọlọrun ti wà sibẹ.

Ọlọrun kì í ṣe ẹ̀dá kan.

Sugbọn nibi yii ni ẹ̀dà Bibeli NIV ti kúkú fọ igbá ayánga:

-Isaya : wi pe: "Bawo ni iwọ ti subu lati

ọrun wá, iwọ Lusiferi"...

-Ibi kan soso pére ninu gbogbo Bibeli ni o ti lè ri ọ̀rọ̀ naa, "Lusiferi". Lẹẹkan ṣoṣo.

Nibi yii ni a ti fi orukọ fun Satani, tí a pè é ni Lusiferi,

tí a bá sì n rìn lọ loju opopọna, tí a sì beere lọwọ àwọn eniyan pe, "Tani Lusiferi?

Kini Lusiferi?" gbogbo wọn a sọ pe, "Oun ni Satani; oun ni Eṣu."

Ṣe o mọ̀ ẹni ti Lusiferi jẹ́?

-Angẹli kan ti a lé sọkalẹ kuro ni ọrun ni, Satani.

-Satani.

-Eyi ni Satani.

-Eyi ni Eṣu.

-Esu.

-Oun ni Satani.

-Satani.

-Satani

-Satani

-Esu ni.

-Esu ni

-Ó dara, tani Lusiferi?

-Esu ni

-Ibeere tí kò nira ni: Mo mọ̀, Eyi ṣe gẹ́gẹ́.

-Satani. Bẹẹni.

-Ọna kan ṣoṣo ti emi ati iwọ fi mọ̀ pe orukọ Satani ni Lusiferi

ni nitori Isaya : sọ bẹẹ.

"Bawo ni iwọ ti subu lati ọrun, Lusiferi," – nisin yii,, mo fẹ́ ki o ṣakiyesi

ó fun wa ní orukọ rẹ̀, ó sí fun wa ni àpèjẹ́ rẹ̀ - "Lusiferi, irawọ owurọ!"

Kinni àpèjẹ́ Lusiferi gan an ná? "Irawọ owurọ", Ṣe bẹẹ ni?

Ifihan Ori , ẹsẹ ; ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu sọ eyi:

"Emi Jesu ni ó ran angẹli mi lati jẹri nnkan wọnyii fun yin ni ti awọn ijọ.

Emi ni" - Jesu lo n sọrọ yii - "Emi ni gbongbo ati irú ọmọ Dafidi,"

Jesu lo n sọrọ yii - "Emi ni imọlẹ ati irawọ owurọ."

Ṣe o rí i bẹẹ?

Kini Jesu pe ara rẹ̀? Irawọ owurọ.

Ìnagijẹ rẹ̀ niyẹn.

Bẹẹ ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu ati ẹ̀dà NIV ninu Ifihan : sọ pe

Jesu Kristi ni irawọ owurọ.

-Kini ẹ̀dà NIV pe Lusiferi tó jábọ́ sílé ayé lati ọ̀run?

-"Bawo ni o ti jábọ́ sinu ayé lati ọ̀run, Irawọ owurọ, ọmọ ìdájí!"

Dipo ki Lusiferi ti a le jade kuro ni ọrun ninu Isaya :, ninu ẹ̀dà NIV

Jesu ni a rí tí wọn lé jade kuro ni ọ̀run.

Wò ó bayii, Bibeli ti sọ fun wa pe a lé Lusiferi tabi Satani jade kuro

ni ọ̀run fun bi o ṣe fẹ́ dabi ọga ogo, o n fẹ́ lati dabi Ọlọrun.

Ṣe o rí i, ẹ̀dà NIV yii, lẹyin tí ó ti kọju-ija sí Kristi Oluwa gẹgẹ bí Ọlọrun, lẹyin tí ó ti kọju-ija

pe ó ti wà kí ayé tó wà, lẹyin ti o ti kọju-ija sí òdodo pé a ti ipasẹ wundia bí i, pe

kò ní ibẹrẹ, pe kò ní opin, pe oun ni Ọlọrun ninu ẹran-ara,

Ó tun wa n fẹsun kàn án pe o fẹ́ dabi ọga ogo. Oun gan an ni ọga ogo!

Gẹgẹ bi ẹ̀dà NIV rẹ ti sọ, Jesu ló ṣubu lati ọ̀run, kì í ṣe Lusiferi!

- Ti Satani ni awọn ti nbẹ lẹyin àwọn ẹ̀dà yii jẹ́. Satani ti fẹ́

ṣe idibajẹ Ọ̀rọ̀ naa ninu ọgba Edẹni

awa kì í sì ṣe òpè sí arekereke rẹ̀. [ Kọrinti :]

Wo, ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní agbara nla.

Bibeli kà bayii ni Heberu :, "Nitori ọ̀rọ̀ Ọlọrun yára,

ó lágbára, ó mú ju idà oloju-meji lọ, ó n wọ inu titi de

yiya ọ̀kan ati ẹmi sọ́tọ̀, ati si ipapọ egungun ati inu egungun,

o jẹ́ olùmọ̀ràn ọkàn ati àwọn ipinnu ọkàn."

Eṣu mọ̀ pe bi oun ba le gba ohun-ija lọwọ wa gẹgẹ bi Kristiẹni, oun le bori wa.

-Afojusun rẹ̀ lọwọlọwọ yii ati ní gbogbo igba naa ni lati gba ohun-ija wa lọwọ wa.

Wo inu itan. Nigbati àwọn eniyan buburu bá fẹ́ ṣẹgun àwọn ọpọ eniyan, ṣe o mọ̀

ohun tó saaju iṣẹgun naa? Wọn yoo gba ohun-ija àwọn eniyan naa ni.

Wò ó, ijọba n gbiyanju lati sọ fun ọ, "A fẹ́ gba àwọn ohun-ija rẹ

nitori a fẹ́ daabo bo ọ."

Ṣe o mọ̀, bi ẹnikan ba fẹ́ gba ohun-ija rẹ̀ lọ, igbiyanju wọn kò le jẹ́ lati

daabobo ọ; wọn fẹ́ gbiyanju lati ri i daju pe nigbati awọn ba wa ba ọ ja,

o kò ni le jà gba ararẹ silẹ rara.

Ni ọdun , orilẹ-ede Ìsọkan Sofiẹti ṣagbekalẹ ofin iṣakoso ibọn. Laarin ọdun si

ogun miliọnu àwọn oloṣelu alátakò ni wọn ṣe iku pa.

Ni ọdun , ilẹ Jamaní ṣagbekalẹ ofin iṣakoso ibọn, wọn bẹrẹ sí gba ibọn lọwọ àwọn eniyan

Laarin ọdun si , miliọnu mẹtala ẹya Juu ati àwọn miran ni wọn pa.

Ni ọdun , ilẹ Ṣáínà ṣe ofin iṣakoso ibọn, wọn bẹrẹ sí ní gba ohun-ija àwọn eniyan.

Laarin ọdun ati ,

ogun miliọnu àwọn oloṣelu alátakò ni ilẹ Ṣáìnà ni wọn pa.

Ni , ilẹ Uganda ṣe ofin iṣakoso ibọn, lati gba ohun-ija lọwọ àwọn eniyan.

Lati ọdun si – gbọ eyi daadaa - ẹgbẹrun lọna ọ̀ọ́dúnrún Kristiẹni ni wọn pa.

Ni ọdun , ilẹ Kambodia ṣagbekalẹ iṣakoso ibọn Ti wọn sì bẹrẹ si gba ibọn àwọn eniyan.

Laarin ọdun ati , miliọnu kan ọmọ Kambodia ni wọn pa.

Jẹ ki òye yii ye ọ, ọ̀tá n lakaka ni igba gbogbo lati gba ohun-ija

lọwọ rẹ, kì í ṣe lati daabobo ọ rara, titori kí o ma ba à lè gbìjà ara rẹ ni.

-Awọn ọ̀dájú-adarí maa n saaba gba ohun-ija àwọn eniyan ki wọn ba à di aláìlágbára,

lati sọ wọn di ẹrú. àwọn olùṣèjọba mọ̀ pe bi wọn ba le gba ohun-ija lọ́wọ́ àwọn eniyan,

wọn kò ní í lè jà lòdì si ìwà ọ̀dájú wọn.

-Gbọ mi ná? Ṣe wọn kọlù ọ̀rọ̀ Ọlọrun lode oni?

Dajudaju, bẹẹ ni. Nitori bi Satani ba le gba ohun-ija naa tí o lè fi

pa á lára lọ́wọ́ rẹ, ànì ohun naa tí o lè fi doju ija kọ ọ́ loju ogun,

bí ó ba lè gba ohun-ija rẹ naa, a jẹ pe iwọ yoo di ìjẹ-ìrọ̀rùn fun un.

-Eṣu ko fẹ́ nnkan miran ju pe ko gba ida oloju-meji naa tí í ṣe

ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu kuro lọ́wọ́ wa, kí oun sí fi ọ̀bẹ ìrẹ́-búrẹ́dì

ti i ṣe ẹ̀dà NIV, rọpo rẹ̀ fun wa

kí oun fi ọ̀bẹ ìrẹ́-búrẹ́dì ẹ̀dà ESV rọpo rẹ̀ fun wa,

kí oun fi ọ̀bẹ ìrẹ́-búrẹ́dì ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun (NKJV) rọpo rẹ̀ fun wa

Oun kò fẹ́ ki a wà ní ìdira-ogun. Kò fẹ́ kí a le bá àwọn alaṣẹ

ibi okunkun aye yii jagun.

Tẹsalonika ori kà bayii ni ẹsẹ , "Maṣe jẹ́ ki ẹnikẹni tàn ọ nì

ọnakọna: nitori ọjọ naa kò ní wà, ayafi ti ìyapa ba kọkọ wáyé,

ati ti ọkunrin ẹlẹ́ṣẹ̀ naa bá farahan, ọmọ iparun naa".

Bẹẹ ni Bibeli sọ fun wa pe...

-Siwaju ki asodisi-Kristi tó wá, kí ijọba ayé-dọ̀kan tó lè bẹrẹ,

kí Ààtò Ayé-Dọ̀tun tó lè bẹrẹ, ìyapa gbọdọ kọ́kọ́ ṣẹlẹ ná.

Kini ìyapa naa? Dídi ẹni-ẹ̀kọ̀ ni

Emi si gbàgbọ́ pe àwọn ẹ̀dà Bibeli ode oni ṣe pataki si ètò Eṣu

fun ẹ̀sìn ayé-dọ̀kan, ijọba ayé-dọ̀kan, Aato Ayé-Dọ̀tun.

Bibeli sọ fun wa pe kí ipadabọ Kristi ẹlẹẹkeji tó ṣẹlẹ, ìyapa nla

yoo wà, a pè é ní "apostasia". Ìyapa nla siwaju ipadabọ Kristi

lẹẹkeji yoo jẹ́ nitori àwọn alaisotitọ, opurọ, ẹ̀dà

Bibeli ode oni ti wọn lọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun sódì, tí wọn sì yi i pada

tí wọn tún n yí ilana Kristi naa pada.

Ohun ti mo n sọ ni pé wọn n fi àwọn àṣiṣe sinu Bibeli wa, tí àwọn eniyan sì n ṣe iyemeji

si Bibeli, wọn n ṣiyemeji si Ọlọrun, wọn n gba arokọ òbírí-layé gbọ́.

wọn n gba àwọn nnkan yii gbọ́. Gbogbo iṣe rẹ̀, o n ṣe atilẹyin fun iṣejọba

Ayé-dọ̀kan ni. Kilode? Nitori pe ó n satilẹyin fun ìyapa.

-Ohun kan tí ó tún yanilẹnu ni pe ní ọpọ igba, nigbati àwọn eniyan ba n sọrọ ijọba

ayé-dọ̀kan, tabi ti ẹ̀sìn ayé-dọ̀kan to n bọ̀, wọn a ma sọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi

Ààtò Ayé Dọ̀tun. Njẹ bẹẹ ló rí? Talo ti gbọ́ gbolohun yii rí:

" Ààtò Ayé Dọ̀tun"?

-Ó jẹ́ erongba nla, ààtò ayé dọ̀tun.

-Wọn maa kù gìrì wọ ilé ninu ọ̀kọ̀-ogun, àwọn ibọn ṣetan lati yìn.

-Ààtò ayé dọ̀tun niyi...

-A nilati fun wọn ni aaye lati ṣagbekalẹ iru aato agbaye

ti mo lero pe gbogbo wa maa fẹ́ lati rí.

-Ṣé o n ṣe ireti rere pe ijọba kárí-ayé kan le ṣẹlẹ bí, lori gbogbo ohun ti a ti gbọ́ yii?

-Bi ó ba le ṣẹlẹ, lotitọ ni ò tilẹ ti n ṣẹlẹ, iṣẹ ti n lọ lọwọ lori rẹ̀...

-Awọn eniyan tó wà lẹyin adehun yii fẹ́ ijọba agbaye naa

tó sì jẹ́ pe ninu ọkàn wọn, igbesẹ kan ni eyi jẹ fun un.

-O nsọ nipa ṣiṣe àkóso ohun-ija, dídarí iye tó wà, ni igbẹyin

dídarí kárà-kátà pẹlu?

-Nigbẹyin, dídarí gbogbo wa.

-Gbọ eyi ná. Njẹ́ o mọ̀ pe ẹ̀dà NIV lo ọ̀rọ̀ yii "ààtò ọ̀tun"

fun ipadabọ Kristi?

Ninu ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu, Heberu : wi pe. "to duro lori ẹran nikan ati

ohun mimu, ati orisirisi wíwẹ̀, ati ilana ẹran-ara, ti a gbekalẹ fun wọn titi

di igba ìṣàtúntò.

Bayii eleyi n sọrọ nipa nnkan ti o ti ṣẹlẹ ṣẹyin, ṣe bẹẹ ni?

-Igba ìṣàtúntò jẹ́ atọka sí pipadabọ Jesu Kristi.

Ní bayii, o ni lati mọ̀ eyi. Eyi jẹ́ atọka si igba àkọ́kọ́wá sáyé

Jesu Kristi. A ko nilo lati maa ṣe ti ẹran, ohun mimu, oriṣiriṣi wíwẹ̀, àwọn

ilana ẹran-ara. A ko ṣe iru eyi mọ́. Kilode? Nitori igba

ìṣàtúntò dé. Jesu Kristi Oluwa dé.

-Gbọ bí ẹ̀dà NIV ti sọ: "àwọn ofin ode ni o n ṣiṣẹ titi di igba

aato ọ̀tun. "Lẹyin naa, bi o ba tun ka ẹsẹ ninu ẹ̀dà NIV yii, ó jẹ́ ki ó jọ

pe ohun kan ti o si n bọ̀ ni ọjọ iwaju ni eyi.

Aato ọ̀tun naa ki i ṣe akọkọ wáyé Kristi, Sugbọn pe ni ipadabọ

ẹẹkeji Kristi ni ààtò ọ̀tun naa n tọka si.

Ẹ̀dà Bibeli Itumọ Iroyin Rere soju abẹ níkòó, ó sọ eyi pe:

"Awọn yii jẹ́ ofin òde, ti ó ṣiṣẹ nikan titi the igba ti Ọlọrun

yoo ṣagbekalẹ ààtò ọ̀tun."

Ẹ̀dà Bibeli Itumọ Gẹ̀ẹ́sì Tuntun pẹlu pè é ní ààtò ọ̀tun.

Ẹ̀dà Bibeli Gẹ̀ẹ́sì Gbogbogboo pẹlu pè é ní ààtò ọ̀tun.

Bibeli tí n tà julọ ni ilẹ Amẹrika lonii

pe pipadabọ Kristi ní ààtò ọ̀tun.

-Tilẹ̀ rò ó ná. Asodisi-kristi kan n bọ̀, igba tó bá sì dé ni yoo jẹ́

àkókò ààtò ọ̀tun.

Sugbọn eyi kọ ni iwe Heberu n sọ nipa rẹ̀.

-ọpọlọpọ nnkan ni n bẹ ninu àwọn Bibeli igbalode yii tó ti sọ awọn asọtẹlẹ igba ikẹyin inu Bibeli di ìdàkudà

kí ó le mu àwọn eniyan gbaradi lati tẹwọgba asodisi-kristi, kí ó le mu àwọn eniyan gbaradi

lati fà wọn bọnú Ààtò Ayé-Dọ̀tun, kí ó le mu wọn tẹwọgba itannijẹ

lati ọwọ ijọba agbaye, ẹ̀sìn ayé-dọ̀kan, agbekalẹ ayé-dọ̀kan

ti asodisi-kristi, ati lati gba ami ẹranko naa.

-Sọ pe, Oluṣọ-agutan Jimenez, o n lọ lori àwọn isọtẹ yii.

Ṣé o gbàgbọ́ ninu Ààtò Ayé Dọ̀tun?

-O rò pe ero aimọkan ni lati rò pe àwọn oṣiṣẹ ile-ifowopamọ ati àwọn eniyan lode

ti n gbiyanju lati mu ijọba ayé-dọ̀kan wáyé?

Emi kò mọ̀ boya o ti ka iwe Ifihan rí, nitori tí bibeli sọ fun

wa pe asodisi-kristi yoo ṣe agbekalẹ ijọba kansoso ni agbaye.

Bibeli sọ fun wa pe asodisi-kristi yoo ṣagbekalẹ ẹ̀sìn kansoso fun agbaye.

Emi kò rò pe o jinna pupọ sí ohun ti àwọn eniyan ti n sọ pe,

"Ah, àwọn osiṣẹ ile-ifowopamọ n gbe aato aye-dọkan wọle wá

pẹlu ijọba aye-dọkan."

Ni lọwọlọwọ yii, wọn le ro pe - ṣebi o mọ̀ àwọn eniyan elérò-dìmọ̀ yii - wọn le maa ro pe,

"Ẹhn, ṣebi àwọn osiṣẹ ile-ifowopamọ kàn ni; ṣebi eyi kàn ni,"

Sugbọn a mọ̀ ninu Bibeli pe asodisi-kristi

n mu nnkan kan naa bọ̀.

Ohun ti Bibeli sọ niyi.

Lati inu ọgba Edẹni, ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti n rí ìkọlù.

Ki Bibeli paapaa tó di akọpari tan, ìkọlù ti n bẹ fun

ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ṣe o rò pe eyi yoo yàtọ̀ lode oni?

Rara.

Ó yẹ ki eyi yé ọ. Lode oni, ọ̀rọ̀ Ọlọrun n rí ikọlu.

Awọn ẹ̀dà Bibeli ode oni yàtọ̀ patapata si ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu

ó sì yẹ ki o beere ibeere yii lọ́wọ́ ara rẹ: kilode?

Ki ìyàtọ̀ naa le yé ọ, o nilo lati mọ itan

Bibeli Gẹ̀ẹ́sì naa.

Ó ṣẹlẹ pe ilé ìsùra-ìsẹ̀mbáyé Bibeli nihin ni ilu Phoenix ti o ní àwọn

akojọpọ irufẹ àwọn Bibeli Gẹẹsi ti kò wọpọ lagbaye, tí oludari ilé ìsùra-ìsẹ̀mbáyé

naa, Joel Lampe yoo gba wa laaye kí a rí àwọn ẹ̀dà Bibeli alákọ̀ọ́kọ́ naa

tí kò wọ́pọ̀, titi dé itan Ọba Jakọbu ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu gan an funrarẹ̀.

