Yan Losi Sioni - Majemu lailai ni ede kukuru

Video

March 26, 2015

Leyin egberun odun merin seyin, Olorun fara han Abrahamu ni Mesopotemia, o si wifun pe, "jade kuro ni orilede re, ati kuro ni odo awon eniyan re, ati kuro ni ile baba re, losi ibi ti emi yio fi han o. Emi yio si so di orilede nla. Abrahamu gboran si Oluwa lenu, o si wa si ile ileri ti Kananni nibiti o gbe pelu omo re isaaki, ati omo-omo re Jakobu, eniti a yi oruko re pada si Isreali.

Isreali ati awon omo re mejila losi ile Egipiti ni tori iyan ti o mu ni ile Kananni, nibe ni won it di orilede ti o lagbara. Eru ba awon ara Egipiti nitoripe awon omo Isreali ti o lagbara ngbe laarin won, bayi ni won se so won si igbekun won si fi aye ni won lara gidigan pelu ise ase kara. Leyin ojilenirinwodinigba ni ile Egipiti, atu won sile kuro ninu igbekun won lati owo Mose, won si la okun pupa koja losi ile Arabia, nibiti won ti gba ofin Olorun ni oke Sina.

Iran awon omo Isreali ti o kuro ni Egipiti pelu Mose won ko ni afani lati wo ile ileri nitori won ko ni igbagbo ninu Oluwa. Won fi tipatipa rin kakiri ni aginju fun ogoji odun di igba ti iran miran jade ti won si gbekele Oluwa, awon yi ni won wo ile ileri pelu Josua.

Fun bi irinwo odun, awon onidajo ni won dari awon eya mejila omo Isreali nipase ofin Mose. Nigbati won fe oba gege bi awon orilede yio ku, Olorun yan Saulu gege bi oba, eniti o se akoso lori won fun ogoji odun, Davidi lo tele, ohun naa see akoso fun ogoji odun, ati omo Davidi ti se Solomoni, o se akoso fun ogoji odun. Nigbati Solomoni nse isakoso, ijoba Isreali wani ipo ti ologo julo, won ko tempeli akoko, sugbon nitori okan Solomoni yi pade kuro ninu Oluwa nigba ogbo re, Olorun wi fun pe, omo re ko ni se akoso lori eya mewa.

Leyin iku Solomoni, ijoba Isreali pin, a daari awon eya mewa nipase awon oba buburu ti won ko wa lati iran Davidi ati Solomoni. Ijoba ti ariwa nje oruko Isreali, won si ni Samaria gege bi ilu nla won. Ijoba kereri ti gosu si nje juda, ti Jerusalemu si nje ilu nla won ti awon iran Davidi si nse akoso lori won. Ninu awon Oba Keji ori kerindinlogun, awon eniyan ti ijoba gosu si je awon Ju lati ipase oruko ijoba Juda.

Nitori iwa buburu ti ijoba ariwa ti Isreali, awon ara Assiria si mu won losi igbekun. Awon omo Isreali ti o ku si nse wole wode pelu awon orilede ti ko mo Olorun ti won wa si ile won. Awon eniyan naa won je awon ara samaria, ti eya mewa ti ariwa ko le je orilede mo rara.

Awon Babyloni si mu awon ijoba juda ti gosu losi igbekun nitori ijaya fun si sin Olorun miran, tempeli si baje, sugbon leyin adorin odun, awon Ju pada si juda, won si ko tempeli ni Jerusalemu, awon iran Davidi si se akoso lori won.

Ni akoko Kristi, orilede ti a npe ni Judea wa ni isakoso Romu. Jesu ati awon eyin re nwasu iyinrere kakiri Judea, won si wa agutan ti o nu ti ile Isreali. Leyin odun meta ati abo ise iranse re, awon Ju ko Jesu gege bi messia, won yi gomina Romu lokan pada lati kan mon aigbelebu. Ni ojo keta, oji dede kuro ninu ipo oku, o si fara han awon omo eyin re ni aaye ki o to losi apa otun Baba lorun.

Nigba die ki won to kan mon aigbelebu, o so asotele pe, Jerusalemu yio jona, tempeli yio parun, ati awon Ju won yio wani igbekun ni orilede gbogbo gege bi ijaya nitori won ko gba gbo. Asotele yi wa si imuse ni adorin leyin iku Kristi, Nigbati ti ologun Tito segun Jerusalemu. Fun bi egbewadinigba ati die, awon Ju si wa kakiri ni orilede gbogbo.

Ni odun 1948, Oun ti kose le ri sele, won gbe ilu Isreali kale, awon Ju si jogun ile ileri lekan si. Opolopo awon Kristiani ti kede pe, eyi je ise iyanu ati Ibukun lati odo Olorun, sugbon nje eyi je ibukun lati odo Olorun, tabi awon alagbara okunkun lo wa nbe?

Ere yi ni idahun.

 

 

 

mouseover