O maa salaye itan ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu fun wa.

Ó maa mu wa kọja ninu itan lati igba Majẹmu Tuntun ti ede Giriki, tí Ẹrasmu kọ,

ojúlówó Textus Receptus.

yoo sì tun mu wa lọ ninu itan gbogbo àwọn Bibeli Gẹ̀ẹ́sì

titi de ti ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu.

Ẹ jẹ ki a bẹrẹ pẹlu Ẹrasimu.

-Oluṣọ-agutan, ohun ti ẹ n wo lori tabili yii, ni kukuru, jẹ itan

ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu.

Ẹ ranti pe a tẹ ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu ní ọdun , ede-aiyede kan

sì n bẹ lode pe eyi ni Gẹ̀ẹ́sì akọkọ.

Bẹẹ sì ni, eyi kò rí bẹẹ. Ọpọlọpọ awọn Gẹ̀ẹ́sì ló ti wà siwaju ọdun

ohun tí ẹ sì n ri nibi bẹrẹ pẹlu ojúlówó Giriki, gẹgẹ bi ẹ ti wi,

Textus Receptus, ti Ẹrasimu Rotadamu ṣe.

Eyi mu ayipada ba ohun gbogbo tí a ti mọ̀ lode oni ohun nipa itan ìjọ

ati pẹlu nipa itan agbaye.

A pè é ni ẹ̀dà èdè Giriki ti Ẹrasimu ilu Rotterdam ti ọdun /Majẹmu Tuntun èdè Latin.

Ó dara, ẹ jẹ́ ki a kàn pe Ẹrasimu ni ohun to jẹ́:

ọkunrin kan tí ó lọgbọn julọ láyé, tí kì í ṣe oriṣa. Ni pato, Jesu

ni ó jáfáfá julọ láyé. Solomoni naa wà nibẹ pẹlu, Sugbọn ni

lode oni, a wòye pe Ẹrasimu ló gbọn julọ. Boya ninu sayẹnsi, ẹkọ imọ Ọlọrun,

ẹkọ ìmọ̀dòye, oun ṣá ló gbọn julọ.

-Ṣé eyi sì ni ojúlówó Textus Receptus nibi yii?

-Ojúlówó Textus Receptus.

-Ẹhn, ẹhn.

-Jọwọ wò ó.

Eyi ti a mọ̀ sí iwe naa tí ó ṣe pataki julọ ninu awọn iwe ti a tẹ jade.

Iwe yii sì ló ìfilọ́lẹ̀ ìṣàtúntó.

Koda kí o jẹ́ alaigbagbọ gan an; iwọ yoo gbà pe eyi ni iwe pataki julọ naa ti a tẹ jade.

Nipasẹ ni wọn ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ìsọdọ̀tun. Ododo naa jẹ jade lati inu iwe yii.

tí a sì rí i bí iwe naa ṣe kún fun aṣẹ tó Sugbọn ohun tí ó tun ṣe ni pe

ó dá ọpọlọpọ wahala silẹ. Kin sì ni ohun ti mo n sọ nipa eyi?

Nigba naa, owó kò wọle fun Romu mọ́. Ile kan nbẹ ti wọn nkọ lọ́wọ́.

Ẹni olókìkí kan wà tí ó maa n ṣe inu ile ní ọ̀ṣọ́, ti wọn gbà lati

ṣe ilé naa ní ọ̀ṣọ́. Mo n sọ nipa ilu Vatican, Michaelangelo,

Ile ijọsin Sistine. Owó kò fi bẹẹ wọle mọ́. Ijọ bẹrẹ sí ní

diyele ori àwọn eniyan, pe, "O kò le kọni ni ẹkọ yii. Eyi kọ ni a

wo pe ó ṣe déédéé", bi o tilẹ jẹ́ pe Ẹrasimu sọ pe, "A ni wahala kan nihin.

'Mẹtanoia' ló sọ, kì í ṣe 'san owó ìtanràn,tori eyi, a ni lati mẹnu ba

ẹkọ ijinlẹ-ọrọ Ọlọrun yii." Sugbọn iwe yii ló mu kí àwọn ìjọ

àfẹ̀hónúhan kórajọ. Kinni ijọ àfẹ̀hónúhan kórajọ tumọ si gan an?

Lati fi ẹ̀hónú han ni.

-Ninu iwe yii ti o fi n han mi yii, Ẹrasimu gbe ojúlówó Giriki

sẹ̀gbẹ̀ẹ́ Latin ìjọ, eyi si jẹ́ ki ó rọrun pupọ lati ri ìyàtọ̀

laarin àwọn mejeeji. -Bẹẹ ni.

-Ṣé lootọ? -Idi niyi tí ó fi yí ohun gbogbo pada.

Nitori pe ó ṣafihan ohun ti a nṣe tí kò dara, ó sì fi ohun ti o yẹ ko jẹ́ hàn.

Sugbọn kò tumọ rẹ̀ lati ṣafihan ohun tó yẹ ko jẹ́ tó bá yá.

Eyi kò rí bẹẹ titi di ọdun

-Ṣé pé awọn ohun meji tí n tako ara wọn niyi lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn.

-Gbogbo ohun tí ó n ṣe kò ju pe ó fidi ẹri mulẹ lọ.

-Ẹ̀dà Latin ìjọ naa ti o ti ní àlèébú ati ojúlówó Giriki Textus

Receptus, ó kàn gbe wọn si ẹgbẹ ara wọn, ó sì jẹ́ ki onkawe

ṣe idajọ.

-Sugbọn eyi ni ota ibon ni paapaa, wulo julo, ti o pa ìjọ.

-Bẹẹni.

Ohun tó n wò nihin ni ohun ti a mọ̀ lonii gẹgẹ bi atẹjade akọkọ Bibeli Coverdale.

Kini, lotitọ, ó jẹ́ nipasẹ iṣẹ tí William Tyndale ṣe. Gẹgẹ bi a kúkú ti mọ̀ pe

Tyndale ni ẹni ti o ṣẹ̀dá ede Gẹ̀ẹ́sì ti a nsọ lonii. Oun naa ni ó ṣẹ̀dá

Bibeli Gẹ̀ẹ́sì akọkọ wa ti a tumọ lati àwọn ede ti ó kọ́kọ́ wà.

Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Tyndale fẹ́ maa ṣe nnkan kan naa ti Luther n ṣe ni ilẹ Jamani.

Ó n ṣiṣẹ ní abẹle, pẹlu atilẹyin akójọ-iwe Luther, Iru àwọn iwe tí n bẹ nibi

lẹyin igba naa ni ó sì tun lo àwọn iṣẹ Ẹrasimu, Tyndale ló ṣe atẹjade

Majẹmu Tuntun akọkọ. Ó di iwe ti wọn lépa julọ ninu itan ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Tí ọba sì fẹ́ ki a jo nnkan yii ninu ina.

-Bayii ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì wà ni abẹ akoso ìjọ Katoliki ni igba naa

ti Tyndale n ṣe atẹjade iwe Majẹmu Tuntun rẹ̀ ni ọdun ?

-Ó sì jẹ́ iwe tí ó jẹ́ ìjọ̀ngbọ̀n si awọn agbekalẹ tabi ìjọ Katoliki

ti ilu London ni igba naa ni.

Eyi yọrísí ohun aṣeyori titobi nitori pe, ninu àwọn ọdun to kẹyin

aye rẹ̀, Tyndale lo pupọ ninu àkókò rẹ̀ lati fi tumọ Bibeli lati ede Heberu ati

Giriki lati ṣe atẹjade iwe yii.

-Eyi to kù ninu Majẹmu Laelae, diẹ ninu rẹ̀ ni wọn ko lee pari lati

ojúlówó Heberu ni deedee igba ti iwe yii jade?

Rara o, nitori wọn mu Tyndale si atimọle ni ọdun

-Bẹẹ ni.

-Ó wà ni atimọle ninu ilé rẹ̀ fun ẹẹdẹgbẹta ọjọ. Lẹyin naa, ni owurọ

ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa, ọdun , wọn mu u jade wọn si dá ina sun ún. Sugbọn ni àkókò atimọle

naa, Myles Coverdale pari ohun ti Tyndale bẹrẹ.

Bayii, akọsilẹ yii ni ohun ti mo nífẹ̀ẹ́ ju ohunkohun ti nbẹ ninu yara yii lọ.

Eyi ni ọdun ti a n pe ni ẹ̀dà Bibeli ti Mateu. Kinni eyi jẹ́?

Kì í ṣe ohun miran bi ko ṣe àṣeparí yii.

-Ẹhn, ẹhn.

-Bayii ranti igba ti Tyndale fẹ kú, ọ̀rọ̀ ikẹyin rẹ̀, gẹgẹ bi o ti sọ ọ rekete

lẹẹkan ni pe, "Oluwa la oju Ọba Ilẹ Gẹ̀ẹ́sì."

Bayii kini o ṣẹlẹ si adura yii?

Tyndale le sọ aimọye àwọn nnkan miran.

Kilode ti iwọ yoo fi sọrọ danu pe, "Oluwa, la oju Ọba

ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì"? Tyndale mọ̀ pe kosi bi Ọba Hẹnr Kẹjọ ti le ya wèrè tó, bí ó

ba le jẹ́ ki Hẹnri Kẹjọ yapa kuro ni Ìjọ tó wà ní Romu, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

yoo rí iṣẹgun ati aabo. Ó jẹ́ ohun kan lati ni ibaṣepọ to dánmọ́rán

pẹlu Jesu. Ohun miran sì tun ni kí a ní ibaṣepọ pẹlu Jesu ati pẹlu

ẹnikan tó fẹ́ jí lati ojú oorun kí ó sì fẹ pa ọ láàràárọ̀. Iṣẹ-ọwọ tiwọn niyi.

Sugbọn nigbẹyin-gbẹyin Hẹnri Kẹjọ fun Bibeli naa laaye lati jade nitori ohun kan:

ìjáwèé-fún-ni ninu igbeyawo.

Laiṣe aniani, awọn iwe mejeeji yii yi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pada.

O le ni ibaṣepọ timọtimọ pẹlu Jesu

lati inu awọn iwe meji yii.

-O ní onílàjà ìjọ naa dípò pe kí

Jesu Kristi nikan jẹ́ onílàjà naa.

-Ohun ti a n pe ni yàrá ijẹwọ lonii.

"Dariji mi, baba, nitori mo ti dẹ̀ṣẹ́. Ó to ọṣẹ meji ṣẹyin

ti mo ti wá fun ìjẹ́wọ́"

-Ni isinsin yii, eyi ti borí yàrá ijẹwọ.

-Ó ti rẹ̀yìn rẹ̀ patapata. A kò nilo eyi mọ́. O ko nilo lati lọ sọdọ

ọkunrin kan ko sọ fun ọ ohun ti ijiya

fun ẹsẹ ti o da si Ọlọrun jẹ́.

Ohun ti a ni lonii yii ni Bibeli nla tabi Bibeli tí Hẹnri Kẹjọ,

Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, fàṣẹ sí, tí ó sì gbà láàyè

Yoo mu inu ẹni dùn, bi a bá le mu awọn ohun kan wá sí iranti.

Ọkunrin ti n jẹ Besa ni ó ṣe ẹ̀dà iṣẹ Ẹrasimu kan tí wọn tẹjade lẹyin eyi.

Iṣẹ miran ti a mọ̀ daradara ni pato, ni eyi tó wà nihin

tí Stefanusi ṣe. Bayii Stefanusi ṣe pataki nitori ó fun wa ni ede Giriki

ti Bibeli Geneva wa tabi Bibeli ti a ṣe nipasẹ àwọn alatunto John Calvin,

William Wittingham, àwọn yii, wọn lo iwe Giriki yii lati tumọ Bibeli ede Gẹẹsi

ti a mọ̀ lonii si Bibeli Geneva.

Bayii, ó lokiki nitori ó jẹ́ akọkọ rẹ̀ pẹlu àwọn ẹsẹ. Ó dara, idi naa niyi

tí Bibeli Geneva fi jẹ́ mimọ daadaa fun wa. Bí i ka sọ pe, nibo ni Johannu :

ti wa? Ẹhn, ó wá lati...

-Wọn pin in sí awọn ori ati àwọn ẹsẹ?

-Awọn ori ti wa nibẹ tẹlẹ.

-Wọn pin si àwọn ẹsẹ. Àwàdà ni o.

-Lẹyin Hẹnri Kẹjọ ni ọmọ rẹ̀ gori ite. A mọ̀ ọ lonii gẹgẹ bi

Ẹdwọdu Kẹfa. Ó kú lọmọde. Ó jọba fun ọdun mẹrin si marun un

pere. Sugbọn ni àkókò yii o gba Bibeli laaye lati jade laisi idiwọ. Sugbọn ko

ni iyawo tabi ọmọ ati nigbati ko sì ní àrólé, tani yoo jogun

ìtẹ́ rẹ̀? Arabinrin rẹ̀ ti a mọ̀ lonii gẹgẹ bi Maria Ẹlẹ́jẹ̀. A ko si

pe bẹẹ nikan nitori ó fẹran ọti ati omi tomati pẹlu

Tabasko diẹ. A n pe ni Maria Ẹlẹ́jẹ̀ nitori o jẹ́ ẹni ti o wa nidi

iku awọn eniyan to le ni ẹgbẹrun meje. Ati eyi ni apẹẹrẹ tó daju kan. Ẹbi kan

n bẹ, Oluṣọ-agutan , nigba ijọba Maria Ẹlẹ́jẹ̀. nibi ni àwọn iya marun un ati baba marun un gbogbo

wọn ni wọn sun jọna ni ita gbangba. Fun idi wo?

Wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn ni Adura Oluwa ni ede Gẹ̀ẹ́sì.

-Ẹhn, ẹhn.

-Oun sì sun wọn níná ni ita gbangba.

-Nitori itara rẹ̀ fun ìjọ Katoliki, o npa àwọn eniyan.

-Awọn obi nkọ àwọn ọmọ wọn ni.

Ó dara. Ati pe wọn kàn fẹ́ jẹ́ kí ìjọ maa kọ wọn ni?

-A kò kun oju-osuwọn, Oluṣọ-agutan lati kọ àwọn ọmọ wa.

-Bayii ni wọn sun wọn níná mọ́ òpó toripe wọn kọ àwọn ọmọ wọn nile.

-Eyi jẹ́ ohun ti o pada jasi. Ninu ero kan, lo jẹ́.

Wọn fẹ́ ìjẹgàba tó rinlẹ̀.

-Ẹhn-ẹhn.

Ni àkókò irukerudo naa, àwọn akọni ọkunrin pinnu pe, awa yoo

yapa. Kinni orukọ wọn? John Knox, John Foxe, William Wittingmam.

Wọn sá kuro ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lati lọ ṣiṣẹ lori iwe tuntun. Ati pe kini a n pe

iwe naa lonii? A n pe eyi ni Bibeli Geneva.

-Bayii ó sọ nibẹ, ẹnikan ti kọ ọ si ibi, "Bibeli Ẹbí"

-Bẹẹ ni o. Ohun ti o jẹ́ gan an niyi: Bibeli akọkọ fun ẹbi.

mọ̀ ọ gẹgẹ bi Bibeli akọkọ, Bibeli "ẹkọ ilé": Bibeli Geneva.

-Bẹẹ ni.

-Eyi sì ni iwe naa tó gun Mayflower rekọja lọ lori omi.

- Àwàdà ni o.

-Eyi ni Bibeli naa tó tẹ̀dó sí ilu Jamestown.

Lẹyin ìjayà Maria Ẹlẹ́jẹ̀, ó ní arabinrin kan. Tí a mọ̀ tí orukọ rẹ̀ n jẹ́

Ọba-bìnrin Elisabẹti. Lati fa oju àwọn Eniyan mọ́ra, ó fun wa ni Bibeli

Biṣọbu. Eyi ni àwọn "biṣọbu" ṣe,

ti àwọn Oluṣọ-agutan ṣe.

-Sugbọn lati orírun Bibeli Geneva naa ni fi wọn ṣe é .

-Wọn kan fẹ́ ohun kan ti ó jẹ́ pe ó ní aṣẹ tó ga diẹ ni.

Bẹẹ ni.

-Eyi wa lati ọdọ àwọn eniyan tI ẹ le gbarale. Awọn ògbóntarìgì

-Awọn ògbóntarìgì ninu ede Heberu ati Giriki, Sugbọn lotitọ, ko tẹ àwọn eniyan lọ́rùn.

Ó jẹ́ iṣẹ tó-fakọyọ.

-Sugbọn ní bákan, kò gbayì tó bẹẹ.

-Kò ní tẹwọgba kankan.

-Boya nitori pe Ọlọrun mọ̀ pe nnkan tó daraju kan n bọ̀ lọna ni.

-Ati pe oun kò kúkú ní ọkọ kankan; ko ni ọmọ. tani yoo gun ori

ìtẹ́ naa? Arakunrin rẹ̀ lati ilu Scotland. Ẹni naa ti a mọ̀ sí Ọba Jakọbu ni.

Bibeli nla yii, tó ga, tí o n wò nisalẹ yii, tó sunmọ ọ julọ yii, oun ni

atẹjade akọkọ ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu. Lẹyin ọdun kan, ó gba àwọn eniyan

laaye lati ra ọ̀kan ni ilé itawe kan, eleyi tí o mú lọwọ yii

naa ni ẹ̀dà Majẹmu Tuntun akọkọ ti Ọba Jakọbu.

-Ẹ̀hn, ẹ́hn.

Nigba tí ó sì di ọdun , Ọba Jakọbu kuku di ọba. Ọba Jakọbu Kẹfa ti

ilẹ Scotland. Ó di ọba, wọn sì sọ fun pe itumọ tuntun

gbọdọ jade fun ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ati eredi ni yii ti

o fi ri ọpọ eniyan tó n lo Bibeli Geneva, Sugbọn wọn a tun lọ si

ìjọ wọn yoo sì rí i pe Bibeli Biṣọbu ló wa nibẹ, tori bẹẹ, àwọn ẹ̀dà gboogi meji ni n bẹ,

tí àwọn mejeji naa sì ní kọ́nú-n-kọ́họ.

Bibeli Geneva ní awọn iṣoro tirẹ̀; Bibeli Biṣọbu naa ni àwọn tirẹ̀ naa pẹlu.

Ni wọn bá sọ pé ẹ jẹ́ ka fi àkókò silẹ lati ṣiṣẹ yii daradara.

Wọn kó àwọn ọ̀mọ̀wé ní ilẹ naa jọ, wọn sì sọ pe kì í ṣe pe a n gbiyanju

lati rọ́pò itumọ tí kò dara.

A n tẹsiwaju lati eyi to dara sí eyi tó dara julọ ni nibi. Mo mọ̀ pe àwọn eyi dara

ni itumọ. Bibeli Geneva dara; Bibeli Biṣọbu dara.

A kan fẹ́ ṣe aṣepe wọn ni kí wọn sì di àmúlò.

Nipa bẹẹ, lati ọdun si , àwọn ọ̀mọ̀wé mẹrinlelaadọta tí wọn jẹ

ògbóǹtarìgì ní ayé igba naa ṣe tumọ ẹ̀dà KJV. Lati kàn fun yin ní apẹẹrẹ kan: ọkunrin kan,

Lancelot Andrews, ọjọgbọn ninu èdè Latin, Giriki, Heberu, Kaldea, Siriaki,

pẹlu Larubawa, ó sì tun n sọ àwọn ede ode-oni mẹẹdogun. Ọkunrin kan niyi ninu awọn mẹrinlelaadọta

àwọn eniyan tó siṣẹ lori itumọ Bibeli ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu fun ọdun meje.

-Àwọn kan kan tun wà tó jẹ́ onímọ̀ ede Larubawa. Awọn kan wà ti wọn jẹ́

Onimọ ede Giriki ati Heberu. Awọn ti Aramaiki naa wà. Wọn jẹ́ àwọn ọkunrin tó

lóye pupọ, gbogbo wọn. Ìmọ̀ wọn nipa bibeli sì yatọ sí ara wọn.

Irufẹ igbagbọ tí ọkọọkan wọn lè ní, tabi abala imọ-ijinlẹ Bibeli ẹnikọọkan

wọn le yatọ sí ọ̀kan tabi àwọn òngbufọ̀ miran.

Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn pin ara wọn si ọna mẹfa.

Awọn mẹfa yii tumọ àwọn iwe mẹfa inu Bibeli ati bẹẹbẹẹ lọ. Nigba ti wọn

ṣe eyi tan, wọn fi ọkọọkan iṣẹ yii wé arawọn lapapọ, bayii sì ni ọkọọkan àwọn isọri mẹfa

naa ṣe. Wọn sì yan olori kan lati inu isọri kọọkan lati ṣagbeyẹwo iṣẹ gbogbo isọri mẹfẹẹfa

ohun tí eyi jasi ni pe, ayọka Bibeli kọọkan ni wọn gbeyẹwo ni igba mẹẹdogun.

Nikẹyin ohun gbogbo: gbogbo wọn fi imọ sọ̀kan pẹlu ohun ti wọn

ti tumọ lori ọrọ-iṣe tó péye ti wọn lò, fun ohun tí

ọrọ naa sọ, fun ohun tí ó tumọ sí,

botilẹjẹ pe ó le yàtọ̀ diẹ niwọnba si ohun ti ọkọọkan wọn gbà lero.

-Ní ọdun Ọba naa sọ pe, "Ó dara, Mo maa da igbimọ kan silẹ, bi ó sì ti wù kó

pẹ tó, ẹ maa siṣẹ labẹ àwọn ilana meji:

Majẹmu Laelae ni ẹ gbọdọ túmọ̀ lati ede Heberu, ẹ sì gbọdọ túmọ̀ Majẹmu Tuntun

lati inu ede Giriki, gbogbo àlùmọ́ọ́nì tí n bẹní ìkápá mi pata ni emi yoo fi fun yin

lati mu ki eyi le ṣeeṣe." Nipa bayii, onimọ ede Heberu igba naa tó dá-ntọ́ julọ,

onimọ ede Heberu igba naa tó dá-ntọ́ julọ, ní ọdun naa, ẹni mẹtalelaadọta ni ó gbé iṣẹ.

naa fun. Wọn siṣẹ naa fun ọdun meje lori ohun ti a mọ̀ lonii gẹgẹ bi iwe to ṣe pataki

julọ ninu itan eniyan; atẹjade akọkọ, agbejade kini, atẹjade kini ti

iwe ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu. Ó sì gba wọn ni ọdun meje.

Wọn ṣe iṣẹ tó ní àpẹẹrẹ. Tí ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu ti emi ati iwọ n ka lonii

jade wá lati inu iṣẹ atunyẹwo ọdun , Sugbọn eyi ni ìdákọ̀ró iwe naa. Eyi

naa sì tun ni abajade rẹ̀. Ní ọdun , ó fun wa ni ohun ti a mọ̀ lonii gẹgẹ bii

ẹ̀dà Bibeli-ìlèwọ́ akọkọ Majẹmu Tuntun ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu.

Eyi ni o di itẹwọgba.

-Eyi ni o ṣe itẹwọgba.

-Bibeli-ìléwọ́ Majẹmu Tuntun.

-Ọba naa sọ pe bi o ba lagbara rẹ̀, ó le jẹ́ tirẹ. Gbogbo ilé-itawe ni ilu London

ló n tà á, yoo si gbera sọ.

Yoo sì di iwe kanṣoṣo tó tà julọ nigba naa lọhun, tí ó sì tun jẹ́ iwe naa tó n tà julọ di oni ninu itan

eniyan. Kosi iwe to figba kan tà ju iwe yii lọ, kò si le si laelae.

-Nigbati bi a ba wo awọn ẹ̀dà Bibeli ti a sọ di ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu naa: Tyndale,

Mateu, Coverdale, Bibeli nla, Bibeli Biṣọbu, Bibeli Geneva, gbogbo

wọn wà loju ìlà pẹlu ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ni. Ohun kan naa gbogbo wọn sọ ní pàtó pẹlu

ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu. Ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu ni àkóríjọpọ̀ àwọn Bibeli to ti saaju

rẹ̀. Nitori naa, tí ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ba baramu pẹlu gbogbo àwọn Bibeli Gẹ̀ẹ́sì

to ti saaju rẹ̀, kilode ti àwọn Bibeli ode oni fi yàtọ̀?

Ọ̀mọ̀wé James White jẹ́ ẹnikan tó jiyàn lòdì sí àwọn eniyan to faramọ́ ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu nikan.

Ó ti ṣe iwe kan lòdì sí àwọn to maa n ka ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu nikan.

Ó jẹ́ ẹnikan ti a mọ̀ gẹgẹ bi akoṣẹmoṣẹ lori idi ti lilo ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu nikan kò tọna. Tori naa,

a maa sọrọ pẹlu rẹ̀ ki a sì sawari ohun ti ariyanjiyan rẹ̀ jẹ́.

-James? A ní àwọn alejo.

-Ó dara. Ṣé alaafia ni?

Ọ̀mọ̀wé James White, o ṣeun pupọ fun pe o ba wa sọrọ lonii.

-Inu mi dun lati wa pẹlu yin.

-Njẹ o le fun mi ni Codex Sinaiticus ni ṣoki,

ati Codex B naa ní ṣoki?

-Lapapọ Sinaiticus ati Vaticanus jẹ́ idi àkọ́kọ́ ọ̀rọ̀ ibinu ti àwọn ẹgbẹ́ ti n fẹ́

ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu nikan nitori tí idagbasoke Majẹmu Tuntun ṣe pataki

sí wọn ju iwe Textus Receptus lọ.

-Awọn meji to n jẹ́ Westcott ati Hort ṣe akojọpọ iwe kan tó dá lori

àwọn àpilẹ̀kọ meji ti a mọ̀ sí Sanaiticus tabi "Codex Aleph" ati

Vaticanus tabi "Codex B". Westcott ati Hort sì rò pe àwọn àpilẹ̀kọ mejeeji yii

lọ́jọ́ lori, tí ó sì gbọdọ jasi pe wọn yoo ṣe e gbarale ju àwọn iwe Giriki ti

wọn lò ninu Textus Receptus lọ.

Awọn Bibeli ode oni lo yẹ ki wọn jẹ́ abajade àwọn ìwakùsà ìgbàlódé ati ẹkọ-ọ̀fẹ́

ìgbàlódé ati àfojúhàn ìgbàlódé. Mo n sọ nipa àwọn ti wọn tilẹ n gbe àwọn Bibeli

igbalode yii larugẹ yoo sọ fun ọ, "Ẹhn, toripe àwọn olùṣèwé ode-oni ní àwọn ohun-elo pupọ ni

arọwọto wọn lonii. Wọn kàn ní àwọn àpilẹ̀kọ ti kò si ni arọwọto

àwọn olùtumọ̀ ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu ni. Idi niyi tí Bibeli ode oni fi dara ju",

ni wọn maa sọ. Idi tí wọn fi n sọ eyi ni nitori awọn àpilẹ̀kọ ti a ti fa

itumọ awọn Bibeli igbalode yọ, awọn bí i, ẹ̀dà NIV, abbl., ní awọn itumọ ọrọ tuntun

wọn ti bòmọ́lẹ̀ fun ọpọ ọ̀rúndún. Ni bayii, jẹ́ ki n ṣe ibeere kan. Ṣé o gbàgbọ́

pe Bibeli ojúlówó jẹ́ bíbòmọ́lẹ̀ fun ọpọ ọ̀rúndún?

[àwọn ìjọ] Rara o.

-Mo n sọ pe n jẹ́ iwọ lero pe Ọlọrun yoo gba ki àwọn eniyan rẹ̀ maa lo

Bibeli tí kò dára fun aimọye-mọye ọdun bí, ati pe lojiji ni àwọn ọdun

inu , ni a tó maa rí àwọn àpilẹ̀kọ to tọ̀nà?

Eyi kò mọgbọn Kankan dání.

Mo ni Ọlọrun ṣe ileri lati pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ ni gbogbo irandiran, sugbọn wọn

gbàgbọ́ pe ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ipo ojúlówó rẹ̀ wa ní bíbòmọ́lẹ̀ nibi kan ati

pe fun àwọn ọpọ ọ̀rùndún, ni gbogbo eniyan n kà, ti wọn sì n waasu, tí wọn tun n gbàgbọ́

ohun ti kò tọna, tí wọn wa n dupẹ fun Ọlọrun fun ìwakùsà awọn ọdun inu

lati hu àwọn àpilẹ̀kọ tuntun jade, otito ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti o ti wa ní ìbòmọ́lẹ̀ fun

àwọn ọdun yii. Wò ó, bí ó bá gba Ọlọrun ní ọpọ àkókò ati laala lati fun wa ni

ọ̀rọ̀ Ọlọrun nipasẹ àwọn wolii ati àwọn iranṣẹ mimọ Ọlọrun tí n sọrọ bi wọn

ṣe gba ìmísí Ẹmi-mimọ laarin àwọn ọgọrun, bẹẹ ni, ànì ẹgbẹẹgbẹrun ọdun,

tí ó sì jẹ́ kí ó wà ní bíbòmọ́lẹ̀ bẹẹ?

Rara, àwọn wọnyi ti a ṣẹṣẹ hú jade laipẹ yii, àwọn tuntun yii, awọn apilẹkọ tó tún daraju

yii, awúrúju ni wọn jẹ́. Wọn ni orukọ bi i Codex Vaticanus. Nisinsin yii, hmm, kini eyi

mú wá sí iranti? "Codex Vaticanus".

-Nitoripe wọn rí i ninu ilu Vatican tabi pé ó ni i ṣe pẹlu ilu Vatican,

ní temi, o mú kí n furasi i ni kiakia.

Bẹẹ ni.

-Awọn bí i ẹgbẹrun marun-le-ni-igba àjákù Giriki ati àwọn abala ẹsẹ Majẹmu

Tuntun tó wà fun kíkà.

-Ẹhn, ẹhn

Àwọn marundinlaadọta laarin àwọn ẹsẹ naa ló sì jẹ́ pe àwọn onitumọ maa n lo fun

eyikeyi tí kì í ṣe ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu.

Eyi ni ida kan ninu ọgọrun àwọn apilẹkọ tó wà

tí ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu sì lo ìdá mọkandilọgọrun un awọn tó lé ní ẹgbẹrun marun un naa tí wọn fi n ṣe itumọ.

Idi naa niyi tí a fi n pè é ní iwe gbogbogbòò. Ó ni lati tun sakiyesi

pẹlu - ati pe emi kò rò pe wọn mẹnuba eyi lọpọ igba - ninu àwọn iyinrere

gan an, laarin Sinaiticus ati Vaticanus naa, àwọn tó lé ní ẹgbẹrun mẹta

ìyàtọ̀. Bawo ni a ṣe fẹ́ mọ̀ eyi to jẹ́ ìyàtọ̀ tó pé, tabi ẹsẹ

pípé tó yẹ fun lilo afi ti àwọn orisun mẹtalelogoji miran ba le fidi rẹ̀ mulẹ pé

wọn nlo? Sugbọn bi mo ba ni apilẹkọ meji, A ati B, tí wọn tako arawọn ninu iyinrere

nìkan ní bí ọna ẹgbẹrun mẹta, bawo ni mo ṣe fẹ́ mọ̀ eyi tó dara? Tori naa, wemi yoo

kúkú ní igbẹkẹle ninu ìjẹgàba àwọn apilẹkọ naa

tó fun wa ni Textus Receptus.

-Bi a ba ri ohun ti a ti bòmọ́lẹ̀ tó sì sọ ohun miran yàtọ̀ si

ohun ti a ti gbà, Iwe ti a Gbà, Textus Receptus, ṣe o mọ̀,

Bibeli naa tí àwọn eniyan ti lò fun ọpọ ọdun, eyi ni lati jẹ́ awuruju.

Ko le jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun bi Ọlọrun kò ba dá a sí. Wọn kàn n kọ

ẹgbẹẹgbẹrun Bibeli silẹ ni gbogbo oriṣiriṣi ede ti gbogbo wọn n sọ

nnkan kannaa. Dipo, wọn maa lọ pẹlu Codex Vaticanus, Codex

Sinaiticus, nitori ojú ti wọn fi n wò wọn ni pe, wọn ti wà siwaju. Ó dara, Sugbọn nitori

pe wọn ti wà tipẹ kò sọ pé wọn dára. Kò tumọ sí pé wọn kì í ṣe

awúrúju. Wò ó. Paulu sọ fun wa ni Kọrinti pe àwọn eniyan n ṣe

idibajẹ wọ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọrun koda nigba ayé rẹ̀. Ni Tẹsalonika ni wọn

ti bẹrẹ sí ní kọ Bibeli èké ti wọn díbọ́n pé ti Aposteli Paulu ni awọn jẹ́.

Ni Ifihan , Ọlọrun n kìlọ̀ fun àwọn eniyan ti yoo gbiyanju lati

yọ kuro tabi fikun ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ni bayii eyi ti n ṣẹlẹ. Nitori bẹẹ,

nitori pe o ti ní apilẹkọ kan tí ó ti wà lati igba ọdun lẹyin Kristi, ẹh,

ko si ọna ti wọn fi le ṣe àparútu rẹ̀, ṣe lootọ? Wọn le ṣe bẹẹ o.

Ati pe wọn pọ̀, gẹgẹ bi Bibeli ṣe sọ fun wa, pe wọn ṣe àdàlú ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

Wọn kì í ṣe diẹ, awọn pupọ ni.

-Awọn apilẹkọ meji yii kò dá duro.

-Bẹẹ ni

Lode oni, atẹjade Kejidinlọgbọn Nestle Allen, atunṣe kẹrin UBS, àwọn

ibi meloo kan wà, tí kì í ṣe pé Sinaiticus kàn takò ó Vaticanus nìkan,

bi ó tilẹ jẹ pe ọpọ igba ni wọn ṣọ̀kan, wọn kò da duro ti a ba n sọ nipa

‘’papyri’’. Ojuṣaaju ti kò dọ́gba lati ọdọ Westcott ati Hort fun Aleph ati B.

Sugbọn wọn ti n ṣiṣẹ ṣiwaju ‘papyri’ pẹlu.

Ohunkohun tó siwaju ‘’papyri’’ lonii kò tilẹ kúkú já mọ́ nnkan kan.

-Ọjọ ti lọ lori rẹ̀ nitori àwọn àfojúhàn àwọn ọ̀tun àpilẹ̀kọ?

-Àwárí papyri, to jẹ́ pe lati ilẹ̀ Egypti ló ti wá

ati àwọn oriṣiriṣi ibomiran...

Alexandria jẹ́ ilu kan ni Íjíbítì, Íjíbítì jẹ́ orilẹ ede kan ninu Bibeli to jẹ́

pe a saaba maa n mọ̀ pẹlu ìwà àìmọlọ́run tabi ẹsẹ tabi ìwà-àìtọ̀. Fun apẹẹrẹ, ní

Ifihan :, Bibeli ka bayii, "Oku wọn sì wà ní

igbooro ilu nla naa, ti a n pe Sodomu ati Egipti ní ti ẹmi,

nibi ti a gbe kan Oluwa wọn mọ́ agbelebu." Bi Ọlọrun ba fẹ́ lo ibikan ninu

Bibeli lati fi ṣe akawe buburu, lati ṣe akawe eyi àìmọlọ́run ati ti

satani, oun a maa lo Íjíbítì lati ṣe akawe naa. Ninu Bibeli, Íjíbítì jẹ́ àpẹẹrẹ

ohun buburu, ti aimọlọrun.

-Kíkà àwọn apilẹkọ akọkọ naa, oju-ewe , oju-ewe , oju-ewe , ti

fidi rẹ̀ mulẹ, ó sì ṣagbejade rẹ̀ pe ìsọwọ́kọ̀wé ti a ba ninu Sinaticus

ati Vaticanus kì í ṣe àwọn nikan ló ni iru rẹ̀. Mo n sọ pé àwọn èródìmọ̀ kan n lọ kiri bayii

pe àwọn wọnyi jẹ́ eyi tí Katoliki Romu ti fi dudu-pe-funfun, ati fun iru àwọn yooku

ìsọnu bi eyi.

-O lee ma ro pe ẹ̀dà NIV jẹ́ Bibeli Katoliki, ati wọn yoo sì sọ fun ọ pe,

"ah, ti ajihinrere ni; awọn Onitẹbọmi ló wà fun." Sugbọn ṣe o mọ̀ nnkan? Mo maa

fi han ọ gbogbo ilana Katoliki ti o yọ jade nitori ó wá lati ọdọ àwọn

apilẹkọ Katoliki. Wọn ti yọ Iṣe Aposteli : kuro ninu àwọn ẹ̀dà Bibeli ode oni

nitori ó tako iribọmi ọmọ ìkókó.

-Eyi ni eredi ti a kì í fi ṣe iribọmi ọmọ ìkókó. O mọ̀ idi? Nitori gẹgẹ bi

Bibeli ṣe sọ, kilo n ṣe idiwọ fun mi lati ṣe iribọmi? O ni lati gbàgbọ́,

kí o sì ṣe iribọmi. Ọmọ ìkókó ko le gbàgbọ́. Ọmọ ìkókó kò tilẹ kúkú ní idalẹbi.

Bi ọmọ ìkókó bá kú, ọrun ni yoo lọ. Sugbọn Katoliki le ka eyi bayii ko sọ pé,

"Bẹẹ, iribọmi ìkókó, tẹ siwaju. Kilo dami duro lati ṣe iribọmi?"

"Kosi. ẹjẹ́ ka sa ri bọmi." Rara, nnkan kan n da ọ duro lati ṣe

iribọmi. Ìgbagbọ ni. Kò kàn sí ninu Bibeli rẹ̀ ni.

-Awọn Katoliki n kọ ilana kan pe Maria jẹ́ wundia sibẹ ní gbogbo ọjọ

aye rẹ̀. A ti mọ̀ pe kò rí bẹẹ, wundia ni Maria jẹ́ nigbati ó fi

bi Jesu Kristi, Sugbọn Bibeli jẹ́ kó yé wa pe lẹyin rẹ̀, ó bi àwọn

ọmọ miran. Ká má purọ, Bibeli darukọ àwọn mẹrẹẹrin aburo-kunrin Jesu: Jemiisi, Jose,

Juda, ati Simoni. Ó fun wa ni àwọn orukọ àwọn arakunrin rẹ̀, tí o sì sọ pé,

"àwọn arabinrin rẹ̀, ṣebi wọn wà pẹlu wa? Nibi yii, Jesu ni àwọn aburo meje, ó kere tán

boya wọn tilẹ ju eyi lọ. Bayii ẹ̀rí nla kan niyi nibi ní Mateu :-. "Nigba ti

Josẹfu dide ninu oorun rẹ̀, o ṣe bi angẹli Oluwa ti wi fun un;

o si mu aya rẹ̀ sọdọ: oun ko si mọ̀ ọ́ titi o fi bi akọbi rẹ̀

ọmọkùnrin: o si pe orukọ rẹ̀ ni JESU," Kò sọ pé Josẹfu kò ba ni

àṣepọ lọkọ-laya paapa o. Ó kàn sọ pe wọn kò àṣepọ lọkọ-laya titi ó fi bi ọmọ

àkọ́bí ọ̀kùnrin rẹ̀. Ó sọ ni ẹsẹ ninu ẹ̀dà NIV. "Sugbọn ko bá a ní aṣepọ

ninu igbeyawo wọn titi o fi bí ọmọkunrin kan. Ó si pe orukọ rẹ̀ ni Jesu."

Kilo sọnu nibi? "Àkọ́bí".

Bi Jesu ba jẹ́ àkọ́bí ọmọkunrin Maria, eyi sọ fun mi pe ọmọ-keji wa.

Sugbo ẹ̀dà NIV yọ eyi kuro ki ẹ ba le sọ pé, ṣé o mọ̀, ọmọ kansoso tó bí

naa niyi. Ilana miran ti ìjọ Katoliki ti ẹ̀dà NIV naa ṣegbe lẹyin rẹ̀

ni ìlànà nà-ara-rẹ. Ẹhn, bẹẹ ni, o gbọ mi daadaa.

Nina-ara ẹni tabi fún-ara rẹ-lẹgba.

Bó ṣe rí yii, àwọn ọrẹ Katoliki rẹ̀ ti o mọ̀ ni Ilẹ Amẹrika le ma

na ara wọn. Sugbọn ninu gbogbo itan, Ijọ Katoliki Romu maa n

kọni bẹẹ tí wọn sì n ṣe kóríyá fun nà-ara-rẹ-lẹgba, o dara? Ni pato, nigbati

Hẹnri Kẹjọ fi ofin de Katoliki ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí ó sì le ìjọ Katoliki

Romu kuro ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ni àkókò yii kan naa ó tún naa ṣe ofin lòdì sí nina-ara

-ẹni. Lode oni ẹ̀wẹ̀, ni ilẹ Filipin, àwọn Katoliki tootọ maa

n na ara wọn lonii ni ọdun . Ni ilẹ Filipin wọn n kan ara wọn mọ́ agbelebu;

wọn n na ara wọn; wọn a maa n rákòrò lori orúnkún wọn titi yoo fi ṣe ẹjẹ.

Mo sọ pé wọn n ṣe iru ìṣe yii si ara wọn. Wo ohun ti Bibeli sọ ni

Kọrinti :. "Sugbọn mo rẹ ara mi silẹ, mo si n mu wa sabẹ itẹriba: pe

lẹyin igbati mo bá ti waasu fun àwọn elomiran, ki emi funrami maṣe

di ẹni itanu," ẹ̀dà NIV sọ pe,"Mo na ara mi". Ati ọpọ àwọn ẹ̀dà ode oni

sọ iru nnkan bayii ni ọna bi, "Mo na ara mi..."

-Rẹ̀ sílẹ̀.

-Rara, wọn ko sọ pé "rẹ̀ sílẹ̀". Wọn ni "Mo nà".

-Rara, ohun ti ẹ̀dà NET sọ niyen.

-O dara o. Sugbọn mo n sọ fun yin, ẹ̀dà NIV sọ pe, "Mo na ara mi". Itẹjade

ti ẹ̀dà NIV sọ pé, "Mo n lu ara mi ní kùmọ̀".

"Mo n jẹ́ ara mi níyà".

-Má lero pe mo maa gbèlẹ́yìn ẹ̀dà NIV.

-Ó dara. Oun ni ẹ̀dà tó n tà julọ ni ilẹ Amẹrika ni .

-Mi o gba eyi gbọ,

-Mo wo ọpọ ibi-itaja. -Mo lero pe ẹ̀dà ESV...

-Oun ló n tà julọ.

-Bẹẹ, Ó dara, bi o ba fi ….. kún un

Ẹ̀dà ESV ni ẹkarun. Ati pe mo ṣe ọpọ iwadii lori eyi.

-Bi o ba safikun àwọn ìjọ alaibikita, boya.

-Ni Kọrinti :, o kò ni gbèlẹ́yín ẹ̀dà NIV "nina ara rẹ"?

-Rara o.

-Nitori ti Katoliki ni. Mo n sọ pé Ijọ Katoliki, ó daarọ!

-Ah, ma sọ bẹẹ... Kì í ṣe ibi tó ti wa niyi.

-Duro ná. Ṣé o fẹ́ sọ pe

àwọn Katoliki ki i na ara wọn titi di oni?

Wọn ki n ṣe ìlànà nina-ara ẹni? Ṣé o fẹ́ sọ pe Hẹnri Kẹjọ...

-Awọn kan n ṣe bẹẹ; ọpọ wọn kì í tilẹ wa fun ijọsin.

Wọn ko ni maa na ara wọn lẹ́gba.

-Bawo ninu àwọn itan? Bawo ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nigbati Hẹnri Kẹjọ le àwọn

Katoliki jade, tí ó sì sọ nina ara rẹ ni di ohun ti kò bofin mu ni ọdun kannaa?

-Sugbọn Steven, kini eyi ni i ṣe pẹlu àwọn to tumọ ẹ̀dà NIV?

Ṣé o rii, nitori Romu ti ṣe e tẹlẹ ṣẹyin

ko sọ pe ohun ti wọn fẹ́ sọ niyen.

-Ohun ti mo n sọ ni pe Satani ni Satani yoo sì maa jẹ́, ó dara? Satani yii kan naa ló n jẹ́ ki àwọn

eniyan lati maa na ara wọn ní Sáà Ìyálẹ̀ta-ayé, Satani yii kannaa ló fi ẹsẹ naa sinu

ẹ̀dà NIV pe ko maa na ara rẹ. Ibi yii ni mo ti fẹ́ so gbogbo rẹ̀ papọ.

-Ṣé o mọ̀, kódà pẹlu bi a ṣe kọ ọ́ sinu ẹ̀dà NIV, o fihan gbangba pe ohun ti o n sọrọ

nipa rẹ̀ yii, dajudaju, afiwe-taara ni.

-Ó dara, ní ti ẹ̀dà Amplified. Emi kò mọ̀ tirẹ o, Sugbọn ẹ̀dà Amplified

ti maa n pariwo ju fun mi. Emi kì í tilẹ rí ojútùú rẹ̀. Sugbọn, tẹ́tí sí

ẹ̀dà Amplified "Sugbọn [bí akànṣẹ́] Mo na ara mi". Bayii jẹ́ ki n bi

yin leyi: Ṣé o ti ri akànṣẹ́ kan tó n na ara rẹ̀ rí? Nitori emi kò rí i rí.

Bibeli Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ kò tilẹ rọrùn pupọ lati ye ọ, ṣebi

nitori idi naa ti ẹ fi fẹran àwọn ẹ̀dà Bibeli ode-oni naa niyi, nitori wọn rọrùn lati

kà ní àkàyé? "Dipo bẹẹ, mo n rọjo ẹsẹ le ara mi, mo sì n rẹ̀ ẹ́ silẹ bi i

ẹrú. "Wò ó, nína ara rẹ ki ṣe ìlànà Bibeli. O sì wá sọ pé, bẹẹ,

ó kàn n ṣapejuwe ni.

Bẹẹ, kini ka ti sọ ti gbogbo àwọn eniyan tó maa n nà ara wọn?

Ilana òdì leyi, ọ̀rẹ́ mi. Mi o gbàgbọ́ ninu rẹ̀.

Bibeli sọ ninu Mateu :, "Ati pe nigbati ẹyin ba ngbadura, ẹ ma ṣe atunwi asán,

bi àwọn keferi: wọn ṣebi a o titori ọ̀rọ̀ pupọ gbọ ti wọn"

Ni bayii, Bibeli kọ wa nihin lati kí a má ṣe awitunwi asan

mọ́, a maa n lero pe bi a ba n sọ ohun kan lera lera, Ọlọrun yoo gbọ

wa, ju bi a ba sọ lẹẹkan soso.

Kinni àtúnwí? Sisọ ohun kan naa ni ẹẹmeji, tabi ẹẹmẹta, tabi

ẹẹmarun. Ó n sọ pé wò ó, maṣe lo àẃitúnwí asan gẹgẹ bi àwọn alaigbagbọ ti n ṣe. Ṣé o gbọ,

Ni idakeji, ẹ̀dà NIV - ati gbogbo ẹ̀dà ode oni ni wọn ti ṣe ayipada

eyi - "Ati bi o ba n gbadura, maṣe má sọ kántankàntan bi alaigbagbọ, nitori wọn lero pe

a o gbọ wọn nitori ọ̀rọ̀ pupọ wọn."

"Kántankàntan" ni bi o ba n sọrọ nipa àwọn ohun ti kò já mọ́ nnnkan kan lera

lera, àlésọ̀ lasan ni eyi. Kì í ṣe ọkan naa pẹlu àtúnwí asan.

Bi mo ba sọ fun ẹlẹ́sìn Katoliki kan, "Ṣe o mọ̀ pe aimọye igba ni o maa gba adura

‘’Baba wa ti n bẹ ni ọ̀run’’ lera lera ati lera lera. Ọlọrun kò ní í tori bẹẹ

gbọ ọ nitori ọ̀rọ̀ pupọ rẹ̀. Eyi ni àtúnwí asan. O ni lati sọ eyi

lẹẹkan ṣoṣo, kí o sì pari rẹ̀ sibẹ, kì í ṣe pe kí o maa ṣe àtúnwí ohun kan naa leralera

ati lera lera. "O mọ̀, Mateu : ṣe atilẹyin eyi, Sugbọn ti mo ba sọ

fun wọn, "Ó yá, dẹ́kun kántankàntan bi alaigbagbọ́, wọn a sọ pé, "Kò buru

eyi kì í ṣe kántankàntan." Wọn a sọ pe, "Adura Oluwa jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun"

Nitori pe ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ẹhn? Eyi kọ́ ni yoo mu mi sọ ọ́ di kéú tabi kí n maa ṣe àtúnwi

asan sí Ọlọrun, Sugbọn Ijọ Katoliki n kọni ni àtúnwí asan,

nitori bẹẹ, wọn ti ṣe ayipada.

Eyi nikan kọ, Sugbọn àwọn Katoliki ni ìlànà lile jíjẹwọ ẹ̀sẹ̀ rẹ

fun Alufa. Wọn yoo sì mu ọ lọ sí Jakọbu :, àlàyé-ààrin kan nbẹ ninu

Bibeli Katoliki ti n sọ pé o ya, ẹsẹ yii n sọ fun ọ pe kí ó

jẹwọ ẹsẹ rẹ fun alufa. Ó sọ pe, fun apẹẹrẹ, ninu alaye-aarin ẹ̀dà Bibeli Katoliki ti

Doway Rheimes. Ohun ti ó sọ niyi. Jakọbu :; "Jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀

rẹ fun ara yin, ati gbadura fun ara yin, ki ẹyin le gba iwosan.

Adura ìtara olododo ni agbára pupọ." Tilẹ gbọ,

nnkan ti ẹ̀dà NIV sọ ati àwọn ẹ̀dà igbalode yí eyi pada sí: " Bakanaa, ẹ jẹwọ àwọn

ẹ̀ṣẹ̀ yin fun ara yin, kí ẹ sì gbadura fun ara yin ki ẹ le gba iwosan.

Adura olododo jẹ́ Alagbara, ó n ṣiṣẹ." Eyi ni NIV,

Ni isinyi, o sọ pe, "O dara, ohun kan naa ni." Sugbọn kì í ṣe ohun kan naa.

Ni àkọ́kọ́, bi o ba pada si ede ìpìlẹ, bi o ba si pada si ohun

ti o sọ gan an ni ede Giriki, "àṣìṣe" ni wọn lò nibẹ ; kì í ṣe "ẹ̀ṣẹ̀".

-Ninu Textus Receptus, eyi lo ọ̀rọ̀ naa fun àṣìṣe, "paraptomata", ti o

wa lati paraptoma," to tumọ si " àṣìṣe". Mo sì lero pe nigba miran àwọn eniyan,

nigbati wọn ba ka nnkan tí kò tọ̀nà nibẹ, wọn yoo maa sare lọ jẹwọ gbogbo

ẹ̀ṣẹ̀ wọn fun eniyan, dipo pe ki wọn rò ó fun Ọlọrun, Nitori ‘’Bi a ba jẹwọ ẹsẹ wa, o

jẹ́ olotito ati olododo lati dariji ẹsẹ wa, ati lati we wa kuro ninu

aisododo wa," ti mo ba jẹwọ àṣìṣe mi fun ọ nigbati mo ba sọ pe, mo jẹ

alailagbara ni abala kan ni igbesi aye mi, Mo nilo lati gba agbara. Ṣé o le gbadura fun

mi?" Bayii nigbati mo ba jẹwọ àṣìṣe mi fun ọ, emi kò ní lọ fun íjẹwọ, bẹẹ ni n kò ní í

jẹwọ ẹsẹ mi fun ọ, Sugbọn mo jẹwọ àwọn àṣìṣe ati àwọn ibi ti

emi kò ti lagbara, bayii ìyàtọ̀ n bẹ ninu òye àwọn ọ̀rọ̀

naa "ẹ̀ṣẹ̀" ati " àṣìṣe" funrawọn.

-Kristiẹni Ajihinrere ninu itan ko gba àwọn ẹ̀sìn Katoliki gẹgẹ bi

Kristiẹni tootọ. Ó waye nigbati mo jẹ́ ọmọde pe Ile-Itawe Kristiẹni maa ni

àwọn iwe ati litiresọ to n tu asiri ìjọ Katoliki, to n kilọ fun ọ nipa

ìjọ Katoliki. Bayii iwọ lọ si ilé-itawe Kristiẹni, wọn n ta

ilẹkẹ adura; wọn n ta Bibeli Katoliki; wọn n ta àwọn nnkan Katoliki.

Ohun ti a n ri ni pe kò si ila laarin àwọn Kristiẹni Ajiyinrere ati àwọn

ẹlẹ́sìn Katoliki mọ́. Awọn eniyan ni wọn ti n gbaradi fun ijọba agbaye kan tí

yoo kó ẹlẹ́sìn Katoliki pọ̀, gbogbo ìjọ ẹlẹ́sìn Kristiẹni,

Ni kókó, gbogbo ẹ̀sìn lagbaye.

-Awọn to ba n wa àjọ ẹ̀sìn agbaye gbàgbọ́ pe gbogbo ẹ̀sìn,

bi ó tilẹ yàtọ̀ lójú, jẹ́ ọ̀kan kan tó tọ ninu awọn ọna si Ọlọrun.

-Dipo gbogbo àwọn oriṣi oriṣa, boya Ọlọrun kan wa to farahan

funrarẹ̀ tí yoo sì àwọn eniyan ni orisirisi ọna.

O mọ̀, bawo ni eyi, ẹhn?

-Ṣé gbogbo wa n sin Ọlọrun kan naa bí, Kristiẹni ati Musulumi?

-Mo ro bẹẹ. A ní orisirisi ọna si Olodumare.

Ṣé Kristiẹni ati alaigbagbọ, ṣe Musulumi n lọ si ọ̀run, ninu ọkàn rẹ̀?

-Bẹẹni wọn n lọ. A ní oriṣiriṣi ọna lati de ibẹ.

Mo lero pe gbogbo eniyan to fẹ́ Kristi, tabi mọ̀ Kristi, boya wọn

mọ̀ tabi wọn ko mọ̀, wọn jẹ́ ará ninu Kristi, eyi sì ni

Ọlọrun n ṣe lonii: Ó n pe àwọn eniyan jade ninu aye fun orukọ rẹ̀, boya

wọn wa lati ọdọ àwọn Musulumi tabi ẹlẹ́sìn Buddha tabi lọdọ àwọn Kristiẹni tabi

àwọn alaigbagbọ, wọn jẹ́ ara ninu Kristi nitori

Ọlọrun ti pe wọn. Wọn le ma tile mọ̀ orukọ Jesu, Sugbọn wọn

mọ̀ ninu ọkàn wọn pe awọn nilo nnkan ti wọn kò ní, wọn a sì

yipada si imọlẹ kan ti wọn ni

Mo si lero pe a gba wọn la

ati pe wọn maa wà pẹlu wa ni ọ̀run.

-Titi emi oo fi papódà, emi kò ni waasu ohun kan ju ifẹ fun arakunrin ati arabinrin

ninu Kristi: àwọn arakunrin ati arabinrin Katoliki, arakunrin ati

arabinrin Bẹẹ-kọ-ló-yẹ-kórí, Kristiẹni Alatunṣe, àwọn ti Luther. Emi kò mọ̀ ti tìrẹ.

-Ati pe o mọ̀ nnkan Jack, ọpọ àwọn ojiṣẹ Bẹẹ-kọ-ló-yẹ-kórí ni n bẹ

tí wọn n ṣe ohun kan naa bi iwọ pẹlu. -Bẹẹ ni.

-O faramọ Vatican bi?

-Oh Mo faramọ Vatican. Mo ti lọ rí Poopu.

ni ọpọ igba. Wọn gbàgbọ́ ninu Kristi. Wọn gbàgbọ́ ninu iku Kristi lori

agbelebu ati ajinde rẹ̀. Mo ro pe mo pẹlu gbogbo àwọn ìjọ naa. Mo wà ni

ilé ni ìjọ Anglikan tabi ìjọ Onitebọmi tabi ìjọ Arakunrin tabi

ìjọ Katoliki.

-O mọ nnnkan, a ko ni afojusun kannaa ati pe olusin Mọmọọni, kì í ṣe

asa ẹ̀sìn Kristiẹni, Sugbọn mo lee mọ̀ diẹ sii ati pe mo le gba koko

pe bi eniyan ba fẹ́ Jesu to si gbàgbọ́ pe

ọmọ Ọlọrun ni, eyi naa dara fun mi.

-Robert McGuiness pẹlu Ajo Iwadii Idile sọ pe ó jọ pe

erongba to farasin kan wa lati so àwọn eniyan papo sabe ẹ̀sìn kansoso ki wọn

le gba eto U.N. ni alaafia bii ifẹto si iye eniyan, eto iṣẹyun,

ati ijọba agbaye kan.

-Gbogbo wọn n papo gẹgẹ bii ọ̀kan labe aṣẹ Lusiferi..

-Esu mọ̀ pe lati jẹ́ ki àwọn eniyan gba Ààtò Ayé-Dọ̀tun, lati

gba ẹ̀sìn eke, o ni lati ṣe awọn ayipada diẹ diẹ. Ko nii

ja owo moto gba. Esu n ṣe were were mu kuro lara àwọn ipile

ẹ̀sìn wa. Esu n ṣe were were mu kuro lara ipile

ọ̀rọ̀ Ọlọrun. O n ṣe were were mu kuro lara otito Bibeli Kristiẹni ki o le

fi ẹ̀sìn agbaye tuntun rọ́po rẹ̀ ni ibi ti asodisi-kristi yoo

maa gba ijọsin bii Jesu Kristi Oluwa.

-Ṣé o gbàgbọ́ pe ninu ẹ̀dà Bibeli ode oni

a ko ipa ninu Ààtò Ayé-Dọ̀tun naa?

-Sugbọn ṣá, Mo ro pe ó ṣeeṣe, nitori bi àwọn itumọ ṣe n jade sii,

bẹẹ ni wọn dabi wọn turaka si lati da bẹẹ, kí ó di atewọgba si i

gbogbo eniyan. Sugbọn ó ti le ni igba bayii. Igba le diẹ.

dípò rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀sìn àgbáyé titun kan níbití wọn yóò ti jọsin fún asòdì-sí-Kristi

gẹ́gẹ́ bíi Jesu Kristi Olúwa.

-Ǹjẹ́ o gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀dà Bibeli ti òde-òni

Ni yóò ní ipa láti kó nínú ààtò ayé dọ̀tun náà?

-Èmí rò pé èyí seése, Nítorí bí ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ se ń jáde síi

bẹ́ẹ̀ni àyè ń gbà wọn síi láti di ohun ìtẹ́wọ́gbà fún

gbogbo ayé. Sugbọn iye wọn ti ju igba lọ bayii. Igba-ó-lé

dípò rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀sìn àgbáyé Tuntun kan nibiti wọn yóò ti jọsin fún asodi-si-Kristi

Gẹ́gẹ́ bi Jesu Kristi Olúwa.

Ǹjẹ́ o gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀dà bibeli ode-oni

Ni yóò ní ipa láti kó nínú ààtò ayé-dọ̀tun náà?

-Èmí rò pe èyí ṢééṢé, Nítorí bi ọ̀pọ̀ itumọ Ṣé n jade sii

bẹ́ẹ̀ni àyè n gbà wọn sii láti di ohun ìtẹ́wọ́gbà fún

gbogbo ayé. Sùgbọ́n iye wọn ti ju igba lọ Báyìí. Igba-ó-lé

Àti nínú awọn ìtumọ̀ yìí a ní àwọn ènìyàn tí o n fi ìtumọ̀ fún

àwọn akọ ń saya akọ ti abo ń ṣọkọ abo , a ní àwọn ènìyàn tí ó fi ìtumọ̀

tí wọn yóò fi ohun tí kò ní ẹ̀mí dípò ohun tó ní ẹ̀mí

nìtorìbẹ́ mo rò pé nínú àwọn ìtumọ̀ òde-òní àti awọn èyí ti o sẹ̀sẹ̀ ń jade tí wọ́n si

bẹ̀rẹ̀ sí ní gbilẹ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n sí̀ fi àyè gba orisirisi ẹ̀sìn

àwọn ènìyàn àti orisirisi ìgbàgbọ́ láti pàdé tí wọn kò sì bínú sí èyíkèyí nínú wọn.

Èyí jẹ́ ohun tí gbogbo ìjọ àgbáyé gbàgbọ́. Bẹ́ẹ̀ni

Ìfohùnsọ̀kan gbogbo ìjọ àgbáyé wà lára àwọn ìsẹ̀lẹ̀ òpin ayé

Ẹ̀dà Bibeli ti ọba Jakobu lo ọ̀rọ̀ “ọ̀run àpáàdì” ní ìgbà mẹrinlelaadọta

ohun tí mò ń sọ ni yìí, ti o ba ka ìwé majẹmu lailai ti ẹ̀dà NIV, a kò ti lẹ̀ mẹ́nuba

ọ̀rọ̀ “ọ̀run àpáàdì” ràrà. A kò tilẹ kà nípa ọ̀rọ̀ “ọ̀run àpáàdì” ràrà nínú ẹ̀dà Bibeli ti NIV

títí dé ìwé Mateu. Tí a ba tilẹ̀ sọ pe a kọ àwọn ẹ̀dà Bibeli Tuntun yìí

Kí o lè rọrùn láti ni òye rẹ̀. Sùgbọ́n síbẹ, tí a bá bèrè lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni

ní òpópónà ohun ti ọ̀run àpáàdì jẹ̀, wọn yóò le sọ fún wa pé ọ̀run àpáàdì jẹ̀ ibi

iná àti ìfìyàjẹni. O jẹ ibi ti àwọn ènìyàn ma ń lọ lẹyin ikú láti jẹ ìyà

kí a si pọ́n wọn lójú. Tí a bá bèrè lọ́wọ́ wọn ohun ti ̀ipò-òkú túmọ̀ sí

Ọpọ ènìyàn ni kí yóò mọ̀ ọ́.

Kíni ọ̀rọ̀ tí à ń pè ni ipò-òkú túmọ̀ sì?

Asà? asà jẹ́ ohun ti n dáàbò bo ni.

Wí bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kanśii. ipò-òkú.

Kíni ? pè é jade.

IPÒ-ÒKÚ…Èyí kò da mi loju. Ràrà

-Ràrà

-Ràrà

-Ràrà ̀Èmi kò rò bẹ́ẹ̀.

-Ràrà

-Ràrà

-hun, ràra.̀

èmi kò mọ̀

Ipò kíni? IPÒ-ÒKÚ: ipò-òkú.

Ràrà. O, ipo-oku? Ràrà

n kò le é rántí rẹ ràrà.

IPÒ-ÒKÚ? Kò dámi lójú. Èmi kò rí ọ̀rọ̀ yìí rí.

--Ràrà, n kò fi bẹ́ẹ̀ mọ èyí.

Ó dára, bẹ́ẹ̀ni. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ yìí

Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi rọrùn ju ọ̀rọ̀ “ọ̀run àpáàdì”

-Ràra.̀. Ó dára.

Mo gbàgbọ́ pé ẹ̀dà bibeli ti Ọba Jakobu ni ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run. Mo gbàgbọ́ pé kò

ní àsìṣe kankan rárá mo sì tún gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀dà míràn tí ó ń jade – ẹ

mọ èyí, ẹ̀dà ti NIV, ẹ̀dà Tuntun ti Amerika- pe wọn kò dára, pé

tí èsù ni wọ́n. Nínú ìwé yin, ó dàbí ẹnipé ẹ kò ri rárá pé

ìdí búburú kan le wà lẹ́yin àwọn atúnsé wọ̀nyi.Ẹ kò ti lẹ̀

gbàgbọ́ pé è́sú le fọwọkan ọ̀rọ̀ rẹ lailai tabi kí èyíkèyí nínú àwọn

àtúnṢé wọ̀nyí burú jáì, pé èyíkèyí nínú awọn ìyàtọ̀ yìí ni láti Ṣé pẹ̀lú ọkunrin kan

tí o sọ pé, “ Èmi yóò yi èyí padà nítorí mo jẹ ẹni búburú,

Nítorípe mo fẹ yi ọ̀rọ̀ Ọlorun padà.”

Èmi gbàgbọ́ pé Ọlorun ti dá àbò bo ọ̀rọ̀ rẹ̀

Sùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́ pé ó wà- fún àpẹrẹ,ìwọ lo ọ̀rọ̀

“ọ̀tè” bóyá ni ìgbà ogún Nínú ìwé rẹ̀ – ǹjẹ́ iwọ gbàgbọ́

pé kò sí ìgbìmọ̀p̀ọ ìbàjẹ́ láti yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run padà?

Ràrà, èmi rò pé a kọ gbogbo awọn ẹ̀dà bibeli yìí láti yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run padà.

Sùgbọ́n èyí farahàn ní gbangba;ó farahàn dáradára

Sùgbọ́n ó ṢééṢé kí wọn ti wà ní awọn ìgbà kan sẹ́yìn? tí awọn ènìyàn kan bá wà loni ti wọn ń

gbé àwọn ìtumọ̀ kan jade tí à ń pè ni Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, èyí tí ó jẹ́

ìyapa tabi ìṢélòdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run - Ǹjẹ́́ iwọ fara mọ́ ọ?

Agbayé Tuntun, fún àpẹrẹ, wọ́n ́n sàyípadà ̀ọrọ̀ Ọlọ́run ní ìgbà ayé Pọ́ọ̀l̀ù - ó

Kìlọ̀ nípa rẹ̀ - kíló dé tí ẹ kò gbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run padà

nìgbàtí iye ọdún aýe jẹ̀ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta,mẹ̀rin,mẹ́jọ Àti mẹsan ?

-A mò wí pé Ìtumọ̀ ayé òde-òní jẹ́ àyìpadà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó

rọrùn láti mọ̀. Ìdí tí mo fi lo "èrò- d̀imọ̀ ọ̀tẹ̀" ni wí pé o gbọdọ̀

ní ẹ̀rí láti gbe àwọn ǹkan wọ̀nyí lẹ́sẹ̀, kìíṢé pé, ", ó jọ béè lójú

mi." O mọ èyí, àwọn ibi tí ìtumọ̀ aýe òde-òní ti si àwọn ǹkan túmọ̀

jẹ́ kókó ibi tí Bíbélì Watchtower àti àjọ Tract Society ti

tako ẹ̀sìn Kristiẹni ti inú Bíbélì.

-O kò leé ka Jobu : ni Ìtumọ̀ ayé òde-òní.

Kílódé?

-Nítorípé ni Jobu :, nínú Bíbélì ti Ọba Jákọ́bù ó wí pé, "A le

ohun tí kò ni adùn ní aìnì iyọ̀, tàbí adùn wà nínú fúnfún ẹyin?

̀Àti nìnú Ìtumọ̀ Ayé Òde-Òní Ó wí pé, " ǹjẹ́ adùn kán wà

nínú èso marshmallow tí ń yọ̀

Nítoríbẹ̀, Èyí jẹ́ ohun tí wọ́n yípadà tí kò sì ní ohun kan láti ṣe pẹ̀lú

̀ajọ Watchtower! ó dára bẹ́ẹ̀? ohun tí mò ń sọ níbẹ̀ ni pé.....

Ǹjẹ́ ẹ há èyí sórí bí?

Ǹjẹ́ a rí láàrin yín.... Bẹ́ẹ̀ni mo ha sórí

Ìwọ́ há èyí sórí bí?

Nkò tilè mọ̀ pé marshmallow ní èso tí ń yọ̀.

Àní tí ẹ bá ní Ìtumọ̀ Ayé Òde-Òní

-Sé kò le sí ète láti ṣẹ̀dá àtakò, láti kàn jẹ́ kí...

-Wọn kò ní...

-...tàbí láti fi àwọn ohun tí kò mú ọgbọn dání sínú Bibeli,...

-Rárá, rárá, rárá, rárá.

-...láti fi àwọn ohun kan tí kò mú ọgbọn dání sínú Bibeli bíi, "Saulu jẹ́ ọmọ ọdún kan

nígbàtí o bẹrẹ sí jọba"?

- Samueli : nìnù ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu sọ pé, "Saulu jọba fún ọdún kan; àti nígbàtí

ó ti jọba ọdún méjì lórí Israeli..." Ní Ìtumọ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó

yípadà sí, "Saulu wà láàỳe fún ọdún kan lẹ́yìn èyí ó sì di Ọba".

- Samueli : nínú ẹ̀dà ti Duway Rhemes, tí ó jẹ́ Bibeli àwọn Katolikí:

"Saulu jẹ́ ọmọ ọdún kan nígbàtí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba,

ó sì jọba fún ọdún méjì lórí Israeli."

-Ẹ mọ ohun tí ẹ̀sẹ̀ yìí sọ fún wa? ó wí pé Saulu jẹ́ ọmọ-ọdún-kan nígbàtí ó

jọba. Nihin ni ìṣòro wà: Samueli : sọ pé, "Láti èjìká rẹ̀

lọ sí òkè ó ga ju àwọn ènìyàn lọ."Bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì

ti sọ, ó jẹ́ ọmọ ọdún kan nígbàtí ó fi orí àti èjìká ga ju gbogbo àwọn

ọkùnrin lọ. Ọmọ yìí tóbi gan ni.

Mo kàn ń gbìyànjú láti sọ fún ọ pé àwọn Bibeli yìí kò mú ọgbọ́n dání

Nígbà míràn tí mo bá jáde fún ìjèrè-ọkàn tí àwọn kan sì sọ fún mi, "Mi kò gbàgbọ́

nínú Bibeli nítorí àwọn àṣìṣe wà nìnù Bibeli."

Èmí sì wí pé, "Fi ọ̀kan hàn mí"

Wọn yóò sì gbé ẹ̀dà NIV kan jade. Èmi á sì wí pé, "Má fi hàn mí - Èmi pàápàá lè fi

àwọn àṣìṣe tí ó wà nínú rẹ̀ hàn Ọ́. Mo lè sàfihàn àwọn ohun tó tako ara wọn nínú èyí. Fi ọ̀kan hàn mí

nínú ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu. Kò sí rárá."

-Àyípadà míràn tí àwọn ẹ̀dà ayé òde-òní Ṣé, ìwé Galátia orí karùn-ún:

"Èmí fẹ́ kí a ké àwọn ohun tí ó ń yọ yín lẹ́nu kúrò."

Ẹ̀dà ti NIV wí pé, "Ní ti àwọn tí ó ń fi ẹ̀hónú hàn, ó wù mí kí wọ́n lọ

pa ara wọn dànú!"

Nísisìyí ǹjẹ́ èyí jọ ohun ti Bibeli lè kọ́ni tí Aposteli

Paulu sì lè sọ? Ẹ̀yin sì wí pé, "Èmi kò rò pé ohun tí wọ́n túmọ̀ sí nìyí

nínú ẹ̀dà ti NIV." Ǹjẹ́ èyí ni ìdí tí Bibeli Gẹ̀ẹ́sì gbogbogbò fi túmọ̀ rẹ̀ pé,

"Mo fẹ́ kí àwọn tí ó ń yọ yín lẹ́nu sọ ara wọn di òkóbó!"

tàbí kí á tún wo ẹ̀dá Bibeli Gẹ̀ẹ́sì ti òde-òní, CEV? Mo ti rí èyí lórí

igbá ní ilé-ìtàwé Kristẹni, "kìíṢé pé mo fẹ́ kí a kọ gbogbo àwọn tí ó ń yọ yiń lẹ́nu

ní ilà nìkan, Sùgbọ́n kí wọ́n ké kúrò jù bẹ́ẹ̀ lọ!"

Àní ṣé ẹ̀ ń gbọ́ èyí? Nítorí ọ̀rọ̀ yìí "ké kúrò" kò ní ̀nkan

ṣe pẹ̀lú pípa tàbí sísọ ara ẹni di òkóbó tàbí ṣíṢé ara ẹni léṣe.

Paulu ń tọ́ka sí Májẹ̀mú láíláí nípa àwọn ènìyàn tí ó

ṣe àìgbòràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run, pé a ó gé wọn dànù. Ẹ wò ó, nk̀o ní àsìkò láti fi

gbogbo àwọn àpẹẹrẹ ọgọ́rùn-ún-lé-díẹ̀ hàn lórí èyí. Gbogbo ohun tí ó ń sọ níbẹ̀ ni pé a

tì wọ́n sí ìta, Ó fẹ́́ kí á gé wọn kúrò, Ó fẹ́ kí

Ọlọ̀run pa wọn run. Ohun tí "ke kúrò" túmọ̀ sí nìyí. Wọn á di

píparun láti ọwọ́ Ọlọ̀run tàbí "ké kúrò" tún lè túmọ̀ sí pé kí á lé wọn

kúrò nínú ìjọ, lé wọn kúrò láàrin agbo, lé wọn kúrò ní orílẹ̀-èdè

Israeli. Èyí ni ọ̀rọ̀ "ké kúrò", Sùgbọ́n àwọn abàmì yìí pẹ̀lú itumọ̀

ayé òde-òní wọn ń mú kí ó dàbí ẹnipé Aposteli Paulu sọ pé, "Mo fẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí

kàn pa ara wọn dànù. Mo fẹ́ kí wọ́n sọ ara wọn di òkóbó. Mo fẹ́

wọ́n ṣe ara wọn leṣe ." Ohun tí mò ń sọ ni pé èyí kìíṢé ohun tí ò ń kọ́ wọn rárá.

Ó yàtọ̀ gìdígìdí.

Sùgbọ́n kì í ṣe pé àwọn ẹ̀dà túntún yìí ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wèrè tí ó jẹ́ kí

Bibeli dàbí ohun òpè nìkan, wọ́n tún ni kókó ètò láti mú kí àwọn ènìyàn gbaradì

fún ààtò ayé-dòtún. Àti pé ara ìgbaradí náà ni láti tan

àwọn Kristẹni kí wọ́n lè gbọ́ràn sí ìjọba lẹ́nu lábẹ́ àkóso bí-ó-ti-wù-kí-ó-rí. Kókó ẹ̀sẹ̀ tí

wọ́n tí ṣe àyípadà sí ni Romu .

-Mo ní òmìnira láti ṣe ara mi ní ẹrú. Mo ní òmìnira láti fi díẹ̀ sílẹ̀ nínú òmìnira mi. Mo

Mo ní òmìnira ṣùgbọ́n mo ní òmìnira láti tẹríba fún àṣẹ ìjọba mi. Àwọn

ij̀ọba búburú gan ma ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ̀run nípa mímú kí àlááfíà wà ní ìwònba ní òpópónà.

Ìjọba Soviet Union lábẹ́ àkóso Stalin gan náà ń ṣe iṣẹ́ fún Ọlọ̀run.

Orílẹ́-èdè Chiná lábẹ́ àkóso Mao Ze Dong náà ń ṣe iṣẹ́ fún Ọlọ̀run. Bu ọlá fún Ọba. Ṣe bẹ́ẹ̀

láìbìkítà bóyá ó yẹ fún ọba tàbí kò yẹ. Bọ̀wọ̀ fún gominá rẹ; bu ọlá fún

olórí ìlú rẹ, bóyá wọ́n yẹ fún tàbí wọn kò yẹ. Bu ọlá fún ọba.

-Kò śi ẹni tí yóò ní ǹkan ìjà ogun lọ́wọ́. A ó gba gbogbo àwọn ohun ìjà ogun.

[Kìkan ilẹ̀kùn pẹ̀lú arìwọ]

-Lónìí ní New Orleans wọ́n gbójú agan sí àwọn alágídí

Iĺe-iṣẹ́ Ọlọ́pàá! Ṣé e wà nílé?

-Kì í ṣe àwọn ibi tí omíyalé ti ṣoṣẹ̀ nìkan, Ṣùgbọ́n ní àwọn àdúgb̀o New Orleans

tí ó gbẹ jù tí wọn sì lọ́rọ̀ jú, pàápàá.

-Ṣùgbọ́n gbígbé ẹsẹ́ lé àwọn ìbọn ni pàtó ohun tó ṣẹlẹ̀ nìgbàtí a kede "ìlú-kò-fararọ"

lẹ́yìn ìjì líle tí ó ṣẹlẹ̀ ní New Orleans. ̀Awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹrika náà dé síbẹ̀.

Mímú ìbẹ̀rù kúrò àti pípa iná òtẹ̀ yóò ṣe kókó, èyí sì ni pàtó ohun

ti ́ẹgbẹ́ ìrànwọ́ ti àwọn òjíṣẹ́ Ọlorun gẹ́gẹ́ bí a Ṣé ń pè wọ́n

mú kí ó ṣeéṣe ní New Orleans.

-Ohun tó ṣe kókó tí à ń sọ fún ẹnikẹ́ni ni pé, "Ẹjé kí á fọwọ́sowọ́pò láti

yanjú èyí, lẹ́yìn náà a ó yanjú gbogbo èdè-aìỳedè

nígbàtí rúkèrúdò yìí bá dópin."

- Irú ẹgbẹ́ ìrànwọ̀ àwọn òjíṣẹ́ Ọlorun yìí yóò ṣe laalaa laarin ohun ti awọn

ìjọba nílò ní ìdojúkọ pẹ̀lú ohun tí àwọn ará ìlú ń fẹ́.

Fún òjìṣẹ́ Ọlorun, ọ̀kan nínú à̀wọn ohun èlò tí ó tóbijù tí wọn yóò ní láti mú kí

ọkàn àwọn ará ìlú balẹ̀ tàbí bọ̀wọ̀ fún òfin ni Bibeli fúnrarẹ̀, Romu ní pàtó.

-Nítorí Olúwa ni ó gbé ìjọba kalẹ̀. Èyí sì jẹ́ ohun tí a gbàgbọ́

nínú ẹ̀sìn Kristẹni; òun ni a kọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run.

-Ṣùgbọ́n dùró ná fún ìṣẹ́jú kan. Bí ọlọ́pàá bá wà sí ilé mi tí ó sì sọ pé,

"Fọ mótò mi fún mi, ẹrú"? Ǹjẹ́ Bibeli ní kí n gbọ́ràn sí èyí bí?

Ó dára, tí Ọlọpa kan bá sọ fún mi pé kí n ṣe ohun tí kò bá òfin mu? Mo ní tí

ọlọpa bá wá bá mi tí ó sì sọ pé, " Ṣé o mọ ǹkan? Mo fẹ́ kí o gun

fensi sínú ọgbá onílékejì rẹ, mo sì fẹ́ kí o yọjú láti ojú fèrèsé láti

wo ohun tí aladugbo rẹ ń ṣe. Mo fẹ́ kí o sọ́ aladugbo rẹ fún mi"?

Mo ní, ǹjẹ́ ó yẹ kí n gbọ́ràn si èyí ? Ẹ̀yín wí pé, "Mò ń lo àwọn àp̣̣ẹrẹ òmùgọ̀."

bẹ́ẹ̀ni. Nítorí kò sí ìjoba kan níbikíbi tí ó pàṣe pé kí

àwọn ènìyàn màa sọ́ aladugbo wọn tàbí òmíràn. Èyí kò ṣẹlẹ́ rí. àbí?

Kò sí ohun tí ó ń jẹ́ Nazi Germany; kò sí ohun tí ó ń jẹ́ Soviet

Union; sáà pa ẹnu mọ́ kí o sì gbọ́ ohun tí wọ́n bá sọ fún ọ. Romu jẹ́ àyọkà Bibeli tí

sàlàyé fún wa pé èrèdí ìjọba ni láti fìyà jẹ́ àwọn òsìkà, kì í ṣe láti darí

gbogbo ayé wa, láti sọ ohun tí a ó ṣe fún wa àti láti darí wa. Ṣùgbọ́n bákannáà

kókó ohun ti Romu kọ́ ni pé kí á gbọ́ràn sí àwọn alásẹ lẹ́nu.

Báyìí fún àpẹrẹ, ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà a ní ìpele ìjọba ní orísirísi, àbí a kò

ní ? Báyìí kíni òfin tó ga jùlọ ní ilẹ̀ wa? Òfin Ọlọ̀run ni àkọ́kọ́.

Èkínní ni ká gbọ́ràn sí Ọlọ̀run. Lẹ́yìn èyí ni ó kan ìwé òfin ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà

nítorípé òfin ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni èyí tí ó ga jùlọ ní ìlú.

Ẹyin wí pé, " Bibeli sọ pé kí á bọ̀wọ̀ fún ọba, nítorínáà a ní láti gbọ́ràn

sí Obama lẹ́nu." Ṣùgbọ́n dúró ná fún àbọ̀ ìsẹ́jú. Sé Obama ni ọba? Ṣe ìjọba wá wà lábẹ́ ìdarí

ọba? Mo rò pé a ní àwọn adarí tí a di ìbò yàn tí ó ń jábọ̀ fún àwọn

ará ìlú àti pé àwọn pàápàá kò kọjá òfin àti pé òfin tí ó ga jùlọ ní ìlú ni òfin ti

Amẹ́ríkà. Báyìí tí a ó bá gbọ́ràn sí ìjọba tí a

lé wa lórí, bi a ba fẹ́ bọwọ fún òfin ilẹ́ náà, èyí túmọ̀ sí pé a ní láti

gbọ́ràn sí ìwé òfin. Ẹ̀dà ti NIV yọ ẹ̀kọ́ yìí dànù pátápátá

Kò kọ́ wa pé kí a tèlé àṣẹ ibi gíga; ó kàn sọ pé;

dípò kí ó sọ pé, "Jẹ́ kí gbogbo ọkàn tẹríba fún àwọn

alaṣẹ. Nítorí kò sí agbára kan bíkòṣe ti Ọlọ̀run: àwọn agbára tí ó wà jẹ́ èyí tí

Ọlọ̀run dá, èyí ń tọ́kasí pé kò sí ẹnìkan láyé yìí tí ó ní àṣẹ

àfi èyí tó wà láti ọdọ Ọlọ̀run, kíni ìdí tí àwọn ọmọ fi gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹnu?

Nítorí Ọlọ̀run sọ bẹ́ẹ̀. Kí́ni ìdí tí a fi ń gbọ́ràn sí ìjọba ènìyàn? kíni ìdí tí a

fi ń bọ̀wọ́ fún ìjọba ènìyàn rárá? Nítorí Ọlọ̀run sọ fún wa pé ìjọba

ènìyàn jẹ́ ohun tí a nílò làti fiyaje àwọn òsìkà, láti dáábò bo àwọn tí

kò mọwọ́mẹsẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn tó lè ṣe wọ́n níkà. Èyí ni Ẹ̀dà Itumọ Ìgbé Ayé Ọ̀tun NLT

ní Romu :. "Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹríba fún àwọn alaṣẹ. Nítorí gbogbo aṣẹ

wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ̀run," - wo èyí - "àti àwọn tó wà ní ipò àṣẹ ní ó wà

níbẹ̀ nípasẹ̀ Ọlọ̀run." Èyí kì í Ṣé òtítọ́. Ẹ̀dà NLT ni ó

n sọ pé gbogbo ẹni tó wà ní ipò àṣẹ ni a fi síbẹ̀ nípasẹ̀ Ọlọ̀run.

Èyí kì í ṣe òtítọ́, nítorí ọjọ́ kan ńbọ̀ tí asòdì-sí-kristi yóò dé ipò

àṣẹ nípasẹ̀ Sátánì. "Dragoni náà fún ní...àṣẹ rẹ̀", ó sọ nínú

Ìfihàn . Kì í ṣe èyí nìkan, àti ní Hoṣéa [:], o sọ pé, "Wọ́n ti yan

àwọn ọba, Sùgbọ́n kì í ṣe nípasẹ̀ mi". Àwọn ìgbà míràn wà tí àṣẹ ènìyàn tí wà níbẹ̀

nípasẹ̀ ènìyàn lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ̀run. Nítoríbẹ̀ Ìtumọ̀ Ìgbé-Ayé Ọ̀tun

ń sọ ní ẹ̀sẹ̀ kẹfà pé, "San owó-òde rẹ pẹ̀lú, nítorí àwọn ìdí kan náà yìí.

Nítorí wọ́n gbọ́dọ̀ san owó àwọn òsìṣẹ́ ìjọba. Wọ́n ń siṣẹ́ sin Ọlọ̀run nínú ohun tí wọ́n ṣe.

Fún gbogbo ènìyàn ni ohun tí o jẹ́ wọ́n: Ẹ San owó orí yín àti owó ìjọba fún àwọn ti ́ó

ń gbà wọ́n". Ó dàárọ̀! Báỳíi kì í ṣe owó orí nìkan; àti àwọn owó ìlú pẹ̀lú,

àwọn wọ̀nyí ló burú jù. Ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu nśọ pé kí o gbọ́ràn sí ìjọba láàrin

gbèdéke kan, láàrin àwọn òdiwọ̀n ohun tí iṣẹ́ wọn jẹ́, ohun tí

ó yẹ kí wọ́n máa ṣe, àti pẹ̀lú, èrèdí àwọn aláṣẹ ni ó wà

gẹ́gẹ́ bí ìjánu àti òsùwọ̀n.

-Kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu tuntun kò fi ní ìmísí? Nítorípé ó lo àwọn ìwé kannáà.

Kò rí bẹ́ẹ̀. Àti pé ọ̀pọ̀ ibi-kíkà ni ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun tí yàtọ̀

sí Textus Receptus tí ó si tún yàtọ̀ sí ohun tí ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ń sọ.

-Kì í ṣe nínú Májẹ̀mú Tuntun.

ó yàtọ̀ ní tòótọ́

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi-kíkà ni ó wà tí ó ti yàtọ̀ sí TR.

-Ó ṣeéṢé kí ó jẹ́ pé Ẹ̀dá ti Ọba Jakọbu tuntun ni ó léwu jù nínú ̀awọn ìtumọ̀ tí ó wà lóde

nítorípé yóò jẹ́ kí o rò pé, " ohun kannáà ni bíi ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu; ó kàn jẹ́

pé ti òde-òní ni, àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti túnṢé." ti o ba ri bẹ́ẹ̀, Nkò tilẹ̀ ní sọ nípa rẹ̀.

-Nítorí ọpọ ènìyàn tí ó sára fún ẹ̀dà NIV

wọn kò ní fọwọ́kan ẹ̀dà ti ESV tàbí Ìtumọ̀ Ìgbé Ayé Ọ̀tun ,

Sùgbọ́n wọ́n wí pé, ", Olùṣọ-àgùtàn Anderson, ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu tuntun? O fẹ́rè jẹ́ ohun

kannáà pẹ̀lú ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu. Ó kàn yọ àwọn ọ̀rọ̀ àtijọ́ kúrò ni.

Ó dàbí ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu yátọ́ sí pé ó rọrùn díẹ̀ láti ka ní àkàyé."

Ó dára. Jẹ́ kí n fún ọ ní àwọn òtítọ́ kan lórí ẹ̀dà Ọba Jakọbu Tuntun. Ẹdà ti Ọba Jakọbu Tuntun

yọ ọ̀rọ̀ "Olúwa" kúrò ní ìgbà ọgọ́ta-ó-lè-mẹ́fà. Ó yọ "Ọlọ̀run" ní ìgbà ọ̀kànlélààdọ́ta.

Ó yọ ọ̀rọ̀ "ọ̀run" ní ìgbà àádọ́ta. Ó yọ ọ̀rọ̀ "ronúpìwàdà" ní ìgbà mẹ́rìnlélógójì.

Ó yọ ̂ẹj̀ệ̀ ní ìgbá mẹtalelogun. Ọ̀rọ̀ "Ọ̀run-àpáàdì" ní a yọ ní ìgbà méjìlélógún.

Ó yọ ọ̀rọ̀ "Jehofa" kúrò pátápátá, Ó yọ ọ̀rọ̀ "idalebi" kúrò pátápátá,

patapata ló yọ Májẹ̀mú Tuntun", Ó yọ ọ̀rọ̀

"àwọn Èṣù pátápátá". Bibeli kì í ṣe nǹkan àtijọ́; O kàn nílò láti já fáfá síi. O nílò

láti kọ́ ẹ̀kọ́. O nílò láti kọ́ èdè náà. O tilẹ̀ paniléẹr̀iń bí àwọn

ọmọ mi kékeré ṣe mọ̀, tí kò sì yé ìwọ tí o jẹ́ àgbàlagbà?

Àti pé ṣe kò panilẹ́ẹ̀rín bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn kannáà tí ó sọ pé ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ti le

jù láti kà náà ló sọ fún ọ pé o nílò láti kọ́ èdè Girikí tí o bá dìdí fẹ́ mọ

ohun tí Bibeli sọ? Bẹ́ẹ̀ni. èyí yóò tilẹ̀ rọrùn láti ka ní ̀akàyé.

"Ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu le jù fún ọ. Èyí ni Májẹ̀mu Tuntun Girikí."

Àwọn ènìyàn yìí ti n sínwín.

Báyìí ẹjẹ́ ká wo àwọn ẹ̀sẹ̀ kan kí á wo èyí tí o rọrùn láti kà ní àkàyé.

Ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu lo ọ̀rọ̀ kan to le púpọ̀ nípa irú igi kan, "oaku".

Ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun rò pe, Haba, èyí ti le jù. 'oaku' Ṣé ó dá ọ

lójú?" Wọ́n yipadà sí "igi terebinti". Èyí rọrùn díè láti

ní ̀oye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni? Báyìí ìwé Àwọn onidajọ : ní àwọn ẹ̀sẹ̀ tó le nínú

ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu, "òòrùn ti yọ lókè".

Mo sọ pé èyí fẹrẹ dàbí "ewì-fún-àwọn-ọmọdé

"Òòrùn ti yọ lókè". Wọn yí èyí si, "Ìgòkèlọ Heresi."

"Ìgòkèlọ Heresi."

Samueli :. Ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu lo ọ̀rọ̀ líle kan "faili". Nitoribẹ ni Ẹ̀dà ti Ọba

Jakọbu Tuntun yipadà sí "pim". P-I-M."Pim". Mo sọ pé, èyí máa dára láti

mọ̀ fún ayò skrabu, Sùgbọ́n Èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀ yí rí. Bẹ́ẹ̀ni?

Samueli : lo ọ̀rọ̀ tó le púpọ̀ yìí "igi". Nítoríbẹ́ẹ̀ ni ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun

ṣe pinnu láti sàtúnkọ rẹ̀ sí "igi tamariskí" kí ó lè jẹ́ kí ó rọrùn láti

ní ̀oye rẹ̀. Samueli :; ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu sọ pé "Korneti ".

Taló mọ ohun tí korneti ń ṣe?

Ó jẹ́ irú ìwo kan, àbí? O jẹ́ irú fèèrè.

Nítoríbẹ́ẹ̀ wọ́n pinnu láti lo ọ̀rọ̀ tó rọrùn, sistrumu"

"Sistrumu. Nítorí gbogbo ènìyàn mọ ohun tí "sistrumu" jẹ́.

Ta ló mọ ohun tí sistrumu jẹ́?

Ta ló mọ ohun tí "korneti" jẹ́?

Ó dára.

Isaiah lo ọ̀rọ̀ tí ó le kan "ọkùnrin" nínú ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu tiyín.

Mo ní, o dàárò! Fi ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu si ilé ìpamọ́ àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé tó yẹ fún-un. "

Fún mi ni ohun tí ó lè yé mi. lílo "Ẹ̀dá" dára ju èyí lọ, àbí?

Danieli : lo ọ̀rọ̀ líle púpọ̣̀ kan "àwọn ọmọ aládé", Nítoríbẹ́ẹ̀ wọ́n lo ọ̀rọ̀ tó rọrùn nínú

ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun, "satrapu".

"Ẹgbẹ́"?

"Ẹgbẹ́" nínú ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu; èyí ti le jù. Ẹjẹ́ kí à yipadà sí "Ẹgbẹ-Ogun".

O dara, àti pé kòsí ẹni tí o máa ní òye ohun tí "ilẹ-omi" jẹ́. Èyí jẹ́ ti

Àtijọ́. "Ilẹ̀-Omi" ni Iṣe Àwọn Aposteli : "Erùpẹ̀ Syritisi" rọrùn láti

mọ̀. Yóò dára kí o ra èdà Ọba Jakọbu Tuntun. O rọrùn láti ní òye rẹ̀.

Ǹjẹ́ ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun yìí rọrùn púpọ̀ láti kà ní àkàyé ju ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu lọ?

Mo ni ọpọ àpẹrẹ nìyí níbi tí ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ti rọrùn jùlọ. Bẹ́ẹ̀, èyí

kì í ṣe gbogbo rẹ̀. Èyí kàn jẹ́ àwọn àpẹrẹ díẹ̀. Nítoríbẹ́ẹ̀, kò ní

ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú pé a fẹ́ kí ó rọrùn láti yéni; kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú

̀ayípadà rẹ̀, bíbàájẹ́, yíyíi sihin-sọhun, ṣíṢé atúnrọ rẹ̀. Ibi kan tí wọ́n lè

toka si,kì wọn si sọ pé " ibí yìí ni a ti jẹ́ kí́ ó rọrùn púpọ̀", ni

yíyọ àwọn "thees" Àti " thous", Sùgbọ́n o ní láti ní àwọn

"thees" Àti "thous" wọ̀nyi" nítorí àwọn "thees" Àti "thous" ỳíi ńṣe àpẹrẹ ọ̀rọ̀ ẹnìkan tí

"you, yee, your" jẹ́ ti ọ̀pọ̀. Awọn to bẹ̀rẹ́ pẹ̀lú TH jẹ́ ti ọ̀rọ̀ ti n ṣe àpẹrẹ ọ̀kan; àwọn

tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Y jẹ́ tí ọ̀pọ̀. Ó máa ń mú ìyàtọ̀ bá ìtumọ̀ nítorí o kò ní sábà

ní ọ̀nà láti mọ̀ bóyá ó ń bá ẹnìkan sọ̀rọ̀ tàbí gbogbo

ènìyàn àfi tí o bá ní "thees" Àti "thous" níbẹ̀ láti sọ èyí fún o.

Ó ṣe pàtàkí̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Gbogbo rẹ̀ ló ṣe pàtàkì púpọ̀. Sùgbọ́n jẹ́ kí́ n fi àwọn àyípadà ẹ̀kọ́

hàn ọ́ ti èdà Ọba Jakọbu Tuntun ṣe tí ó fi yí èkọ́ padà.

Lọ sí Korinti :.

-"Nítorípé wèr̀e ni ọ̀rọ̀ agbelebu sí àwọn tó ń ṣègbé; Sùgbọ́n sì

àwa tí à ń gbàlà, agbaára Ọlọ̀run ni."

-Bọ̀dá Garretti, ka èyí fún mi dáradára kí o sì kàá sókè pẹ̀lú nínú ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun.

-"Nítorí ọ̀rọ̀ agbelebu jẹ́ wèrè fún àwọn tí ó ń ṣègbé,

Sùgbọ́n fún àwa tí à ń gbàlà ó jẹ́́ agbára Ọlọ̀run."

-Báyìí, sàkíyèsí, nínú ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ó sọ pé a ti ní ìgbàlà. Ní ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun

ó sọ pé à ń gbà wá là. Ìyàtọ̀ ńlá, nítorí ìgbàlà kì í ṣe

à ń ṣe lọ́wọ́. Ìgbàlà máa ń ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan, ní ìṣẹ́jú àáyá kan, a

gbàgbọ́ nínú Kristi, A sì mú wa kọjá láti ikú sí ìyè. Kí í ṣe ohun tí à ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́,

kì í ṣe pé a n gbà mí là lọ́wọ́; Mo ti ní ìgbàlà!

-Àmín!

- Korinti : sọ èyí pé: "Nítorí àwá jẹ́ òórùn dídùn Kristi fún Ọlọ̀run,

nínú àwọn tí a ti gbàlà, àti nínú àwọn tí ń ṣègbé".

Kàá fún mi láti inú ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun.

-"Nítorí òórùn dídùn ti Kristi ni a jẹ́ fún Ọlọ̀run láàrin àwọn ti à ń gbàlà

àti àwọn tí wọ́n ń ṣègbé."

-Leekansii, kì í ṣe àwọn tí a ti gbàlà, Sùgbọ́n àwọn tí a

ń gbàlà, bíi pé ó jẹ́ ohun tí à ń ṣe lọ́wọ́.

Matthew : fún àpẹrẹ, nínú ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun sọ pé, " líle ni ọ̀nà náà

tó lọ sí ìyé, àwọn péréte ni wọ́n ń ríi". ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu sọ pé

"tóóró" èyí tí ́ó ń tọ́ka si iye àwọn ènìyàn tí ó ń lọ, ó tọ́ka si kókó náà pé

àwọn tí ó ti nì ìgbàlà. ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun sọ pé èyí nira.

Báyìí, tí ó ba ṣe pé nípa iṣẹ́ ni yoo nira.

- Ẹ̀dà Itumọ Ìgbé Ayé Ọ̀tun NLT sọ pé, Sùgbọ́n ọ̀nà sí ìyé jẹ́ tóóró àti pè

ọ̀ná náà nira, díẹ̀ ni ó le sàwári rẹ̀". Itumọ ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì

sọ pé "nítorí tóóró ni ẹnu-ọ̀nà naa, àti pé ọ̀nà tí ó lọ sí ìyé nira àwọn tí ó

sàwárí rẹ̀ kéré". Báyìí o sọ pé, " Olùṣọ́-àgùtàn Jimenez, kíni ohun bàbàrà

nínú èyí? Títọ́, tóóró? Tóóró, líle? Sòro, Líle?

Kíni ohun bàbàrà níbẹ̀?" Èyí ni ohun bàbàrà: ṣé ó le láti di ẹni ìgbàlà?

Wò ó, Jesu ti ṣe èyí tí ó le níbẹ̀. Báwo ni ó ṣe le tó láti gba ẹ̀bùn kan? Báwo ni ó ṣe le tó

láti mu omi? Báwo ni ó ṣe le tó láti rìn gba ìlẹ̀kùn? Báwo ni ó ṣe le tó

láti jẹ́ búrẹdì? Àwọn ohun tí Jesu fi ṣe àkàwé ìgbàlà nìwọ̀nyí

nítorí ó rọrùn láti di ẹni ìgbàlà nítorí o kò nílò láti siṣẹ kí o tó lè dé

ọ̀run. ̀Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Bibeli túmọ ìgbàlà sí, nínú ìwé

Heberu? Ìsinmi.

Wò ó, ṣe ìsinmi le?

Màṣe jẹ́ kí àwọn ìtumọ ti ẹ̀dà ayé òde-òni tàn ọ́ jẹ. Ó ṣeéṣe kí á dán ọ wò lọ́jọ́ kan:

Ah!, Ǹjẹ o mọ̀, ìjọ yìí ń lo ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun, àti kí tún ni?

Ó jẹ́ ohun bàbàrà.

Ṣé o rò pé a nílò ọgọ́rùn ún marun orísi Bibeli Gẹ̀ẹ́sì?

-Rárá. kódà, Mo sọ pé wọ́n ti pọ̀jù. A kò nílò òmíràn

mọ́. Nkò rò pé ìdí pàtàkí kán wà fún bí a tí ní wọn ní ọ̀pọ̀ yanturu

káàkiri ní àwọn ọ̀pọ̀ ọdún ṣẹ́yìn. Mo mọ ìdí rẹ̀.

Ó dára.

-Kò tilẹ̀ nira. Ohun náà ni pé bí o bá ní ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé tí o sì fẹ́

ṣe ẹ̀kọ́ Bibeli tàbi nǹkan míran - èmi kì í ṣe ara àwọn tí ń kọ́ èkọ Bibeli -

èmi náà kì í Ṣé ara wọn.

-Ohun tí wọ́n ṣe ni pé tí o bá jẹ́ ilé ìtẹ̀wé ńlá, tí o kò sì fẹ́

san owó fún elòmíràn, nítoríbẹ́ẹ̀ gbogbo wọ́n ṣe ìtumọ̀ tiwọn jáde.

-Bẹ́ẹ̀ni. ìwúrí owò wà láti kọ

gbogbo àwọn orisi ìtumọ̀ yìí síta.

-Ò wà. Kòsí ìbéèrè kankan nípa rẹ̀.

-Ṣé Ọlọ̀run fẹ́ kí Kristẹni tí ó kéré jù kọ́ èdè Girikí bí?

Ọlọ̀run fẹ́ kí Kristẹni tí ó kéré jù lo gbogbo àwọn ìmọ̀ tí a ti fí

fún, a wà ni ìgbà ti a ní ìmọ̀ rẹpẹtẹ ní àrọ́wọ́tó wa

ju àwọn ìran mìran lọ, a sì nílò rẹ̀ ní àkókò yìí nítorí àwọn

àtakò láti ọwọ lúsíférì kò burú bí èyí rí.

Sé o rí ewu, ó dára - nítorí èyí ni ìgbàgbọ́ mi nípa rẹ̀. Mo rò pé bí ẹnìkan

bá kọ́ èdè Girikí Koine tí ó sì mọ̀ ọ́ dáradára tí ó sì le gbe kí ó sì kàá

láìkosẹ̀, èyí yó mà dára o, Sùgbọ́n...

-kíkọ́ èdè Girikí díẹ̀ jẹ́ nǹkan tí ó léwu.

-Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lórí. Sé ẹ̀yin kò rí ewu nínú ẹnìkan tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ sáà méjì péré ní

Ilé ẹ̀kọ́ Bibeli ti Girikí àti nísisìyìí, wọn yóò dide láti sọ pé - bíi, ẹnìkan

tí ó mọ ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu nìkan yóò dìde - ó ti lo sáà ẹkọ méjì ní Ile ẹ̀kọ́ Bibeli

ti Girikí - yoo si dide láti sọ pé "ah!, àwọn onitumọ ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu,

wọn kò túmọ̀ èyí dáradára." Àti pẹ̀lú j́iju ọwọ́ rẹ̀, o mọ̀ pé,

ọdún meje nínú èyí t́i àwọn àadota olọ̀pọ̀lo pipe jáde kúro ni ́ojú fèrèsé fún...

-Steven, ó ṣeéṣe láti tàbùkù ohun rere Àti pé níní ìmọ̀ Girikí díẹ̀ lè jẹ́ ohun tó léwu.

Mo ti gbọ́ àwọn odìdí ìwàásù kan tó dá lórí alayé buburu, bẹ́ẹ̀ ni? Sùgbọ́n jẹ́ kí n

kàn sọ èyí pé ní àwọn ọdún ṣẹ́yìn òjíṣẹ́ Ọlọ̀run kan wá sọ́dọ́ mi ó sì wí pé, "wò ó

Mo rí nǹkan yìí ńinú àlàyé Bibeli. Èyí ń ẁáas̀u, Sùgbọ́n ń kò tíì gbọ́ kí

ẹnikẹ́ni sọ irú rẹ̀ ri. Ìwọ́ ní ìmọ̀ Girikí. Ṣé o le yẹ̀ẹ́wò fún mi?"

Báyìí ni Mo yẹ̀ẹ́wò fún. Kò tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun tí

ó dàbí ẹnipé ẹni tó kọ àlàyé Bibeli ƴìí yà kúrò lo]jú ọ̀nà. Ǹjẹ́ o mọ̀ ohun tí ó ṣe ní gẹ́rẹ́ tí Mo

sọ fún? Ó padà lọ wàásù rẹ̀ láìbìkítà.

-Nítorípé ó dùn láti gbọ́ ó sì fẹ́ràn rẹ̀.

Nítorípe o dùn láti wàásù púpọ̀.

-O jẹ́ kókó tí ó tóbi jọjọ.

-Ah, ó tóbi gan.

-èyí ko yamilẹnu.

-Ó ṣeni láànú pé kò tilẹ̀ jọmílójú

-Kòsí ẹni tí ó takòó pé àwọn ojúlówó ni ìmísí.

[ Peter :] Bibeli sọ pé, "Awọn ènìyàn mímọ́ sọ̀rọ̀

bí a ṣe darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá."

Sùgbọ́n wọn kó gbàgbọ́ pé ohun tí a ní lónìí ní ìmísí nítorí wọn kò

gbàgbọ́ pé a pa Bibeli mọ́ Bibeli, Sùgbọ́n ṣé o mọ èyí, Bibeli sọ nínú

Orin Dafìdí :, " Ọ̀rọ̀ Olùwa, ọ̀rọ̀ funfun ni: bi fàdákà tí a yọ nínú ìléru

erùpẹ̀, tí a dá ní ìgbà méje. Ìwọ ó pa wọ́n mọ́, Olúwa, ìwọ ó

pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìran yìí láíláí." Ẹ sì mọ́ pé, Ọlọ̀run kannáà tí ó

fún wa ní ọ̀rọ̀ imisi náà ni yóò pa ọ̀rọ̀

tí ó ní ìmísí yìí mọ́. Mo sì lérò pé o tàbùkù wa láti rò pé Ọlọ̀run lágbára láti lo àwọn

ẹlẹ́ṣẹ̀ kí ó sì tún ri pé o fún wa ní ojúlówó pípé àti pẹ̀lú Ọlorun yìí kannáà

ko ̀le lo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kí ó sì tún ri dájú pé ó paámọ́ kúrò lọ́wọ́ ìran yìí títíláí?

Mo gbàgbọ́ pé Ọlọ̀run lágbára láti lè fún wa ní ọ̀rọ̀ ìmísí mo sì tún gbàgbọ́ pé Ọlọ̀run

lágbára to láti pá àwọn ọ̀rọ̀ imisi yìí kannáà mọ́.

kúrò lọ́wọ́ ìran yìí títíláí.

Báyìí jẹ́ kí n bèèrè lọ́wọ́ rẹ: Ǹjẹ́ o gbàgbọ́ pe àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ èdè Heberu tàbí

Giriki tàbí Gẹ̀ẹ́sì, tàbí kí wọn, ṣé wọ́n le ní Bibeli ní gbogbo èdè?

-Wọ́n gbọ́dọ̀ ni Bibeli ní gbogbo èdè. Ìdí nìyí tí a fi ń sàtìlẹyìn fún

àwọn iṣẹ ìranṣẹ tí ó se ìtúmọ̀ Bibeli bíi àjọ Bibeli Àgbáyé. Textus Receptus ni a

lò, ó sì hàn gbangba pé a lo Bibeli Heberu, láti ṣe ìtúmọ̀ si àwọn èdè

mìràn, tí yóò jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run.

A gbàgbọ́ pé gbogbo ènìyàn yẹ kó ní Bibeli ní èdè wọn,

ní Gẹ̀ẹ́sì, ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu ni.

-Jẹ́ kí n parí pẹ̀lú sísọ èyí: a ti pa ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run mọ́ fún wa ní

ìran yìí. Gbọ ohun tí Isaiah : sọ. "Ní ti èmi, èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn,

ni Olúwa wí; Ẹ̀mí mi tí ó wà lára rẹ, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí

ẹnu rẹ̀, kí yóò kúrò lẹ́nu rẹ̀, tàbí kúrò lẹ́nu irú-ọmọ rẹ,

tàbí kúrò lẹ́nu irú-ọmọ ọmọ rẹ̀, ni Olúwa wí, láti ìsisìyí lọ àti

láíláí."Ó ní,"Wò ó, Isaiah. ọ̀rọ̀ náà tí ò ń wàásù, àwọn

ọmọlẹ́yìn rẹ yóò wàásù ọ̀rọ̀ yìí. Awọn ọmọ rẹ àti ọmọ ọmọ rẹ àti àwọn

ọmọ tiwọn láti ìsisìyí àti títí lái ni wọn yóò ní àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi" Mo sì gbàgbọ́

pé àwọn ọ̀rọ̀ náà ló wà lọ́wọ́ mi ní ìsisìyí. Sì wò ó, àwọn

ẹ̀dà ayé òde-òni, bóyá NIV, tàbi ESV, ẹ̀dà ti Igbé Ayé Ọ̀tun, tabi

ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu Tuntun, èrò yìí jẹ́ èrò tí ó sọ pé ọ̀rọ̀ a kò pa ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run

mọ́. A ní láti hú òmíràn túntún jáde. A ní láti hú ìwé àkọsílẹ tí

ó ti pẹ́ láti le yanjú àwọn ìsòro tí ó wà nínú rẹ̀. Rárá, mi ò gbàgbọ́ pé a ti

paámọ́ láti igba ayé Kristi títí di ìsisìyí. Ó ti di àtọwọ́dọ́wọ́ ohun tí a sì

ní lónìí ni ẹ̀dà ti ẹ̀dà ti ẹ̀dà èyí tí ó jẹ́ àtọwọ́dọ́wọ́.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló gba ohun tí kì í ṣe òtítọ́ gbọ́ pé a ti yí ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu padà laarin àwọn

ọdún sẹ́yìn, pé àtẹ̀jáde tí à ń lò loni yìí yàtọ̀ pátápátá sí ti

, Sùgbọ́n ní òdodo àwọn ohun tí ó yàtọ̀ ní ní bi a ṣe kọ ọ́

lílo àwọn alifabẹẹti ọlọ́jẹ̀ ńlá, àmì, àwọn èyí tí a ṣìtẹ̀ tí a sì ṣàtúnṣe rẹ̀: àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò

yípadà. àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lonii nínú ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu wa náà ni àwọn ọ̀rọ̀ kannáà

tí àwọn onítumọ̀ fún wa ní ọdún . Awọn ọ̀rọ̀ náà ko tíì

yípadà. A ti pa àwọn ọ̀rọ̀ náà mọ́,

Eyí sì ni ohun tí Ọlọ̀run ṣe ìlérí pé òun yóò paámọ́,

Ó ní, wò ó, "Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, Sùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kí yóò kọjá

loọ." Kò sọ pé àwọn èrò rẹ̀: kò sì sọ pé àwọn èróńgbà: kò sọ pé àwọn

ìlànà; ó sọ pé, àwọn ọ̀rọ̀ mi kí yóò kọjá lọ."Awọn ẹ̀dà túntún yìí wá

láti orísun àìmọ́ wá wọ́n sì nì èso àbàwọ́n. Wo èsó àwọn ẹ̀dà tuntun

wọ̀nyí . Wo bí àwọn ìjọ ti dà: ibi ìgbafẹ́. Wo ohun tí àwọn

ìjọ dà nítorí àwọn ẹ̀dà ayé òde-òni: tó kún fún àwọn

ẹni tí a kò tii gbàlà. Tí ó kún fún àwọn ènìyàn tí kò ní ẹ̀kọ́, tí kò sì bìkítà nípa

ẹ̀kọ̀, nítorí nígbàtí o ba ńka ìwé tí ó kún fún àwọn ìyàtọ,

ó sòro láti bìkítà fún ìkọ́ni. Sùgbọ́n nígbàtí o bá ń ka ìwé tí ó

pé, tí ó mọ́, tí a sì pamọ́, o mọ èyí, o wo gbogbo ọ̀rọ̀ o sì

bìkítà nípa ìkọ́ni, o sì tún bikíta nípa ohun tì ó wí ,o tún bìkítà ohun tí

túmọ̀ sí, kì í ṣe, "bẹ́ẹ̀ ni, ó kàn dàbí ẹnipé ó yé mi. Jesu kú lórí

àgbelèbú. Ó yé mi."Rárá, Mo fẹ́ mọ gbogbo ẹ̀kọ̀ tí Ọlọ̀run ní

fún mi láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run.

-Ṣe o mọ̀ pé, láti fọwọ́kàn ìwé yií àtị láti kẹ̀kọ́ wà lápá kan. Láti mọ rírì rẹ̀

láti ọ̀ọ́kán nípa ohun tí àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé là kọjá

kí ìwọ àti Èmi le kà ìwé kan lónìí tí à ń pè ní Bibeli láìsí ìbẹ̀rù

inúnibíni. Ó rọrùn láti sọ nọ́ḿbà yìí: ẹgbẹ̀rún mẹwa ènìyàn ni ó jóná,

lẹ̀ lòkuta pa, yọ̀fun rẹ̀ síta, fún kí́ka ìwe ỳií.

-Mo kẹ̀kọ́ọ́ púpọ̀ ní àárọ̀ ỳíi, tàbí nígbàmìràn títí di ìrọ̀lé, kí n lè

jí ní aago mẹ́ta pẹ̀lú àbá kan, mo sì máa lọ ka èyí nínú ̀iwé mímọ́

O sì rí ẹwà rẹ̀ àti ohun tí ó ń sọ, ̀eyí sì mú ọ jókòó

síbẹ̀ pẹ̀lú omije tí ó ń sàn ni ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ nítorí o mọ títóbi ohun tí

a ti fi fún ọ. Nítorí èyí nígbàtí mo bá kọ́ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ẹ̀dá Bibeli ti Ọba Jakọbu Mo ní

ìdánilójú pátápátá pé ohun tí ó wà lọ́wọ́ mi ni ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run láti páálí dé

páálí àti pé ọ̀kan náà ni nìsisìyí bí yóò ti rí ní wákàtí kan sí ìsisìyí nítorí

a ti paámọ́ kò sì yípadà. Nítoríbẹ́ẹ̀ mo ní ìgboyà pé tí n bá síi sílẹ̀ tí mo sì wàásù

láti inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ìsinmi tí mo sì tún kọ́ni ní ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi tàbí wàásù fún àwọn ènìyàn

ní òpópónà, Mo mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run ni a sì ń fojúsọ́nà láti pàdé

ọ̀rọ̀ fúnrarẹ̀ nínú ògo láti jẹri sí ohun

tí ati ń kẹ̀kọ́ nípa rẹ̀ ní gbogbo ayé wa.

- Inú Ọlọ̀run kò duń sí àwọn ènìyàn tí ó yọ àwọn ẹ̀sẹ̀ kan kúrò, s̀afikún àwọn ẹ̀sẹ̀, sàfikún

àwọn ohun kan, yíyọ ohun kan. Lọ sí Ìfihàn.

Ìfihàn :; "Èmí ńjẹri fún olúkúlùkú ẹni tí ó gḅó ọ̀rọ̀

ìsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá bá fi kún wọn, Ọlọ̀run yóò fi kún

àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. ìwé yìí". Ṣé o ti ka ìwé

Ìfihàn ri? Awọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún búburú ni ó wà nínú ìwé náà. ó sọ pé Èmi yóò

fún ọ ní àwọn ègún yii tí o bá ṣe àfikún ọ̀rọ̀ mi. Ìfihàn :; " Bí

ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ̀run yóò

mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mimọ, àti kúrò nínú

àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí," Sùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyíí tí ó yí

ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run padá, Bibeli wí pé wọn sọ àǹfànì láti rí ìgbàlà nù.

Ó wí́ pé, "Èmi yòó mú kúrò". O sọ pé, "Bí ẹ ti ṣe yọ kúrò nínú ọ̀rọ̀ mi,

Èmi yòó yọ ipa tirẹ̀ náà kúrò nínú ìwé ìyè," Ó wí pé, "Èmi yóò ríi dájú

pé o kò ní ìgbàlà nítorí o ti sọ Bibel mi dìdàkudà." Èyí sọ fún mi pé

kò fí èyí ṣeré rárá.

Ó dà bíi pé,"Ó dára, Olùṣọ́-àgùtàn Jimenez, Mo gbà. Ó yé mi. Awọn Bibeli yìí kò dára.

Wọ́n ń ba ẹ̀kọ́ jẹ́. Ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu mọ́, ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu

ni ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run. Ó ti yé mi. Kíni kí n ṣe pẹ̀lú rẹ̀?

Bí o bá ri mọ̀ pé o ní ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run ní ọwọ́ rẹ,tí kì í ṣe èrò ọkàn Ọlọ̀run,

tí kì í ṣe ohun ti ó ṣeéṣe kí ó ti sọ, kì í ṣe ohun tí a rò pé ó sọ, Sùgbọ́n ọ̀rọ̀

Ọlọ̀run gan-gan, Kì í sì ṣe èyí nìkan, Sùgbọ́n nígbàtí o bá ni ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run o ní

Ọlọ̀run, kì í ṣe ìwé yìí, Sùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nígbàtí o bá ri mọ̀ pé o ní

ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run, èyí yẹ kí ó máa mú wa ka Bibeli. Èyí yẹ kí ó máa mú wa gbé

ìgbé-ayé wa nípasẹ̀ Bibeli yìí. Ìwé yìí ni ìdáhùn fún gbogbo ìbéèrè láyé.

Ẹ̀yín wí pé, "Olùṣọ́-àgùtàn Jimenez, Mo wá sí Ijọ Baptisti Verity; Nkò tilẹ̀

wá láti kọ́ nípa ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu. Mo wá sí ibi yìí láti kọ́ nípa

ìgbàlà." A kọ́ nípa ìgbàlà nínú ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu.

"Nkò tilẹ̀ wá sí ibí láti kọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Mo wá sí ibí kí n lè

ri ìrànlọ́wọ́ lórí ìgbéyàwó mi." Ìwé yìí á ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìgbéyàwó rẹ.

"Nkò tilẹ̀ wá síbí láti kọ́ nípa ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu. Mo wá síbí

láti kọ́ nípa bí mo ṣelé tọ́ àwọn ọmọ mi. Ìwé yìí á ṣe ìrànlọ́wọ́ láti tọ́ ọmọ rẹ.

Yóò yanjú gbogbo ìṣòró rẹ. Yóò mú ìgbàlà wá fún o. Yóò ṣe

ohun gbogbo tí o bá fẹ́ kó ṣe. Kílode? nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run ni...

láì si àṣìṣe, pípé, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ̀run ti fún ọ.

Ó fún mi nì ìgboyà láti ri mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run jẹ́ pípé. Ǹjẹ́ o mọ ìdí

tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kó ṣe gba Ọlọ̀run gbọ́ lonii, tí wọn kò sì wá sí ìjọ, ìran

àwọn ọ̀dọ́ ń fi ìjọ sílẹ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí wọn kò sì padà

mọ́? Nítorípé àwọn ẹ̀dà Bibeli ode oni ti di ìbàjẹ́, àṣìṣe wà

nínú wọn, èyí sì jẹ́ kí wọn kó siyèméjì nínú ìgbàgbọ́ wọn sí Ọlọ̀run. Sùgbọ́n kì í ṣe

èyí. Elèyí pé. Ẹ̀dà Ọba Jakobu ni ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run.

Máa Kà á.

Kọ́ ọ

Kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.

Kọ́ ọ sórí.

Gbé nípa rẹ.

Wàásù rẹ̀ fún àwọn elòmìràn.

E jẹ́ kí á tẹríba fún àdúrà. Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,

Olúwa, a nifẹ rẹ. E ṣeun fún ọ̀rọ̀ yín. Olúwa, a dúpẹ́ pé o kò fún wa

ní ojúṣe àti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́, Sùgbọ́n èyí jẹ́ ojúṣe ti

O fún ara rẹ̀. O gbìmọ̀ rẹ̀, O paámọ́, O sì ti fún

wa lonii. Baba, a fẹ́ Ọ. Rànwálọ́wọ́ láti má fi ibí yìí sílẹ̀ lonii tí

tí ìwáásù yìí bá gba etí kan wọlé tí ó sì gba èkejì jade. Rànwálọ́wọ́ láti mọ̀ pé, ̂ Mo ni

ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run; bóyá ó yẹ kí n kà a. Bóyá kí n kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. Bóyá kí n

gbé ìgbé-ayé mi. "A nifẹ rẹ Olúwa, Ni orúkọ iyebíye rẹ ni Mo gbàdúrà. Àmín.

Mo fẹ́ béèrè ohun kan.

Ṣé o mọ̀ dájú pé bí o bá kú loniyi, ṣe wà á lọ sí ọ̀run?

O lè sọ pé, "Kò dámilójú bóyá màá lọ sí ọ̀run."

Bóyá o ko tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀ rí.

Sùgbọ́n Bibeli wí pé ó lè dáọlójú pé o wà lọ́na rẹ sí ọ̀run.

Báyìí, gẹ́gẹ́ bii Bibeli ti wí, o nílò láti ní òye àwọn ohun díẹ̀ kan láti lè

gba ìgbàlà. Ohun akọ́kọ́ nì yìí:

Bibeli sọ nínú ìwé Romu :, "Gbogbo ènìyaǹ ni ó sá ti ṣẹ̀ ti wọn s̀i kùnà ògo

Ọlọ̀run. Bibeli sọ fún wa pé "ẹ̀sẹ̀ ni ìtàpá sí òfin." Nígbàtí a bá

rú ̀ofin Ọlọ̀run, a dẹ́ṣẹ̀. Àti gẹ́gẹ́ bi ẹ̀sẹ̀ Bibeli náà ti wí, gbogbo wa ti ṣẹ̀.

Ẹlẹ́sẹ̀ ni mí; ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ́.

Ó sì ṣeni láànú pé èrè wà fún ẹ̀sẹ̀ wa. Romu : sọ pé, "Nítorí

ikú ni èrè ẹ̀sẹ̀". Níbáyìí, ọ̀rọ̀ "èrè" túmọ̀ sí sísanwó. Ohun tí o tọ́ sí ọ

Bí mo bá lọ sí ibi iṣẹ́, wọ́n fún mi ní owó. Èrè mi nì wọ̀nyí. Sùgbọ́n nítorí

ẹ̀sẹ̀ mi,èrè rẹ̀ ni ikú. Ohun tí mo gbà ni ikú. "Nítorí ikú ni èrè

ẹ̀sẹ̀". Báyìí, nígbàtí a bá ronu nípa ikú ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ronú ikú ara,

Sùgbọ́n Ìfihàn :- sọ pé, "Àti ikú àti ipò-òkú ni a sì sọ sínú adágún

iná." (Èyi tó tọka sí ipò-òkú) O wí pé, Èyí ni ikú kejì.

Bí a bá sì rí ẹnikẹ́ni ti ́a kò kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè a sọ ọ sínú adágún

iná."Báyìí, gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti wí, àwọn èrè ẹ̀sẹ̀ wa kì í ṣe

ikú ara nìkan, Sùgbọ́n ikú kejí. O wí pé, "Kí́ni ikú kejì?"

Sísọ sínú adágún iná. "Èyí ni ikú kejì. . "Ohun ti a gba

nítorí ẹ̀sẹ̀ wa ni ikú: ikú ara, ikú kejì, ti o jẹ́ sísọ sínú

adágún iná. Ìfihàn : sọ pé, "Sùgbọ́n àwọn ojo àti àwọn

aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti

osó, Àti abọ̀rìsà..." Báyìí èyí jẹ́ àtòkọ burúkú, àbí?

Àwọn apànìyàn, alágb̀erè, oṣó. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò faramọ́ ọ, apànìyàn

"Ah Bẹ́ẹ̀ni . Wọn á lọ sí àpáàdì. "Sùgbọ́n kí́yèsí pé ó ní, "Sùgbọ́n ojo,

Àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra,àti apànìyàn, àti alágb̀erè, àti

osó àti abọ̀rìsà..." Àti ní ìkẹ̀yín àtòkọ yìí ó sọ

èyí: "Àti gbogbo onírọ́, wọn yóò ní ìpín wọn nínú adágún tí ó n jó pẹ̀lú iná

àti sulfuri: tíí ṣe ikú kejì." Àti ìdí tí Ọlọ̀run fi sàfikún

ẹ̀sẹ̀ irọ́ pípa lẹ̀yín àtòkọ yìí, Ó ń sọ ohun kan fún wa,

nǹkan náà lèyí: gbogbo wa ni ẹlẹ́ṣẹ̀. Gbogbo ènìyàn ló ti parọ́. Tì o

tún n gbìyaǹjú láti sọ ní pé ko sí olòdodo; gbogbo wa la ti ṣẹ̀; ohun tí ó yẹ fún wa ni láti lọ sí

ọ̀run àpáàdì. Báyìí, ̀iròyìn búburú ni èyí. Mo jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀; o jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, gbogbo wa sì

ni a ti dájọ́ ọ̀run àpáàdì fún, Sùgbọ́n ìhìnrere ni ìr̀oyìn ayọ̀ tàbí ìròyìn

rere. Romu : sọ pé, "Nítorí ikú ni èrè ẹ̀sẹ̀". A róye ohun tí èyí

túmọ̀ sí báyìí. Sùgbọ́n apá kejì ẹ̀sẹ̀ yìí sọ pé, "Sùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ̀run ni

ìyè ayérayé nínú Jesu Kristi Olúwa wa." Bibeli sọ pé Ọlọ̀run ní

ẹ̀bùn kan tí ó fẹ́ fún ọ èyí tí í ṣe ìyè àìnípẹ̀kun. Báyìí ní Efesu :-

Bibeli sọ pé, "Nítorí ore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́". Ọ̀rọ̀ náà "ore-ọ̀fẹ́"

túmọ̀ sí láti gba ohun tí kò tọ́ sí ọ. O kò siṣẹ́ rẹ̀; o kò

sanwó fún un. "Ni a fi gbà yín là" ó ń tọ́ka sí gbígbà wá là kúrò ní ọ̀run àpáàdì,

nítorí Mi kò fẹ́ lọ síbẹ̀. Ó dámilójú pé o kò fẹ́ lọ síbẹ̀.

Ọ̀rọ̀ náà "ìgbàgbọ́" túmọ̀ sí láti gbàgbọ́. Ó sọ pé, "Nítorí nípa ore-ọ̀fẹ́ ni a rí ìgbàlà nípa

ìgbàgbọ́; àti pé kì í ṣe tiwa". Kò ní ohun kan láti ṣe pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ìdí:

Ẹ̀bùn Ọlọ̀run ni: Kì í ṣe ti iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má baà ṣògo. "Ẹ̀bùn kì í ṣe

ohun tí o siṣẹ́ fún. Ẹ̀bùn ni ohun tí a fi fún ọ. Elòmìràn

ti sanwó rẹ̀, Sùgbọ́n o kò sanwó fún un. Bí mo bá fún ọ ni ẹ̀bùn kan ti mo sì sọ pé

kí o fún mi ní owó fún un, èyí kì í ṣe ẹ̀bùn. Bi mo bá fún ọ ní ẹ̀bùn, Sùgbọ́n

Mo ńi kí o ṣe nǹkan fún un, èyí kì í ṣe ẹ̀bùn. Báyìí, Ẹ̀bùn kò

ná ọ ní ohun kan, Sùgbọ́n o ná ẹni tí ó ń fún ọ ní ohun kan.

ẹ̀bùn Ọlọ̀run náà kò yàtọ̀ sí èyí. Jesu ti sanwó fún ẹ̀bùn náà,

Romu : sọ pé, "Sùgbọ́n Ọlọ̀run fi ìfẹ́ Òn pàápàá sí wa hàn ní èyí pé, nígbàtí a jẹ́

ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa." Johannu :,ẹsẹ tí ó lókí̀kí ́jùlọ nínú

Bibeli, sọ pé, "Nítorí Ọlọ̀run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi ọmọ bíbí rẹ̀ nìkanṣoṣo fúnni, pé

ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun

Ìhìnrere nìyí: Jesu Kristi ni a bi nípasẹ wúńdíá. Ó gbé ayé aláìléṣè;

kò dẹ̀ṣẹ́ rí, kò ṣe ohun búburú kankan. Ó kú lórí igi agbelebu,

a sì sìnkú rẹ̀. Bibeli sọ fún wa pé ẹ̀mí rẹ̀ lọ sí ọ̀run àpáàdì fún ọ̀san mẹta àti

òru mẹta, Ó jíǹde kúrò ni ibojì, kì í ṣe láti san ẹ̀sẹ̀ tirẹ̀,

nítorí kò dẹ̀ṣẹ́. Ó kú láti san ẹ̀sẹ̀ wa. Wò ó, Ó ti sanwó fún

gbogbo rẹ̀ . Ó ti sanwó fún ẹ̀bún náà . Báyìí èyí ní láti yé ọ

nípa ẹ̀bùn náà: Johannu : sọ pé "ìyè àìnípẹ̀kun". Ẹ̀bùn yìí ni

ìyè àìnípẹ̀kun. Ọ̀rọ̀ náà "àìnípẹ̀kun" túmọ̀ sí pé yóò wà títí láí. Ayé tí kò

ní òpin. Kò le è tán láíláí. Johannu : sọ pé "ìyè àìnípẹ̀kun"

"Ìyè" túmọ̀ sí pé kò níí tán. Johannu : sọ pé "ìyè àìnípẹ̀kun". Romu

: sọ pé "̀iyè àìnípẹ̀kun". Nínú gbogbo Bibeli ni ìwọ yóò ti rí èyí: ìyè àìnípẹ̀kun,

ìỳè àìnípẹ̀kun, ìyè tó máa pé títí láí, ìyè ayérayé, ìyè tí kò ní tán.

Gẹ́gẹ́ bí Johannu :, O máa ríi gbà ní kété tí o bá ti gbàgbọ́. "Ẹni tí ò bá gbàgbọ́

nínú ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun". Báyìí, àwọn kan rò pé, Wòó, Mo le è gbà

ìgbàlà, Sùgbọ́n lọ́gán tí mo bà níi, tí mo bá ṣe ohun tí ó burú, bíi

àgbèrè, bi ìpànìyàn, pìpa ara ẹni, pe Ọlọ̀run yóò gba ìgbàlà mi

kúrò." Sùgbọ́n tí ó ba] gbàá kúrò, kò pé títí láí. Wò ó, a ní láti

ní òye pé ìgbàlà kì í ṣe ohun tí a siṣẹ́ fún, àti pé lọ́gán tí a bá tí

ni, kì í ṣe ohun ti a máa toju. Bibeli wí pé ni Titu :, "Ní ìrètí

̀iyè àìnípẹ̀kun, ti Ọlọ̀run, tí kò le è parọ́, ṣe ̀ilérí kí́ ayé tó bẹ̀rẹ̀".

Wòó, ìrètí wa fún iye ayérayé ni pé: Ọlọ̀run kò lè parọ́. Tí Ọlọ̀run bá ṣe

ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún mi, nígbànáà, dábàá ohun tó lè jẹ́. O jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun. Ó ṣe ìlérí ̀iyè

àìnípẹ̀kun fún mi, yòó pẹ́ títí láí. Ìwọ́ wí pé, bẹ́ẹ̀, bí mo bá ṣe ohun

tí ó burú jáì?" Kì í ṣe ti wa. Kò ni ́ohun kan láti ṣe pẹ̀lú mi. Ó jẹ́

ẹ̀bùn tí o máa wà láíláí. Báyìí ohun kan tí o nílò láti ṣe nìyí:

Gégé bíi ẹ̀bùn míràn, o ní àǹfààní bóyá o fẹ́ gbàá tàbí

tàbí o fẹ́ kọ̀ ọ́. O le béèrè pé, "báwo ni Mo ṣe lè gba ẹ̀bùn Ọlọ̀run?" Romu :

sọ èyí: "Pé bí..." Báyìí, ó sọ pé "bí" nítorí pé o ní

àǹfàní láti yàn. Ó wí pé, "Bi ìwọ ba jẹ́wọ́ Jesu Olúwa pẹ̀lú ẹnu rẹ..."

Ọ̀rọ̀ náà "jẹwọ"túmọ̀ sí pé kí o gbà. Ìwọ́ wí pé, "Kíni mò ń gbà?" ò ń

gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó. Ò ń gbà pé ó yẹ kí ́o lọ sí

ọ̀run-àpáàdì. Sùgbọ́n ò ń béèrè fún ìdáríjì. Ó wí pé, "Bí ìwọ bá jẹ́wọ́ Jesu Olúwa

pẹ̀lú ẹnu rẹ..." Sùgbọ́n o pọ̀ ju sísọ ọ̀rọ̀ lásán lọ.Ó tún sọ pé,

"tí ìwọ si gbàgbọ́ nínú ọkàn rẹ pé Ọlọ̀run ti jí dìde láti inú

òkú..." Ò ń gbàgbọ́ pé Jesu Kristi kú lórí agbelebu, a sín,

Ó sì jíǹde kúrò nínú isà-òkú gẹ́gẹ́ bíi sísanwó fún ẹ̀sẹ̀ rẹ. Ó wí pé "Bí ìwọ bá

jẹ́wọ́ọ Jesu Olúwa pẹ̀lú ẹnu rẹ , tí o sì gbàgbọ́ nínú ọkàn rẹ pé

Ọlọ̀run ti jí dìdé kúrò nínú òkú, "Bibeli sọ pé, "ìwọ yóò ní ìgbàlà."

Kò sọ ṕe bóyá o lè ní ìgbàlà. Kò sọ pé bóyá o nírètí ìgbàlà.

Ọlọ̀run sọ pé, "Èmi yóò gbà ọ bí o bá jẹ́wọ́ pẹ̀lú ẹnu rẹ tí o sì gbàgbọ́ nínú

ọkàn rẹ." Sàkí́yèsí pé o kò nílò láti lọ sí ilé ìjọsìn. Kò sọ pé o ní láti ṣe

ìrìbọmi. Kò sọ pé o ní láti ronúpìwàdà ẹ̀sẹ̀ rẹ.Kò sọ pé o ní

láti ṣe ohun kan; sá gbàgbọ́ kí o sì sọ fún un pé kí o gbà ọ. Bí o bá gba èyí gbọ́

nínú ọkàn rẹ, bí o bá gbàgbọ́ pé Jesu Kristi kú fún ọ lórí agbelebu fún ẹ̀sẹ̀ rẹ,

a sì sin, o jíǹde kúrò nínú ibojì, o fẹ́ fún o ni ẹ̀bùn, ó jẹ́ ìyè

àìnípẹ̀kun, kíni kò ní jẹ́ kí o jẹ́wọ́ pẹ̀lú ẹnu rẹ nisisiyii?

Màá ràn ọ́ lọ́wọ́ gba àdúrà kan. Bi o bá èyí gbọ́, gbàdúrà pẹ̀lú

mi báyìí ni ìsisìyí:

Bí o bá gba àdúrà yìí tí o sì gbàgbọ́ nínú ọkàn rẹ, gẹ́gẹ́ bíi

Bibeli ti wí, o ti ní ìgbàlà. O ti ní ìyè àìnípẹ̀kun. O kú oríiré.

 

 

 







mouseover